Joh 6:15-21
Joh 6:15-21 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí Jesu mọ̀ pé wọn ń fẹ́ wá fi ipá mú òun kí wọ́n sì fi òun jọba, ó yẹra kúrò níbẹ̀, òun nìkan tún pada lọ sórí òkè. Nígbà tí ilẹ̀ ṣú, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí èbúté, wọ́n wọ ọkọ̀, wọ́n ń lọ sí Kapanaumu ní òdìkejì òkun. Òkùnkùn ti ṣú ṣugbọn Jesu kò ì tíì dé ọ̀dọ̀ wọn. Ni omi òkun bá bẹ̀rẹ̀ sí ru sókè nítorí afẹ́fẹ́ líle ń fẹ́. Lẹ́yìn tí wọ́n ti wa ọkọ̀ bí ibùsọ̀ mẹta tabi mẹrin wọ́n rí Jesu, ó ń rìn lórí òkun, ó ti súnmọ́ etí ọkọ̀ wọn. Ẹ̀rù bà wọ́n. Ṣugbọn ó wí fún wọn pé, “Èmi ni. Ẹ má bẹ̀rù.” Wọ́n bá fi tayọ̀tayọ̀ gbà á sinu ọkọ̀. Lẹsẹkẹsẹ ọkọ̀ sì gúnlẹ̀ sí ibi tí wọn ń lọ.
Joh 6:15-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí Jesu sì wòye pé wọ́n ń fẹ́ wá fi agbára mú òun láti lọ fi jẹ ọba, ó tún padà lọ sórí òkè, òun nìkan. Nígbà tí alẹ́ sì lẹ́, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí Òkun. Wọ́n sì bọ́ sínú ọkọ̀ ojú omi, wọ́n sì rékọjá Òkun lọ sí Kapernaumu. Ilẹ̀ sì ti ṣú, Jesu kò sì tí ì dé ọ̀dọ̀ wọn. Òkun sì ń ru nítorí ẹ̀fúùfù líle tí ń fẹ́. Nígbà tí wọ́n wa ọkọ̀ ojú omi tó bí ìwọ̀n ibùsọ̀ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n tàbí ọgbọ̀n, wọ́n rí Jesu ń rìn lórí Òkun, ó sì súnmọ́ ọkọ̀ ojú omi náà; ẹ̀rù sì bà wọ́n. Ṣùgbọ́n ó wí fún wọn pé, “Èmi ni; ẹ má bẹ̀rù.” Nítorí náà wọ́n fi ayọ̀ gbà á sínú ọkọ̀; lójúkan náà ọkọ̀ náà sì dé ilẹ̀ ibi tí wọ́n ń lọ.
Joh 6:15-21 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati Jesu si woye pe, nwọn nfẹ wá ifi agbara mu on lọ ifi jọba, o tún pada lọ sori òke on nikan. Nigbati alẹ si lẹ, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lọ sinu okun. Nwọn si bọ sinu ọkọ̀, nwọn si rekọja okun lọ si Kapernaumu. Okunkun si ti kùn, Jesu kò si ti ide ọdọ wọn. Okun si nru nitori ẹfufu lile ti nfẹ. Nigbati nwọn wà ọkọ̀ to bi ìwọn furlongi mẹdọgbọn tabi ọgbọ̀n, nwọn ri Jesu nrìn lori okun, o si sunmọ ọkọ̀; ẹ̀ru si bà wọn. Ṣugbọn o wi fun wọn pe, Emi ni; ẹ má bẹ̀ru. Nitorina nwọn fi ayọ̀ gbà a sinu ọkọ̀: lojukanna ọkọ̀ na si de ilẹ ibiti nwọn gbé nlọ.