Ìmọ̀lára Mímọ́ - Èsì Látinú Bíbélì sí Ìpèníjà GbogboÀpẹrẹ

Holy Emotions - Biblical Responses to Every Challenge

Ọjọ́ 2 nínú 30

Ìgbésí ayé wa kìí ṣe tiwa, ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti fi wọ́n lé wa lọ́wọ́. Padà kí o ka gbólóhùn àkọ́kọ́ yẹn lẹ́ẹ̀kansí: Ìgbésí ayé wa kìí se tiwa, síbẹ̀síbẹ̀ Ọlọ́run ti fi wọn lẹ̀ wa lọ́wọ́. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìtakóra mímọ́ wọ̀nyẹn tí ó mú kí a wo ójú Ọlọ́run tọkàntọkàn pẹ̀lú ìyàlẹ́nu pátápátá.

Òtítọ́ ni - ìwọ jẹ́ iṣé-ṣíṣe ti Ọlọ́run. A ti dá ọ nínú Krístì Jésù nítorí ète kanṣoṣo: nítorí iṣẹ́ rere tí Ọlọ́run ti pète fún ọ ní pàtó ṣájú ìpilẹ̀ṣè aiyé. Ètò Ọlọ́run ni pé kí ẹ máa rìn nínú ìgbésí ayé tí Ó ti wéwèé tí ó sì ti ṣètò fún àǹfààní yín. Sugbon, yiyan tun wa lowo re. O lè níi bóyá ní ọ̀nà tìrẹ tàbí ní ọ̀nà Ọlọ́run.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé o jẹ́ ti Ọlọ́run nítorí pé ó dá ọ àti pé Ó ṣe ètò ìgbé ayé àgbàyanu tẹ́lẹ̀ fún ọ, ó ṣì fi àyànfẹ́ ìgbésí ayé àgbàyanu sí ọwọ́ rẹ. Ọ̀kan nínú àwọn ìsẹ̀lẹ̀ tí ó wúlò jùlọ ti ibití a ti yan Ọlọ́run tàbí yan ara wa ni àwọn àyànfẹ́ ẹ̀dùn àti àwọn ìsesí wa. O gbọ́dọ̀ fi ẹ̀tọ́ rẹ sílẹ̀ láti sọkún kí o sì sọ̀rọ̀ lẹ́yìn náà kí o sì fi tọkàntọkàn gba ètò Ọlọ́run fún ìgbésí ayé rẹ, èyí tí a rí nínú èso ti Ẹ̀mí. A dá yín fún iṣẹ́ rere, kì í ṣe fún iṣẹ́ ti ara tàbí fún èrò ìmọ̀lára yín.

Àwọn iṣẹ rere tí Krístì gbèrò fún ọ ṣáájú kí ó to bí ọ ju kíka ìwé ìfọkànsìn tàbí gbígbọ́ orin ìjọsìn. Àwọn iṣẹ́ rere tí Ọlọ́run ní lọ́kàn nígbà tí ó ronú nípa rẹ jẹ́ ológo tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé látìgbà ayérayé ni ó ti sọ pé ìwọ ni iṣẹ́ ọnà òun gan-an. Ọlọ́run ti ní ojú rẹ̀ lára rẹ láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ àkókò láti ṣe ohun kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nínú ìgbésí ayé rẹ débi pé àwọn áńgẹ́lì pàápàá yóò dúró sẹ́yìn ní kàyéfì, wọn yóò sì máa wù ọ́ láti ṣe ohun tí a dá ọ láti ṣe!
Ọjọ́ 1Ọjọ́ 3

Nípa Ìpèsè yìí

Holy Emotions - Biblical Responses to Every Challenge

Ọlọ́run dá ọ Ó sì fi ọ sí àyè tí o wà ní irú àkókò yìí, to love the unlovable, bii àlàáfíà nínú rúkè rúdò, kí o sì fi ayọ̀ tí kò ṣeé dẹ́kun nínú ìṣẹ̀lẹ̀ gbogbo. À ti ṣe bẹ́ẹ̀ lè jọ pé kò ṣeéṣẹ, ṣùgbọ́n o le è ṣeé tí o bá kọ́ oun tí Bíbélì sọ nípa àwọn ìmọ̀lára ọkàn rẹ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn àti bí o tilè ṣàkóso wọn. Ètò ẹ̀kọ́ yìí dá lórí àwọn ohun tí a kò kà sí àti nígbà míràn awon ohun ìdojúkọ tí kìí ṣe lásán tí à ń bá pàdé lojojúmọ́, ó sì fún wa ní ìtọ́kasí ẹsẹ̀ Bíbélì láti ṣàkóso ìmọ̀lára wa ní ọ̀nà bíi ti Ọlọ́run.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Carol McLeod and Just Joy Ministries fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ̀ síi, jọwọ lọsí: www.justjoyministries.com