Ọjọ́-Ìsinmi - Gbígbé Ìgbé-ayé ní Ìlànà Ọlọ́runÀpẹrẹ

Sabbath - Living According to God's Rhythm

Ọjọ́ 7 nínú 8

ỌJỌ́-OLÚWA ÀTI ÌFIFÚNNI  

ÀṢÀRÒ

Gbogbo wa la ní ìpòngbẹ fún ìsọdimímọ́ àti ìsọdipípé. A nífẹ̀ẹ́ sí ìgbésí ayé tó kún fún ìṣerere bẹ́ẹ̀ là ń retí àwùjọ tó "ṣe dédé," àti àgbáyé tí kò ní àbùkùn. Kìíṣe yíya ọjọ́ kan sọ́tọ̀ níkàn ni àwọn òfin Ọjọ́-Olúwa dá lórí. Pẹ̀lú ìpè láti ṣe àjọyọ̀ ọdún Ìtúsílẹ̀, Ọlọ́run fún àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní ìtọ́wò bí ìsọdimímọ́ ayérayé máa ti rí – ìyẹn ìtọ́wò Ọjọ́-Olúwa ayérayé. 

Ìwé Mósè àti Májẹ̀mú titun sọ̀rọ̀ nípa Ọjọ́-Olúwa àti ọdún Ìtúsílẹ̀ gẹ́gẹ́bí ọ̀nà láti fi ẹsẹ̀ inúrere, ìdájọ́ òdodo, àti ìsọdọ̀tun múlẹ̀ láàárín àwọn ènìyàn Ọlọ́run. Gbogbo ẹbí nínú ẹ̀yà kàànkan ló gbẹ́kẹ̀lé ilẹ̀ tí a fífún wọn láti lè pèsè fún gbogbo ènìyàn tó wà ní àwùjọ wọn. 

Ní apá kejì, àwọn òfin Ọjọ́-Olúwa ń ṣe ìrànwọ́ fún oníkálukú wa. Wọ́n ń ràn wá lọ́wọ́ láti rí ìsinmi lójú iṣẹ́ àti láti ráyè fún ìjọsìn sí Ọlọ́run, láì gbàgbé wípé iṣẹ́ yí ló ń pèsè fún oúnjẹ òjọ́ wa. Àmọ́ yàtọ̀ sí ìrànwọ́ tí ó ńṣe fún oníkálukú, àwọn òfin Ọjọ́-Olúwa fi ìbáraẹnigbépọ̀ ṣe àfojúsùn. Àwọn òfin yìí ṣe àfihàn irúfẹ́ ẹ̀dá tí Ọlọ́run jẹ́ àti bí àwa ènìyàn – pàápàá àwa onígbàgbọ́ – ṣe nílò láti wà ní àwùjọ. Àwọn ọ̀nà tí à ń gbà bá ara wa lò ní láti mú inúrere dání gẹ́gẹ́bí àmì ore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, èyí tí àwa fúnra wa ti jẹ ìgbádùn rẹ̀. Ìgbésí ayé wa gbọ́dọ̀ ní àmúyẹ ìdájọ́ òtítọ́, èyí tí a ní láti pèsè fún àwọn mìíràn nítorí Ọlọ́run onídàájọ́ ni Ọlọ́run wa. Bákan náà, ìgbésí ayé wa gbọ́dọ̀ fi ìsọdọ̀tun ṣe ọ̀ṣọ́, nípasẹ̀ ṣíṣe ìrànwọ́ fún àwọn tó yí wa ká láti wà níbi tó níyì láwùjọ. Lóde òní, kò fi gbogbo ara túmọ̀ sí wípé a gbọ́dọ̀ ní ilẹ̀ tí a lè kólé sí. Dípò èyí, a lè fi ara wa jìn sí ṣíṣe ìrànwọ́ fún àwọn mìíràn láti rí iṣẹ́, láti rí ilé gbé àti láti gbé ìgbé ayé ìrọ̀rùn. 

Nísinsìnyí tí ayé-ti-lu-jára, àwọn ènìyàn káàkiri àgbáyé ti di alábàágbé wa. A ní láti ro ọ̀nà tí ìgbáyé-gbádùn wa ń gbà pa àyíká wa lára. Nígbàtí a bá ṣe àwọn ǹkan àdayébá àti èyí tí o lalẹ̀ hù ní ọ̀ṣọ́, a máa mú Ọjọ́-Olúwa ni Afrika, Asia, àti gbogbo àgbáyé rọrùn. Inúrere kò nííṣe pẹ̀lú ààlà tó pín àwọn ìlú níyà.

ÀWỌN ÌBÉÈRÈ LÁTI GBÀ'RÒ  

  • Ǹjẹ́ mo ti jẹ àǹfààní inúrere, ìdájọ́ òtítọ́, tàbí ìsọdọ̀tun nípasẹ̀ ẹlòmíràn?  
  • Kíni a lè kọ́ nípa Ọlọ́run nígbàtí àwọn ènìyàn bá fi inúrere hàn síwa, tí wọ́n bá dìde fún ìdájọ́, tàbí ran ìsọdọ̀tun iyì àwọn ènìyàn lọ́wọ́? 
  • Báwo ni mo ṣe lè ní ìrírí àwọn òfin Ọjọ́-Olúwa – yàtọ̀ sí ìsinmi – gẹ́gẹ́bí àǹfààní fún ìdájọ́ láwùjọ?   
  • Ìsọ̀rí ìgbésí ayé mi wò ni mo ti lè fi inúrere hàn? 

KÓKÓ ÀDÚRÀ  

  • À ń gbàdúrà fún àwọn ènìyàn tí a fi ìdájọ́ òtítọ́ dùn.  
  • À ń gbàdúrà fún àwọn tó ńṣe àìní ní àwùjọ tí wọn sì ń w'ojú Ọlọ́run fún ìgbésí ayé tó buyì fún ni.  
  • À ń gbàdúrà fún ìjọ láti tan ìmọ́lẹ̀ inúrere àti ìdájọ́ òdodo ti Ọlọ́run.  
  • Olúwa, fi ọ̀nà tí mo lè gbà ṣe àfihàn ìdájọ́ òtítọ́ àti inúrere Rẹ lójojúmọ́ hàn mí.

ÀBÁ ÀDÚRÀ 

O ṣeun, Baba mi Lọ́run, fún inúrere Rẹ tí kò l'ákàwé síwa. Èyí tó pọ̀ débi jíjọ̀wọ́ Ọmọ Rẹ láti kú fún wa. Kìíṣe Ore-ọ̀fẹ́ àti ìdájọ́ òtítọ́ rẹ nìkan ló fi hàn sí wa lákòókò Rẹ̀ ní ayé, àmọ́ Ó ti mú kó ṣeé ṣe fún wa láti jẹ àǹfààní àwọn ǹkan wọ̀nyí nípasẹ̀ ikú Rẹ̀ lórí àgbélébùú àti nípa Àjíǹde. 

Fún wa ní ọgbọ́n àti agbára nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ láti gbé ìgbé ayé inúrere àti ti ìdájọ́ òtítọ́. Kí O sì ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe ìtọ́jú àwọn ìṣẹ̀dá Rẹ nítorí ní àwòrán Rẹ ni a dá wa. Fún wa lójú láti rí àwọn tó nílò ìsọdọ̀tun kí a ba lè di ohun-èlò ìfẹ́ Rẹ sí wọn lónìí. Àmín.


Marc Jost, General Secretary of the Swiss Evangelical Alliance (German-speaking part), Switzerland.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 6Ọjọ́ 8

Nípa Ìpèsè yìí

Sabbath - Living According to God's Rhythm

Àjọ Evangelical Alliance Week of Prayer (WOP) jẹ́ tí gbogbo àgbáyé ṣùgbọ́n ó fì sí ilẹ̀ Yúróòpù tí a sì ṣe àgbékalẹ̀ àwọn ohun-èlò rẹ̀ láti ọwọ́ European Evangelical Alliance. WOP 2022 wáyé lábẹ́ àkòrí "Ọjọ́-ìsinmi." Láàrin ọjọ́ mẹ́jọ a pé àwọn òǹkàwé láti fojúsí ohun kan nípa Ọjọ́- ìsinmi: ìdánimọ̀, ìpèsè, ìsinmi, ìyọ́nú, ìrántí, ayọ́, ìlawọ̀ àti ìrètí. A gbàdúrà pé ohun-èlò yìí yíó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣàwárí lọ́tun ìgbé-ayé tí ó bá ìlànà Ọlọ́run mú!

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ European Evangelical Alliance fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, Jọ̀wọ́ lọsí: http://www.europeanea.org