Ọjọ́-Ìsinmi - Gbígbé Ìgbé-ayé ní Ìlànà Ọlọ́runÀpẹrẹ

Sabbath - Living According to God's Rhythm

Ọjọ́ 4 nínú 8

ỌJỌ́ ÌSINMI ÀTI ÌṢÁÁNÚ         

ÀṢÀRÒ

Ọlọ́run kò dá ọjọ́ Ìsinmi kó lè di òfin LÒDÌ sí wa, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ìṣe àánú FÚN wa. Ìdí nìyí tí a fi gba àwọn ọmọ ẹ̀yìn láàyè láti jẹ àwọn orí ọkà láti pa òùngbẹ ebi wọn ní ọjọ́ Ìsinmi (Mátíù 12:1-8). Ìdí nìyí tí ọkùnrin tí ọwọ́ rẹ̀ rọ fi gba ìwòsàn ní ọjọ́ Ìsinmi (Matthew12:9-13). Jésù rí ebi àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ àti ìjìyà ọkùnrin náà Ó sì ṣeé láàánú. Ọjọ́ Ìsinmi jẹ́ ọjọ́ ifara-lókun àti ìwòsàn. Yálà ìfi òfin dè làti ṣe nǹkan (“kíká-wọ́-lọ́wọ́”) tàbí ohun tí ó pè fún láti ṣenǹkan (“rírú ẹbọ”) wọ́n wà ní àárín gbùngbùn Ìsinmi. Kókó àfojúsùn ọjọ́ Ìsinmi ni láti fi àánú Ọlọ́run hàn wá. 

Nínú Májẹ̀mú Láíláí Ìsinmi jẹ́ àfihàn májẹ̀mú láàrin Ọlọ́run àti àwọn ènìyàn Rẹ̀, gẹ́gẹ́ bíi ìkọlà. Ìsinmi jẹ́ ọjọ́ tí a yà sọ́tọ̀ fún ìsinmi, láti fi wo ojú Ọlọ́run nígbàtí ń wòye àánú àti ẹwà ìwà mímọ́ Rẹ̀. “Ẹ̀yin gbọdọ̀ máa pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́. Èyí ni yóò jẹ́ ààmì láàrín èmi àti ẹ̀yin fún ìrandíran tó ń bọ̀, nítorí kí ẹ̀yin lè mọ̀ pé èmi ni Olúwa, ẹni tí ó yà yín sí mímọ́.” (Exodus 31:13). Àwọn ènìyàn Ọlọ́run gba àánú Ọlọ́run, ó “ràn” wọ́n, wọ́n sì ń pín kiri bíi ìbùkún fún gbogbo ayé. 

Nígbàtí a bá pé jọ láti jọ́sìn àti láti jùmọ̀ kẹ́gbẹ́, nígbàtí a bá gbọ́ ohùn Ọlọ́run tí a sì bá A sọ̀rọ̀, à ń gbé ìgbé ayé wa ojojúmọ́ a sì ń yọ̀ níti àánú Rẹ̀. Ní ilé ìjọsìn èrò ìgbìyànjú ọrọ̀ ajé àt'ohun àti èrò eré ìgbafẹ́ ìdárayá, wọ́n fọ́ yángá. Fún ìdí èyí, ètò ìjọ́sìn kìí ṣe oko òwò tàbí ìran idán, yálà akitiyan ẹ̀sìn tàbí ohun lílò fún ẹ̀sìn. Ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ó jẹ́ ibití ọkàn wa ti lè ní ìsinmi àti ibití a ti lè ní ìrírí àánú Ọlọ́run. N'ílé Ìjọ́sìn, Ọlọ́run Ń bá wa lò pẹ̀lú àánú Rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gba àánú Ọlọ́run yóò di ẹni tí ó ń ṣàánú. "Ǹjẹ́ kí ẹ̀yin ní àánú, gẹ́gẹ́ bí Baba yín sì ti ní àánú." (Lúùkù 6:36).

Láti pasẹ̀ ẹ̀bùn àánú, Ọlọ́run Ń palẹ̀ wa mọ́ láti gbé ìgbé ayé àti láti hùwà àánú, láti ṣe rere sí ọmọnìkejì. Ẹsẹ̀ Bíbélì fún òní ń gbà wá níyànjú kí á fi Jésù ṣe onígbọ̀wọ́ wa nínú ayé.

ÀWỌN ÌBÉÈRÈ FÚN ÀṢÀRÒ  

  • Ṣe àròjinlẹ̀ lórí àwọn ǹkan wọ̀nyí: Ọlọ́run kò dá ọjọ́ Ìsinmi kó lè di òfin fún LÒDÌ sí wa, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ìṣe àánú FÚN wa.  
  • Báwo ni mo ṣe lè ní ìrírí àánú Ọlọ́run tí a ṣe àpẹẹrẹ ẹ̀ nínú Ìsinmi ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run àti àwọn ènìyàn tí ó yí mi ká?  
  • Kíni àyípadà kíún tí mo lè ṣe láti fi ìyọ́nú Ọlọ́run ṣe àkọ́kọ́ ní ọjọ́ Ìsinmi––gẹ́gẹ́bí ènìyàn, nínúìdílé, nínú ìjọ?

ÀKỌLÉ ÀDÚRÀ  

  • A gbàdúrà fún àkókò láti tẹjúmọ́ Ọlọ́run. A pa ẹ̀yìn dà kúrọ̀ ní ìrònú wa gbogbo ìgbà tí ó o ma ń tẹjúmọ́ ìgbìyànjú àti àmúlò. À ń béèrè lówó Ọlọ́run fún àánú Rẹ̀ (Kyrie eleison – Lord have mercy!).   
  • A gbàdúrà fún ìdáríjì fún gbogbo àkókò tí ìjọsìn ti di ìjàgbara ẹ̀sìn lásán dípò ìbá pàdé pẹ̀lú Ọlọ́run.  
  • A gbàdúrà fún gbogbo àwọn tí ń wàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti pé kí iṣẹ́ ìránṣẹ́ àánú Rẹ̀ lè di gbígbọ́ àti gbígbà.   
  • A gbàdúrà kí Ọlọ́run ṣí ojú wa, kí á bàa lè wù ìwà àánú sí àwọn aládùúgbò wa gẹ́gẹ́ bí Òun ṣàánú fún wa.   
  • A gbàdúrà kí Ẹ̀mí Mímọ́ fi hàn wá bí a ṣe lè fi Ọlọ́run ṣe kókó kí á sì ṣe ìtọ́jú fún ohun gbogbo tí a dá.

ÀBÁ FÚN ÀDÚRÀ

Ọlọ́run aláàánú, a yìn Ọ̀ a yọ̀ nítorí Rẹ̀! A sìn Ọ. “Mímọ́, Mímọ́, Mímọ́, Olúwa, Ọlọ́run Zeboath (alágbára)”, à ń gbàdúrà pẹ̀lú àwọn ọmọgun áńgẹ́lì. 

Dáríjì wá fún ìmọ tara ẹni àti kí kọjú sí akitiyan wa, nígbàtí ó yẹ ká tẹjú mọ́ Ọ. Ẹ sọ àwọn ìjọsìn wa jí pẹ̀lú Ẹ̀mí Mímọ́ Yín, kí á leè bá Yín pàdé ní ọ̀tun, àti kí àwọn ọkàn wa lè gba áyípadà nípasẹ̀ àánú Rẹ. Bùkún fún gbogbo àwọn tí ó ń wàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ṣí ojú àti ọkàn wa sí àìní àwọn aládùúgbò àti àwùjọ wa. Fún wa ní ìrònú àti ìgboyà láti fi àánú dá oko-owo sínú ìjọ Rẹ àti ayé. Àmín.


Lea Schweyer, Olórí ẹgbẹ́ Evangelical Alliance Ẹ̀ka Riehen-Bettingen, Switzerland.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 3Ọjọ́ 5

Nípa Ìpèsè yìí

Sabbath - Living According to God's Rhythm

Àjọ Evangelical Alliance Week of Prayer (WOP) jẹ́ tí gbogbo àgbáyé ṣùgbọ́n ó fì sí ilẹ̀ Yúróòpù tí a sì ṣe àgbékalẹ̀ àwọn ohun-èlò rẹ̀ láti ọwọ́ European Evangelical Alliance. WOP 2022 wáyé lábẹ́ àkòrí "Ọjọ́-ìsinmi." Láàrin ọjọ́ mẹ́jọ a pé àwọn òǹkàwé láti fojúsí ohun kan nípa Ọjọ́- ìsinmi: ìdánimọ̀, ìpèsè, ìsinmi, ìyọ́nú, ìrántí, ayọ́, ìlawọ̀ àti ìrètí. A gbàdúrà pé ohun-èlò yìí yíó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣàwárí lọ́tun ìgbé-ayé tí ó bá ìlànà Ọlọ́run mú!

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ European Evangelical Alliance fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, Jọ̀wọ́ lọsí: http://www.europeanea.org