Ọjọ́-Ìsinmi - Gbígbé Ìgbé-ayé ní Ìlànà Ọlọ́runÀpẹrẹ
ỌJỌ́ ÌSINMI ÀTI ÌRÁNTÍ
ÀṢÀRÒ
Abala Ọ̀rọ̀ Bíbélì yíì jẹ́ ìkéde ti òfin kẹrin. Olúwa pàṣẹ fún wa láti faramọ́ Ọjọ́ ìsinmi, ọjọ́ ìsinmi lẹ́hìn ọjọ́ mẹ́fà fún iṣẹ́- ọjọ́ kan láti ní ìtura. Ní àárín ìsinmi ni ìpè láti rántí: "kí o sì rántí"(Deutoronomy 5:15). Ọjọ́ ìsinmi àti Ìrántí ní ìsopọ̀ tí ó jinlẹ̀, ṣùgbọ́n báwo àti kí nìdí?
Ẹ jẹ́ ká rántí pé ètò ọjọ́ ìsinmi ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ fún gbogbo ènìyàn kò ní àfiwéra nínú ọ̀làjú àtijọ́. Àwọn ará Gíríìkì rò pé àwọn Júù kíi ṣe iṣẹ́ torí pé wọ́n máa ń béèrè ìsinmi ọjọ́ kan lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Ẹ wo irú ẹ̀bùn àrà ọ̀tọ̀ ti Ọlọ́run Sábáàtì jẹ́!
"Ìwọ yóò rántí” ní òtítọ́ méjì: Àkọ́kọ́: “Ẹ̀yin jẹ́ ẹrú ní Íjíbítì.” Èkejì: “Olúwa, Ọlọ́run rẹ ti mú ọ jáde kúrò ní Íjíbítì.” Ní ọ̀rọ̀ mìíràn, wọ́n ti jà ọ́ lómìnira, ṣùgbọ́n nísinsìnyí Olúwa ti mú ọ jáde, ó dá ọ sílẹ̀, Ọjọ́ ìsinmi n rán wa létí bí a ṣe lè gbé ní òmìnira kúrò nínu oko-ẹrú nítorí Ọlọ́run. Ó sọ̀rọ̀ lóri kókó òmìnira, ìyẹn ni òmìnira kúrò nínú ìsìnrú ìṣe tiwa fúnra wa.
Ọdọọdún ni mo máa ń rántí May 8, 1945. Bàbá mi jẹ́ ọmọ ogun ìjọba Nazi, ó sì ní láti máa ṣiṣẹ́ tọ̀sán-tòru. Nígbàtí ó tẹ́tí sí BBC ní ìkòkò tí ó gbọ́ tí ìlọsíwájú ti àwọn ọmọ ogun Amẹ́ríkà, ó sálọ ó sì dé ìlú abínibí rẹ̀ ní Luxembourg ní ọjọ́ ìfọkànn balẹ̀ ti a mẹ́nu bà. Nínú ìsìnrú Nazi àti sínú òmìnira, ó dúpé ìyàlẹ́nu fún àwọn olùdásílẹ̀ rẹ̀. Gbogbo ìrírí tí òmìnira di apákan tí ìdánimọ́ àti ẹ̀rí wa.
Ṣáájú kí Jésù tó fi ara Rẹ̀ hàn mí, èmi gbé nínú ìbẹ̀rù lójoojúmọ́. Nígbàtí ẹ̀mí mímọ́ wá láti gbé nínú ọkàn mi, ó fi àlàáfíà Krístì sínú ìjìnlẹ̀ ìwà mi. Irú àlàáfíà yíì sí wà. A gbà mí lọ́wọ́ ẹrù ńlá mi. Mo mọ̀ mo sì rántí ìdánimọ̀ mi nínú Krístì, àti pé mo pín ẹ̀rí mi pẹ̀lú àwọn míràn.
Rántí, ṣùgbọ́n kìí ṣe fún ara rẹ nìkan. Ní ọjọ́ ìsinmi, àwọn ìránṣẹ́, ẹrú, àti àwọn àjèjì pàápàá yóò sinmi pẹ̀lú wa (Deuteronomi 5:14). Ẹ jẹ́ ká rántí àwọn tó ṣì wà nínú “ẹrú” tí wọn ò tíì gba ìdáǹdè wọn.
ÌBẸ̀RẸ̀ FÚN ÀṢÀRÒ
- Ọlọ́run, Bàbá wa, kò wá àwọn òṣìṣẹ́ lákọ̀ọ́kọ́, bí kò ṣe fún àwọn ọmọ rẹ́ okùnrin àti ọmọbìnrin. Kíni o rò nípa ọ̀rọ̀ yíì? Báwo ni ọjọ́ ìsinmi ṣe ràn ọ́ lọ́wọ́ láti rántí ìyẹn?
- Kíni àwọn ẹ̀rí rẹ ti ìtùsílè tàbí òmìnira tí o gbádùn láti rántí àti sọ?
- Láti le ní òmìnira, a gbọ́dọ̀ rántí. Ṣé òtító nìyẹn? Báwo ni ó ṣe ṣẹ́?
- Àwọn wo ni “ẹrú Íjíbítì” lónìí? Àwọn tí o kò fẹ́ gbàgbé? Àwọn tí o fẹ́ láti gbé ayé rẹ sì?
KÓKÓ ÀDÚRÀ
- A gbàdúrà pé kí Ọlọ́run, Bàbá wa, yóò gbà wá lọ́wọ́ ìbẹ̀rù àti ẹrú ibi nínú ìgbésí ayé wa nípasẹ̀ Jésù Krístì.
- A gbàdúrà pé kí á kọ́ ẹ̀kọ́ láti gbé gẹ́gẹ́ bí ọmọ Ọlọ́run ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin, Bàbá wa, ẹnití ó gbà wá láti gbé nínú agbára ti ẹ̀mí mímó ati gẹ́gẹ́ bi ọ̀rọ̀ rẹ̀.
- A gbàdúrà pé kí ọpẹ́ àti, nítorí náà, ayọ̀ le dàgbà nínú ọkàn wa, nínú àwọn ìdílé wa, àti nínú àwọn ìjọsìn wa.
- A gbàdúrà fún ìtúsílè àwọn ẹ̀rù òde òní (àwọn ọmọ-ogun, àwọn olù fara gbá ti eniyan ati awọn ọmọde tí a jí gbé, ati bẹbẹ lọ).
- A gbàdúrà fún ìtìlẹyìn Ọlọ́run àti ìtúsílè àwọn tí a fi sẹwọn nítorí ìgbàgbó wọn.
ÀDÚRÀ TÍ O LE GBÀ
Mo dúpẹ́ Olúwa. Ìwọ kò fún mi ní ẹ̀mí tí ó mú mi padà sínú ìgbésí ayé ìbẹ̀rù. Bí kò bá sí ohunkóhun, ìwọ ti mú mi wá sínú ìdílé rẹ, èyítí ó sọ mí di ọmọkùnrin rẹ, ọmọbìnrin rẹ. Ìdí nìyẹn tí mo fi sọ ní ohùn òkè pé: “Olúwa” ó jé òtító nítorí ẹ̀mí rẹ Jẹ́rì pé èmi ni ọmọ rẹ. Jésù, èmi ni ajogún ayé re àti ọkàn rẹ. Níbikíbi tí O bá ti dá mi sílè, ràn mí lọ́wọ́ láti mú àwọn tí o fẹ́ràn padà sọ́dọ̀ Bàbá wa. Àti pé tí mo bá ní láti jìyà nítorí Rẹ, Èmi yóò gbá a, nítorí nígbà náà ni a ó fi ògo Rẹ hàn, nísinsìnyí àti fún ayérayé. Àmín. ( Róòmù 8, 14-17)
Paul Hemes, Olukọni HET pro (ẹkọ ẹkọ ẹkọ ẹkọ) St. Légier, Switzerland
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Àjọ Evangelical Alliance Week of Prayer (WOP) jẹ́ tí gbogbo àgbáyé ṣùgbọ́n ó fì sí ilẹ̀ Yúróòpù tí a sì ṣe àgbékalẹ̀ àwọn ohun-èlò rẹ̀ láti ọwọ́ European Evangelical Alliance. WOP 2022 wáyé lábẹ́ àkòrí "Ọjọ́-ìsinmi." Láàrin ọjọ́ mẹ́jọ a pé àwọn òǹkàwé láti fojúsí ohun kan nípa Ọjọ́- ìsinmi: ìdánimọ̀, ìpèsè, ìsinmi, ìyọ́nú, ìrántí, ayọ́, ìlawọ̀ àti ìrètí. A gbàdúrà pé ohun-èlò yìí yíó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣàwárí lọ́tun ìgbé-ayé tí ó bá ìlànà Ọlọ́run mú!
More