Ìgboyà: Àgbéyẹ̀wò Ìgboyà Ìgbàgbọ́ Àwọn Ènìyàn AláìpéÀpẹrẹ
Ọjọ́ Kẹrin: Jónátánì
Jónátánì ni àkọ́bí Sọ́ọ̀lù, ọba àkọ́kọ́ ní Ísírẹ́lì. Nígbà tí ọba kan bá kú, ọmọkùnrin rẹ̀ àkọ́bí ló sáábà máa ń di ọba. Ó bani nínú jẹ́ pé Ọlọ́run kọ Sọ́ọ̀lù sílẹ̀ nítorí àìgbọràn rẹ̀ (wo 1 Sámúẹ́lì 15), nítorí náà Ọlọ́run yan Dáfídì láti rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba. Dáfídì ní sùúrù, ó sì dúró de àkókò tí Ọlọ́run fẹ́ kí ó jọba dípò tí ì bá fi fi ipá mú ara rẹ̀ láti di ọba kí Sọ́ọ̀lù tó parí ìṣàkóso rẹ̀.
Fojú inú wò ó pé ìwọ ni Jónátánì nínú ipò yìí. Ọmọ-ọba ni ọ́. Ọba ni bàbá rẹ. Inú ààfin ni ò ń gbé, ìgbésí ayé rẹ dára. Lẹ́yìn náà ni bàbá rẹ ṣe àwọn ìpinnu tí kò dára, tí ó sì ba ọjọ́ ọ̀la rẹ jẹ́. Báwo ni ó ṣe máa rí l'ára rẹ sí ẹni náà tí wọ́n yàn láti j'ọba lẹ́yìn bàbá rẹ dípò ìwọ?
Ohun yòówù kí Jónátánì kọ́kọ́ rò nípa Dáfídì, a rí i pé òun àti Dáfídì di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́. Sọ́ọ̀lù, tí ó wá di àna Dáfídì, ní àjọṣe tí ó díjú gan-an tí ó sì kún fún pákáleke pẹ̀lú Dáfídì. Nígbà míì, lràn, yíó jọ bíi ẹni pé ó nífẹ̀ẹ́ Dáfídì, àmọ́ ó gbìyànjú láti pa á lọ́pọ̀ ìgbà.
Àmọ́ Jónátánì kò f'ìgbà kan ṣ'iyèméjì. Ó dúró ṣinṣin gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́ àti alátìlẹyìn. Nínú ìwé 1 Sámúẹ́lì orí 20, a kà nípa bí ó ṣe kìlọ̀ fún Dáfídì pé kí ó sá kúrò lọ́dọ̀ Sọ́ọ̀lù, bàbá rẹ̀, nígbà tí ó ń wá bí òun yìó ṣe pa Dáfídì (bí í t'àtẹ̀tìnwá). F'ojú inú wo bí yíó ṣe ṣòro tó fún Jónátánì láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ó mọ̀ pé Ọlọ́run ni ó fún Dáfídì ní ẹ̀tọ́ láti jọba. Ó ní láti ṣe alárinà láàárín bàbá rẹ̀, tí ó jẹ́ ọba lọ́wọ́lọ́wọ́, àti ọ̀rẹ́ rẹ̀, tí yíó jẹ́ ọba lọ́la. Ó ní láti f: ara mọ́ ọ̀kan l'ára wọn, kí ó sì máa bọ̀wọ̀ fún ẹnì kejì. Jónátánì sì yàn láti wà ní ìhà kan; ó dúró ti ẹni tí Ọlọrun yàn. Ó pinnu láti ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́. Èyí kò mú ìgbésí ayé rẹ̀ rọrùn, àmọ́ ìwà rẹ̀ kò bàjẹ́ nígbà tí ó kú.
Ìgboyà tí Jónátánì ní jẹ́ kí ó mọ ohun tí yíó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Ó mọ̀ pé òun kò níí di ọba àti pé òpin ti dé bá ìdílé ọba tí Sọ́ọ̀lù bàbá òun ti wá. Bàbá rẹ̀ kò fún un ní ìpín rere, ṣùgbọ́n Jónátánì wo ọjọ́ iwájú ó sì dá ọmọ tirẹ̀ sílẹ̀. Ó yàn láti ṣe ohun tí kò tó nǹkan nínú iṣẹ́ ńlá tí Ọlọ́run gbé lé e lọ́wọ́, ó kọ̀ láti ṣe ìlara bí i ti bàbá rẹ̀, èyí sì mú kí ọmọ rẹ̀ náà jẹ àǹfààní rẹ̀.
Àṣàrò/Ìbéèrè Ìjíròrò:
1. Ǹjẹ́ o mọ ẹnìkan tí ìgboyà rẹ̀ ṣe é ní àǹfààní ju tí àwọn ẹlòmíràn lọ? Kíni èrò rẹ nípa irú ẹni tí ẹni náà jẹ́?
2. Kíni ọ̀nà kan tí o lè gbà fi ìgboyà gbèjà ẹlòmíràn?
Nípa Ìpèsè yìí
Ìgboyà kò nílò láti jẹ́ ohun tí ó bùyààrì tí a sì ní láti pariwo rẹ̀ fún ayé rí; ó kàn jẹ́ ìgbésẹ̀ láti mú ohunkóhun tí o ní wá fún Jésù àti níní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Rẹ̀ lórí àbájáde wọn. Wá jẹ́ ká jọ rìn ìrìn-àjò ọlọ́jọ́ méje láti wo bí àwọn ènìyàn aláìpé ṣe ní ìgbàgbọ́ tí ó lágbára.
More