Ọjọ́-Ìsinmi - Gbígbé Ìgbé-ayé ní Ìlànà Ọlọ́runÀpẹrẹ

Sabbath - Living According to God's Rhythm

Ọjọ́ 8 nínú 8

ỌJỌ́ ÌSINMI ÀTI ÌRÈTÍ

ÀṢÀRÒ

"Ojú ń kàn mi láti f'ẹ̀yìntì," alábàgbé mi màá ń se awẹ́wa yìí ní gbogbo ìgbà, bíótilẹ̀jẹ́pé ó ṣì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún láti ṣiṣẹ́ síi kí ìfẹ́ rẹ̀ yìí tó wá sí ìmúṣẹ. "Kí ẹ̀mí ọlá ìṣiṣẹ́fẹ̀yìntì ó pẹ́ o!" lè ṣe atọ́nà bí a ṣe ńṣe sí nígbàtí a bá ronû nípa ìsinmi tí a ti pinnu fún wa nígbátí a fi ayé wa fún Ọlọ́run, Ilẹ̀ Ìlérí tí ńdúró dè wá lẹyìn ikú. Èyí lè rí bí ohun tí ó jìnnà tèfè bí a bá wo ayé bíi ìrìn-àjò adánilágara inú aginjù.

Àmọ́ṣá, òǹkọ ìwé Hébérù ń tì wá láti wọ inú ìsinmi Rẹ̀ lójúẹsẹ̀. (Hébérù 4:11). Nítorí náà, ìsinmi kan kù fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run (Hébérù 4:9), "èyí túmọ̀ sí pé ìsinmi ti ẹ̀mí kan wà tí Ọlọ́run pè wá sí" (Johannes Calvin). Nítorí náà, ohun kan wà nípa ìsinmi Ọjọ́-ìsinmi tí ó ti wà fún wa bíi atọ́ka ohun tí yíó jẹ jáde tí yíó sì máa gbèrú síi ní ìlọ́po mẹ́wàá ní ayérayé tí a ṣ'èlérí.

Ní Hébérù 4 "ìsinmi" tọ́ka sí ibi tí a ṣe ìlérí rẹ̀ ní ọjọ́ iwájú, ibi ààbò àti ilẹ̀ ológo fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run, àti pẹ̀lú, ibi tí a wà lọ́wọ́lọ́wọ́ tí ó sopọ̀ mọ́ ìsinmi tí Ọlọ́run ṣ'ẹ̀dáa rẹ̀ nígbàtí Ó parí iṣẹ́ ìṣẹ̀dá tí Ó sì ṣe àjọyọ̀ iṣẹ́ ara Rẹ̀. Ó jẹ́ Ilẹ̀ Ìlérí wàrà àti oyin àti àkókò ayọ̀ ńláńlá níwájú Ọlọ́run. L'ọ́jọ́ kan, a ó dé òpin ìrìn-àjò wa, gẹ́gẹ́bí àwọn ènìyàn Ọlọ́run ṣe dé Ilẹ̀ Kénááànì. Síbẹ̀, làti òní lọ pàápàá jùlọ l'ónìí, a pè wá láti ní ìtọ́wò ìsinmi yìí, kí a sì yípadà sí Ọlọ́run láti k'ókòkí ògo Rẹ̀, kí a sì rán wa létí iṣẹ́ Rẹ̀ àti kí a fi ìgbẹ́kẹ̀lé wa sínú Rẹ̀. Èyí tí ó kẹyìn yìí ṣe pàtàkì nítorípé òǹkọ ìwé Hébérù kìlọ̀ fún òǹkàwé pé gẹ́gẹ́bí àwọn ọmọ Isrẹ́lì ṣe sọ àǹfààní áti wọ Ilẹ̀ Ìlérí nù ní Kadeṣi Báníà, àwa náà lè sọ àǹfààní wa nù nígbàtí a bá sé ọkàn wa le. Nípa gbígbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run àti yíyàn láti ṣe bẹ́ẹ̀ lójoojúmọ́, ìsinmi Ọjọ́-ìsinmi yíó wà pẹ̀lú wa láti òní lọ títí a ó fi wọnú rẹ̀ ní tòótọ́ ní iwájú Rẹ̀ l'áyérayé.

Ẹ má jẹ́ kí á jẹ́ aláìmọ̀kan nínú ìjọsìn wa, ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí á sin Ọlọ́run ní Ẹ̀mí àti ní òtítọ́. Ka Bíbélì kí o sì gbọ́ ohùn Ọ̀lọ́run. Ka Bíbélì kí o sì rí Jésù. Ka Bíbélì kí o sì gba agbára Ẹ̀mí-mímọ́.

ÌBÉÈRÈ FÚN ÀṢÀRÒ

  • Kíni ìsinmi tí ẹ̀mí túmọ̀ sí fún mi?
  • Báwo ni àwọn àkókò Ọjọ́-ìsinmi mi ṣe ń ru ìrètí mi s'ókè?
  • Ǹjẹ́ àwọn agbọn ayé mi kan wá tí wọ́n ti mú mi sé ọkàn mi le?

KÓKÓ ÀDÚRÀ

  • A gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún wa ní ìsinmi lónìí.
  • A gbàdúrà fún ìdáríjì fún gbogbo ìgbà tí a ti sé ọkàn wa le tí a ti yípadà kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run.
  • A gbàdúrà fún ìdáríjì àti pé kí ìlérí Rẹ̀ fún wa ní ọ̀nà tààrà sí Ilẹ̀ Ìlérí, ibi ìsinmi àti ibi tí Yíó ti lo ayérayé pẹ̀lú wa.
  • A gbàdúrà fún ìrànlọ́wọ́ Rẹ láti gba ara wa ní ìyànjú láti jẹ́ àpẹẹrẹ rere tí ìdúróṣinṣin fún àwọn ìran tí ń bọ̀.

ÀBÁ ÀDÚRÀ

Baba, mo gbẹ́kẹ̀lé Ọ, bí mo tilẹ̀ wà ní aginjù, nítorípé mo mọ̀ pé Ìwọ yíó mú mi wọ inú ìsinmi Rẹ, àti iwájú ààbò àti ògo Rẹ. Mo fẹ́ gbé ní iwájú Rẹ láti gba ìrètí yìí àti ìsinmi Ọjọ́-ìsinmi lójoojúmọ́. Àmín.


Michael Mutzner, Permanent Representative at the UN in Geneva, World Evangelical Alliance, Switzerland.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 7

Nípa Ìpèsè yìí

Sabbath - Living According to God's Rhythm

Àjọ Evangelical Alliance Week of Prayer (WOP) jẹ́ tí gbogbo àgbáyé ṣùgbọ́n ó fì sí ilẹ̀ Yúróòpù tí a sì ṣe àgbékalẹ̀ àwọn ohun-èlò rẹ̀ láti ọwọ́ European Evangelical Alliance. WOP 2022 wáyé lábẹ́ àkòrí "Ọjọ́-ìsinmi." Láàrin ọjọ́ mẹ́jọ a pé àwọn òǹkàwé láti fojúsí ohun kan nípa Ọjọ́- ìsinmi: ìdánimọ̀, ìpèsè, ìsinmi, ìyọ́nú, ìrántí, ayọ́, ìlawọ̀ àti ìrètí. A gbàdúrà pé ohun-èlò yìí yíó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣàwárí lọ́tun ìgbé-ayé tí ó bá ìlànà Ọlọ́run mú!

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ European Evangelical Alliance fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, Jọ̀wọ́ lọsí: http://www.europeanea.org