Ọjọ́-Ìsinmi - Gbígbé Ìgbé-ayé ní Ìlànà Ọlọ́runÀpẹrẹ
ỌJỌ́ ÌSINMI ÀTI AYỌ̀
ÀṢÀRÒ
"Kíni ká ṣe ní ọjọ́ ìsinmi? 50 ọ̀nà tí o lè gbà d'ojúkọ ìkáàárẹ̀!"
Ìwé ìròyìn kan ńgbìyànjú láti pe àkíyèsí rẹ pẹ̀lú àkọlé yìí. Ọjọ́ ìsinmi wá kún fún oríṣiríṣi ohun-afẹ́ tàbí ìrìn-àjò pákáleke. Àfojúsùn ibẹ̀ ni kí á ní ìrírí tí ó mú ìgbádùn wá. Ẹ̀wẹ̀, ayọ̀ kò ṣéé gbámú. A lè ní àwọn ìrírí tó dùn tó sì mú ayọ̀ wá léraléra, síbẹ̀, lọ́gán tí wọ́n bá tí k'ásẹ̀, gbogbo ìmọ̀lára tó rọ̀ mọ wọn á parẹ́ pẹ̀lú. Ohun tó kù ni ìpòǹgbẹ fún irú àwọn ìrírí aládùn yìí síi. Ayé wa yìí ń làkàkà fún ìdùnnú tí ó wà nínú àwọn ìrírí wọ̀nyí. Síbẹ̀, báwo ni a ṣe lè mú ìpòǹgbẹ fún ìdùnnú àti ayọ̀ yìí ṣẹ tí kò fi níí já sí aré asán? Àtipé kíni yíó ṣẹlẹ̀ bí ìkúukùu ẹ̀dùn àti arò bá bo àwọn ìrírí yìí mọ̀'lẹ̀? Ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí rọrùn bákan náà sì ni wọ́n pe 'ni níjà.
Bí ó bá jẹ́ pé ìrírí àt'ọ̀dọ̀ Ọlọ́run tó dára tó sì dùn nìkan ni ayọ̀ sopọ̀ mọ́, kò níí jẹ́ ayọ̀ tòótọ́. Ayọ̀ tí Ọlọ́run fún wa nípa ọjọ-ìsinmi jinnú, a kò sì lè múu kúrò. Ó fún wa ní ààyè àti àkókò fún ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú Òun. Nígbàtí a bá súnmọ́ Ọlọ́run, ayọ́ tòótọ́ á ṣeé gbámú; irú ayọ̀ báyìí ju gbogbo ìpòǹgbẹ fún ayọ̀káyọ̀ míràn lọ. A lè kún fún ayọ́ tó jinlẹ̀ níwájú Ọlọ́run bíótilẹ̀jẹ́pé ọkàn wa ńsọkún. Irú ayọ̀ báyìí kún wà fún ìwòye tuntun, á sì ṣe onígbọ̀nwọ́ wà ní àkókò ìdojúkọ. Ó ṣàn wá tààrà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá sínú ọkàn wa, ó sì jẹ́ ìfìfẹ́hàn Rẹ̀ sí wa.
Bí Ọlọ́run fúnraarẹ̀ bá ṣ'àjọyọ̀ lórí ẹ̀dá Rẹ̀ ní ọjọ́ keje, mélòómélòó ni àwa náà ní ìdí láti yọ̀, bí a ṣe ń f'ọwọ́sowọ́ pẹ̀lú Rẹ̀ nínú ìjọba Rẹ̀? Nígbàtí a bá ríi mọ̀ wípé ayé wa wá lọ́wọ́ Ọlọ́run aláṣẹ, àti pé ohun gbogbo tí a ní tí a sì níílò wà nínú Rẹ̀, nígbà náà ni ọkàn wa lè yọ̀. Èyí ni ọjọ́-ìsinmi tòótọ́ túmọ̀ sí.
Nítorí ayọ̀ tó fún wa àti èyí tí a ní nínú Rẹ̀, a lè gbádùn ẹ̀bùn Ọlọ́run síi dáadáa; ẹ̀bùn bíi rìírìn àti mímọ rírì ẹ̀dá Ọlọ́run, jíjẹ̀ 'gbádùn oúnjẹ pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́, tàbí ṣíṣe àjọyọ̀ gbogbo ẹbí. Ọjọ́ Àìkú kò ní láti jẹ́ ọjọ́ ìfọkànsìn nìkan. A lè gbádùn rẹ̀ bíi ọjọ́ ìdàpọ̀ àti àjọyọ̀.
ÌBÉÈRÈ FÚN ÀṢÀRÒ
- Báwo ni mo ṣe ń fi ayọ̀ Ọlọ́run hàn ní ọjọ́ Àìkú?
- Bíbélì wípé: "Nítorí ayọ̀ Olúwa ní agbára yín" (Nehemiah 8:10) Ṣé okun àti agbára mi wá nípa ayọ̀ Olúwa tábí nípa ìṣẹ̀lẹ̀ àyíká mi?
- Ṣé mo lè jẹ̀gbádùn ẹ̀bùn Ọlọ́run láì jẹ́ pé mo pòńgbẹ fún òmíràn ní gbogbo ìgbà?
KÓKÓ ÀDÚRÀ
- A gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fi hàn wá bí a ṣe le gbádùn ọjọ́-ìsinmi lọ́tun pẹ̀lú Rẹ̀.
- A gbàdúrà fún ayọ̀ ọ̀run tí ń sọ ayé wa jí láì lákàsí ohun tó ńṣẹlẹ̀ láyèe wa.
- A gbàdúrà pé kí ọjọ́-ìsinmi jẹ́ tí Ẹ̀mí-mímọ́ tí ńru ayọ̀ sókè nínú wa.
- A gbàdúrà pé kí àwọn ilé-ìjọsìn wa ṣe àjọyọ̀ pẹ̀lú agbára ayọ̀ ńlá.
- A ronúpìwàdà kúrò nínú gbogbo ìgbà tí a ti gbá'ju mọ́ ẹ̀bùn Ọlọrun tí a sì sọ Ọlọ́run olùfúnnilẹ́bùn nù.
ÀBÁ ÀDÚRÀ
Olúwa, a dúpẹ́ pé ìwàláàyè Rẹ nìkan ni a níílò. Nínù Rẹ ni a ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ayọ̀. A gbé ojú wa sókè sí Ọ, a sì Yìn Ọ́ nítorí Ìwọ ni Ọlọ́run àti Ọba wa. O seun nítorípé O ń fi hàn wá bí a ṣe lè bù ọlá fún Ọ àti bí a ṣe lè ṣe àjọyọ̀ Rẹ ní ọjọ́-ìsinmi. O ṣeun tí O mú ayé wa ró lọ́wọ́ Rẹ, tí O sì jẹ́ orísun ìdùnnú wa. Àmín.
Deborah Zimmermann, Olùdarí 24-7 Prayer CH, Switzerland.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Àjọ Evangelical Alliance Week of Prayer (WOP) jẹ́ tí gbogbo àgbáyé ṣùgbọ́n ó fì sí ilẹ̀ Yúróòpù tí a sì ṣe àgbékalẹ̀ àwọn ohun-èlò rẹ̀ láti ọwọ́ European Evangelical Alliance. WOP 2022 wáyé lábẹ́ àkòrí "Ọjọ́-ìsinmi." Láàrin ọjọ́ mẹ́jọ a pé àwọn òǹkàwé láti fojúsí ohun kan nípa Ọjọ́- ìsinmi: ìdánimọ̀, ìpèsè, ìsinmi, ìyọ́nú, ìrántí, ayọ́, ìlawọ̀ àti ìrètí. A gbàdúrà pé ohun-èlò yìí yíó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣàwárí lọ́tun ìgbé-ayé tí ó bá ìlànà Ọlọ́run mú!
More