Ọjọ́-Ìsinmi - Gbígbé Ìgbé-ayé ní Ìlànà Ọlọ́runÀpẹrẹ
ÌSINMI ÀTI ÌPÈSÈ ỌLỌ́RUN
ÀṢÀRÒ
Láti ìdá kíní nínú mẹ́ta ti ọdún 2020, awọn ènìyàn káàkiri àgbáyé rántí gbogbo àwọn ipò tí ó nira tí àjàkálẹ̀-àrùn dá sílẹ̀. Àwọn àkókò wọ̀nyí rán àwa Kristẹni létí àkókò tí àwọn ènìyàn Ọlọ́run, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, lò nínú aṣálẹ̀, nígbà tí wọ́n fẹ́ pa dà sí oko ẹrú ní Íjíbítì nítorí ebi ń pa wọ́n: “... Àwa ìbá ti ti ọwọ́ OLÚWA kú ní Egipti, nígbàtí àwa jókòó ti ìkòkò ẹran, tí àwa ńjẹ àjẹyó..." (Ẹ́kísódù 16, 3). Ọlọ́run dá Ọjọ́ Ìsinmi gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ìkẹyìn ti ìṣẹ̀dá Rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àmì fún oore-ọ̀fẹ́ Rẹ̀ àti ìpèsè Rẹ̀ fún àwọn ènìyàn Rẹ̀.
Nínú Ẹ́kísódù 20:8 Ọlọ́run rán wa létí pé kí a rọ̀ mọ́ Ọjọ́ Ìsinmi, ọjọ́ ìsinmi fún gbogbo ènìyàn, ọjọ́ tí ó mú gbogbo àìdọ́gba kúrò ní gbogbo apá ìgbésí-ayé, ní pàtàkì fún àwọn tí wọ́n jẹ́ apákan àwọn àwùjọ onírẹ̀lẹ̀. Ọlọ́run fi ìfẹ́ Rẹ̀ hàn sí wa, ó sì ń bá gbogbo àwọn ẹ̀dá Rẹ̀ lò lọ́nà kan náà. Gbogbo wa ni ao le gbadun isimi olorun li ojo isimi.
Ní aṣálẹ̀, Ọlọ́run ń bọ́ àwọn ènìyàn Rẹ̀ pẹ̀lú irú oúnjẹ tuntun kan tí ó túmọ̀ sí “Kí ni ìyẹn?” Ó jẹ́ oúnjẹ tí ó ní àmì ìbéèrè, tí ó sì túmọ̀ láti èdè Hébérù sí “Mann-hou,” mánà. Pẹ̀lú oúnjẹ yìí Ọlọ́run pèsè ọjọ́ ìsinmi sílẹ̀, Ó sì mú kí ó ṣeé ṣe fún àwọn ènìyàn Rẹ̀ láti pèsè fún àti láti jáwọ́ nínú ohun tí wọ́n ti là kọjá ní Íjíbítì.
Lẹ́yìn Ẹ́kísódù 16:4, àwọn ènìyàn náà gba oúnjẹ mánà lójoojúmọ́ gẹ́gẹ́ bí ìpèsè tí ó tó fún ọjọ́ náà. Ọlọ́run ṣe èyí kí wọ́n lè gbọ́ràn sí àwọn ìlànà àti láti lọ síwájú ní ọ̀nà tí a ti là sílẹ̀. Àwa (àwọn ènìyàn tí ó wà nínú aṣálẹ̀ àti àwọn Kristẹni lónìí) ń gba ìgbọràn àti ìbáwí lójoojúmọ́ nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Wọ́n pèsè ìdánilójú oore-ọfẹ Ọlọ́run nínú ìgbésí ayé wa.ÌBÉÈRÈ FÚN ÀṢÀRÒ
- Ṣé a ní “ìkòkò tí ó kún” tí ó yẹ kí á fi rọ́pò oúnjẹ tuntun láti òkè wá?
- Báwo ni Ọlọ́run ṣe pèsè “oúnjẹ tuntun” tí o kò mọ̀ tẹ́lẹ̀ rí? Gbígbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run lójoojúmọ́ gbọ́dọ̀ jẹ́ òtítọ́ fún àwa Kristẹni, ìtọ́ni àti ìbáwí kì í sì í fìgbà gbogbo jẹ́ ara ìgbésí ayé wa. Ṣé ó yẹ kí á ṣàwárí àwọn èròjà wọ̀nyí ní tuntun? Báwo?
KÓKÓ ÀDÚRÀ
- A gbàdúrà fún àwọn Kristẹni tí a ṣe inúnibíni sí ní àgbáyé yìí. Kí wọ́n gba mánà, ìpèsè ojoojúmọ́ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.
- A gbàdúrà fún ìgbàgbọ́ àwọn Kristẹni tí wọ́n ti ṣí wá, pàápàá àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n ń dán ìgbàgbọ́ wọn wò.
- A gbàdúrà pé kí Ọlọ́run tún gbé àwọn ènìyàn bí Mósè (àwọn olórí) dìde ní agbègbè àwọn Kristẹni wa.
ÀBÁ ÀDÚRÀ
Olúwa, ìwọ ni ó tọ́jú àwọn ènìyàn Rẹ nínú aṣálẹ̀. O bọ́ wọn, ṣe ààbò, O sì gbà wọ́n níyànjú. A dúpẹ́ fún oore-ọ̀fẹ́ tí O fi fún àwọn tí O dá sílẹ̀ kúrò ní oko-ẹrú ní Egipti.
O ṣeun fún àwa pẹ̀lú. Ìwọ ti tú wa sílẹ̀ lọ́wọ́ gbígbé nígbèkùn ẹ̀ṣẹ̀, ìwọ sì ti fi wá sínú ìjọba Rẹ. O fi ọ̀rọ̀ Rẹ bó wa. O dáàbò bò wá o sì ń gbà wá níyànjú lójoojúmọ́.
A kọ lílọ padà sí “Egipti” ti ìṣàájú sílẹ̀ a sì yípadà sí ọ, Jésù. Ràn wá lọ́wọ́ láti gbé àwọn àkókò ìsinmi ní iwájú Rẹ, níbití O pèsè gbogbo agbára àti ìgboyà tí àwá nílò láti se ìfẹ́ Rẹ. Àmín.
Joseph Kabongo, Alága tẹ́lẹ̀ rí fún àwọn ìjọsìn Áfíríkà ní Switzerland, Switzerland.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Àjọ Evangelical Alliance Week of Prayer (WOP) jẹ́ tí gbogbo àgbáyé ṣùgbọ́n ó fì sí ilẹ̀ Yúróòpù tí a sì ṣe àgbékalẹ̀ àwọn ohun-èlò rẹ̀ láti ọwọ́ European Evangelical Alliance. WOP 2022 wáyé lábẹ́ àkòrí "Ọjọ́-ìsinmi." Láàrin ọjọ́ mẹ́jọ a pé àwọn òǹkàwé láti fojúsí ohun kan nípa Ọjọ́- ìsinmi: ìdánimọ̀, ìpèsè, ìsinmi, ìyọ́nú, ìrántí, ayọ́, ìlawọ̀ àti ìrètí. A gbàdúrà pé ohun-èlò yìí yíó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣàwárí lọ́tun ìgbé-ayé tí ó bá ìlànà Ọlọ́run mú!
More