Nigbati Jesu si woye pe, nwọn nfẹ wá ifi agbara mu on lọ ifi jọba, o tún pada lọ sori òke on nikan. Nigbati alẹ si lẹ, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lọ sinu okun. Nwọn si bọ sinu ọkọ̀, nwọn si rekọja okun lọ si Kapernaumu. Okunkun si ti kùn, Jesu kò si ti ide ọdọ wọn. Okun si nru nitori ẹfufu lile ti nfẹ. Nigbati nwọn wà ọkọ̀ to bi ìwọn furlongi mẹdọgbọn tabi ọgbọ̀n, nwọn ri Jesu nrìn lori okun, o si sunmọ ọkọ̀; ẹ̀ru si bà wọn. Ṣugbọn o wi fun wọn pe, Emi ni; ẹ má bẹ̀ru. Nitorina nwọn fi ayọ̀ gbà a sinu ọkọ̀: lojukanna ọkọ̀ na si de ilẹ ibiti nwọn gbé nlọ.
Kà Joh 6
Feti si Joh 6
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Joh 6:15-21
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò