Ọjọ́-Ìsinmi - Gbígbé Ìgbé-ayé ní Ìlànà Ọlọ́runÀpẹrẹ

Sabbath - Living According to God's Rhythm

Ọjọ́ 3 nínú 8

ỌJỌ́ ÌSINMI ÀTI ÌSINMI     

ÀṢÀRÒ

Nígbà tí mo wà ní èwe, mo ní àwọn aṣọ fún Ọjọ́ Ìsinmi. Ní alẹ́ Ọjọ́ Àbámẹ́ta ni mo ti máa ń yọ wọ́n síta nítorí ọ̀la jẹ́ Ọjọ́ Ìsinmi. Lẹ́hìn èyí ni ìsinmi. Ní àárọ̀ mo máa ń lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Ọjọ́ Ìsinmi pẹ̀lú àwọn ẹ̀gbọ́n àti àbúrò mi. Ní gbogbo ọ̀sán, àwọn òbí mi máa ń ló àsìkò wọn pẹ̀lú wa. A ó ṣeré pọ̀, a lè kọrin pọ̀ tàbí kí á na'sẹ̀ jáde. Lónì, mo jẹ́ díákónì obìnrin, síbẹ̀ mo sì tún máa ń wọ aṣọ pàtàkì ní Ọjọ́ Ìsinmi. 

Láti ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ ọdún sẹ́hìn ni àwọn Júù àtijọ́ àti àwọn Krìstẹ́nì ti ní ìmọ̀ nípa ìdánuró àti ìsinmi ní Ọjọ́ Ìsinmi. Ìpìlẹ̀ rẹ̀ wà nínú ìtàn ìsẹ̀dá ayé níbi tí Ọlọ́run ti sinmi ní ọjọ́ keje lẹ́hìn ọjọ́ mẹ́fà t'ó fi dá àye. Láti ìgbà tí Jésù ti jínde, ọjọ́ tí ó tẹ̀lé ọjọ́ Ìsinmi Olúwa ni ó ń ṣe atọ́kùn bí nnkan ṣe ń lọ ní àwùjọ àwọn Krìstẹ́nì. Lọ́jọ́ yẹn, wọ́n péjọ láti sìn àti láti ní ìdàpọ̀ nínú ẹ̀mí. 

Ọlọ́run fún wa ní ọjọ́ kan fún ìsinmi-Ọjọ́ Ìsinmi-gẹ́gẹ́ bí ìrànlọ́wọ́ fún wa láti dáwọ́ dúró díẹ̀ kúrò nínú gbogbo àṣà iṣẹ́ síṣe kìràkìtà. Kò pọn dandan kí ọjọ́ ìsinmi jẹ́ ọjọ́ kan gbòógì nínú ọ̀sẹ̀, ṣùgbọ́n ọjọ́kọ́jọ́ t'ó bá jẹ́ gbọdọ̀ yàtọ̀ sí àwọn ọjọ́ t'ó kù. Ọjọ́ Ìsinmi jẹ́ ìrántí fún wa pé àwa ènìyàn níye lórí ju àwọn àṣeyọrí wa lọ. Oníwòsàn àti ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀sìn Albert Schweitzer sọ pé "Nígbà tí ọkàn rẹ kò bá ní Ọjọ́ Ìsinmi, yóò rọ.”

Oníwòsàn àti ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀sìn Albert Schweitzer sọ pé "Nígbà tí ọkàn rẹ kò bá ní Ọjọ́ Ìsinmi, yóò rọ.Ó ti rí ìdákẹ́jẹ́.Níigbà tí a bá wá ìsinmi nínú ìdákẹ́jẹ́ ọkàn wa náa yóò rí ìdákẹ́jẹ́. Ọ̀pọ̀ èrò ọkàn wa tí a lè mú wá síwájú Ọlọ́run ṣùgbọn tí a ti bò mọ́lẹ̀ á ru wá sókè.

Lójoojúmọ́ mo máa ń ya ọgbọ̀n ìṣẹ́jú sọ́tọ̀. Màá lọ síbì kan tí n kò ti ní ní ìdíwọ́ kankan. Màá lọ síwájú Ọlọ́run, síwájú Jésù, gẹ́gẹ́ bí mo ti rí. O tí ń retí mi. Màá bojú wo inú mi, màá fiyè sí bí mo ṣe ń mí, lẹ́hìn yí màá fiyè sí èrò àti ìmọ̀lára mi. Ohunkohun tó bá jẹyọ sí mi, màá mú un wá síwájú Rẹ̀ pẹ̀lú èémí tí mò ń mí jáde. Màá fi sílẹ̀ fún Ọlọ́run láti ṣàkóso rẹ̀. Màá ní sùúrù láti parí àdúrà mi pẹ̀lú ìdúpẹ́. 

Jésù pe àwọn ọmọ ẹ̀hìn Rẹ̀: "Ẹ wá kí á lọ sí ibìkan níkọ̀kọ̀, níbi tí kò sí eniyan, kí ẹ sinmi díẹ̀." (Maku 6:31a) Ní báyìí, Ó ń pè wá láti ṣe bákan náà.

ÀWỌN ÌBÉÈRÈ FÚN ÀṢÀRÒ  

  • Kín ló ń dí mi lọ́wọ́ láti ya àsìkò sọ́tọ̀ fún ìdákẹ́jẹ́ àti ìsinmi?   
  • N jẹ́ mo lè mọ̀ọ́mọ̀ pa ìròhìn tàbí fóònù mi tì sẹ́gbẹ̀ kan f'ọ́jọ́ kan?   
  • Ọlọ́run ti bùkún O sì ti ya ọjọ́ keje sí mímọ́. Njẹ́ mo ṣì ka Ọjọ́ Ìsinmi sí mímọ́? Njẹ́ mò ń rí ìrírí ìbùkún Rẹ̀ lórí Ọjọ́ Ìsinmi?

ÀWỌN ÀKÒRÍ ÀDÚRÀ  

  • A gbàdúrà fún oore ọ̀fẹ́ láti borí ẹ̀rù tí a ní fún ìdákẹ́jẹ́ kí a sì lè kàn wà.  
  • A gbàdúrà pé kí ìpòngbẹ ọkàn wa láti máa wà níwájú Ọlọ́run k'ó má ṣe kú kí á sì le ya àsìkò sọ́tọ̀ fún un nínú ayé wa lójoojúmọ́.  
  • A gbàdúrà pé kí àwọn nnkan tí kò ṣeé ṣàlàyé máa jẹyọ láti ìsàlẹ̀ ọkàn wá nígbà tí a bá wà ní ìdákẹ́jẹ́. A gbàdúrà pé kí á máa dágunlá sì wọn ṣùgbọ́n kí á máa jẹ́wọ́ wọn níwájù Ọlọ́run.  
  • A gbàdúrà fún ọgbọ́n àti ààbò ní àwọn àsìkò ìdákẹ́jẹ́ tí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ru wá sókè.   
  • A gbàdúrà fún àwọn ìjọ àti ilé ìjọ́sìn, àwọn ibi ìsinmi, kí wọ́n jẹ́ ibi tí àwọn ènìyàn yó ti máa gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.  
  • A gbàdúrà fun àwọn tí iṣẹ àti ojúṣe mu lómi tó bẹ́è tí wọn kò lè kọ̀ ẹ̀hìn wọn sí àwọn ìnilára yìi.

ÀBÁ ÀDÚRÀ 

Èmi nìyí níwáju yín, Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí mo ti rí yálà pé mo ti sinmi ni tàbí bẹ́ẹ̀kọ́, ní gbígbẹ worokoko àtí ní òfìfo, tàbí pẹ̀lú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìmoore, pẹ̀lú ìpòngbẹ àbí láì tilẹ̀ ní òye rárá.

Ọlọ́run, ẹ̀yin ni orísun ìyè. Ẹ wá pẹ̀lú agbára ìsọdọ̀tun yín. Ẹ sọ mí di mímọ́, ẹ wò mí sàn, kí n lè di ẹni tí ẹ dá mi láti jẹ́. Àmín.


Arábìnrin Lydia Schranz, Díákónì Obìnrin àti Àlùfáà, Switzerland.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 2Ọjọ́ 4

Nípa Ìpèsè yìí

Sabbath - Living According to God's Rhythm

Àjọ Evangelical Alliance Week of Prayer (WOP) jẹ́ tí gbogbo àgbáyé ṣùgbọ́n ó fì sí ilẹ̀ Yúróòpù tí a sì ṣe àgbékalẹ̀ àwọn ohun-èlò rẹ̀ láti ọwọ́ European Evangelical Alliance. WOP 2022 wáyé lábẹ́ àkòrí "Ọjọ́-ìsinmi." Láàrin ọjọ́ mẹ́jọ a pé àwọn òǹkàwé láti fojúsí ohun kan nípa Ọjọ́- ìsinmi: ìdánimọ̀, ìpèsè, ìsinmi, ìyọ́nú, ìrántí, ayọ́, ìlawọ̀ àti ìrètí. A gbàdúrà pé ohun-èlò yìí yíó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣàwárí lọ́tun ìgbé-ayé tí ó bá ìlànà Ọlọ́run mú!

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ European Evangelical Alliance fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, Jọ̀wọ́ lọsí: http://www.europeanea.org