Ninu eyiti ẹnyin nyọ̀ pipọ, bi o tilẹ ṣe pe nisisiyi fun igba diẹ, niwọnbi o ti yẹ, a ti fi ọ̀pọlọpọ idanwo bà nyin ninu jẹ: Ki idanwò igbagbọ́ nyin, ti o ni iye lori jù wura ti iṣegbe lọ, bi o tilẹ ṣe pe iná li a fi ndán a wò, ki a le ri i fun iyìn, ati ọlá, ati ninu ogo ni igba ifarahàn Jesu Kristi: Ẹniti ẹnyin fẹ lairi, ẹniti ẹnyin gbagbọ, bi o tilẹ ṣepe ẹ kò ri i nisisiyi, ẹnyin si nyọ ayọ̀ ti a kò le fi ẹnu sọ, ti o si kun fun ogo: Ẹnyin si ngbà opin igbagbọ́ nyin, ani igbala ọkàn nyin; Igbala ti awọn woli wadi, ti nwọn si wá jinlẹ, awọn ti nwọn sọ asọtẹlẹ ti ore-ọfẹ ti mbọ̀ fun nyin: Nwọn nwadi igba wo tabi irú sã wo ni Ẹmi Kristi ti o wà ninu wọn ntọ́ka si, nigbati o jẹri ìya Kristi tẹlẹ ati ogo ti yio tẹlé e. Awọn ẹniti a fihàn fun, pe kì iṣe fun awọn tikarawọn, bikoṣe fun awa ni nwọn ṣe iranṣẹ ohun wọnni, ti a ròhin fun nyin nisisiyi, lati ọdọ awọn ti o ti nwãsu ihinrere fun nyin pẹlu Ẹmí Mimọ́ ti a rán lati ọrun wá; ohun ti awọn angẹli nfẹ lati wò. Nitorina ẹ di ọkàn nyin li amure, ẹ mã wa li airekọja, ki ẹ si mã reti ore-ọfẹ nì titi de opin, eyiti a nmu bọ̀ fun nyin wá ni igba ifarahàn Jesu Kristi
Kà I. Pet 1
Feti si I. Pet 1
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: I. Pet 1:6-13
5 Awọn ọjọ
Nípa ìrètí rẹ̀ nínú lẹ́tá tí ó ko sí ìjọ àkọ́kọ́, Peteru gbà wá níyànjú kí a ní ìgbàgbọ́, kí á sì gbọ́ràn. Ó ní kí á dúró sinsin nínú ìgbàgbọ́ nígbà tí a bá ń kojú àdánwò àti inúnibíni. Ó ní nítorí ẹ̀dá tí a jẹ́ nínú Jésù, a ní agbára láti gbé ìgbá ayé ìwà mímọ́, a ó sì le ní àfojúsùn ogún ayérayé.
10 Days
As Christians, we are not immune to troubles in this world. In fact, John 16:33 promises they will come. If you are facing the storms of life right now, this devotional is for you. It is a reminder of the hope that gets us through life's storms. And if you aren't facing any struggles in this moment, it will give you the foundation that will help you through future trials.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò