Wá Àyè Fún Ohun tó Ṣe Kókó: Ìhùwàsí Ẹ̀mí Márùn-ún Fún Àkókò Lẹ́ńtìÀpẹrẹ

Make Space for What Matters: 5 Spiritual Habits for Lent

Ọjọ́ 6 nínú 7

Ìwà Bárakú tí Ẹ̀mí: Ààwẹ̀

Tí o bá ronú nípa "ààwẹ̀," kí ló máa ń wá sí ọ l'ọ́kàn?

Bóyá ìwòye tìrẹ ni àwọn kan tí wọ́n ń mọ̀ọ́mọ̀ fi ebi pa ara wọn. Bóyá o máa fojú inú wo olùfọkànsìn tí o je pé búrẹ́dì gbígbẹ lásán ni oúnjẹ rẹ̀. Tàbí o jẹ́ enìkan tí o yàn láti má ronú nípa ààwẹ̀ rárá... láí.

Jésù lo ogójì ọjọ́ nínú aginjù tí o ń gba ààwẹ̀. Tí a bá ṣe àgbéyẹ̀wò ìjíròrò Jésù pẹlú àwọn ọmọ ẹ̀hìn rẹ̀, ààwẹ̀ jẹ́ ohun tí Ó l'érò pé àwọn náà yóò máa ṣe pẹ̀lú.

Àmọ́ kí a mọ̀ọ́mọ̀ fi ààyè sílẹ̀ nínú ayé wa láti gbọ́ Ọlọ́run nípa mímú àwọn ohun tí ó gbadùn mọ́ wa kúrò kò rọrùn rárá - pàápàá jùlọ nínú ayé wa yìí tí o gbé ìrọra lékè.

Ìdí mẹ́ta tí ààwẹ̀ fi ṣe pàtàkì:

Ààwẹ̀ a máa fún ohun tí kò jẹ́ kí a ní ìrírí Ọlọ́run lọ́rùn pa. A máa fí tipátipá mú wa ṣàkíyèsí àwọn agbọn ayé wa tí à ń bò m'ọ́lẹ̀ sínú oúnjẹ àjẹjù láàrin òru àti tít'ẹ̀bàti ìkànnì ìbánidọ́ọ̀rẹ́ lọrùn. Nípa bẹ́ẹ̀, ó ńkọ́ wa láti gbára lé Jésù láti bá àìní wa pàdé.

Ààwẹ̀ ńpè wá láti jọ̀wọ́ ohun tí a fẹràn lọ́wọ́ lọ kí a sì fi ààyè sílẹ fún ohun míràn to a fẹràn jù. Bíótilẹ̀jẹ́pé fífi ohun tí a fẹràn, bíi oúnjẹ, lè sòro kí ó sì má rọrùn, ó jẹ́ àǹfàání láti ní ìrírí ayọ̀ ńlá, nítorípé ayọ̀ tòótọ́ máa ń jẹyọ nígbàtí okun wa bá wá láti ọ̀dọ̀ Jésù.

L'ọ̀pọ̀ ìgbà ààwẹ̀ a máa wá síwájú àlùyọ. Mósè gbààwẹ̀ fún ogójì ọjọ́ kí o tó gba òfin mẹwàá, Dáníẹ̀lì gbààwẹ̀ fún ọ̀sẹ̀ mẹ̀ta lẹ́hìn náà o gba ìran, Jésù gbààwẹ̀ fún ogójì ọjọ́ lẹ́hin náà Ó borí ìdánwò èṣù. Nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyí, Ọlọ́run fi ìdí òkodoro múlẹ̀, O fún wọn ní okun, àti àlùyọ lẹ́hìn ìfarajìn tòótọ.

Gbé Ìgbésẹ̀: Gbìyànjú láti parí ààwẹ̀ oníwákàtí mẹ́rìnlélógún. Bí o kò bá kí ńgbààwẹ̀ tẹ́lẹ̀, , keep this exercise simple—àfojúsùn níbí n'ipé kí a parí. Tí ó bá bẹ̀rẹ̀ síí ṣ'àárẹ̀ láàrin ààwẹ̀ rẹ, sọ àárẹ̀ ọkàn yìí di àǹfàání láti bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ kí o sì tẹ́'tí sílẹ̀ sí I. Ní kété tí ó bá ti parí ààwẹ̀ rẹ, kọ ohunkohun tó bá wá sí ọ lọ́kàn lásìkò yìí sílẹ̀.

Ìwé mímọ́

Day 5Day 7

Nípa Ìpèsè yìí

Make Space for What Matters: 5 Spiritual Habits for Lent

Lẹ́ńtì: àkókò ìyẹaraẹniwò àti ìrònúpìwàdà fún ogójì ọjọ́ gbáko. Èròngbà tó dára ni, àmọ́ báwo ní àkókò Lẹ́ńtì ṣe ma ń rí lára? Ní ọjọ́ méje tó ḿbọ̀, ṣe àwárí àwọn ìhùwàsí márùn-ún ti ẹ̀mí tí o lè bẹ̀rẹ̀ ní àkókò àwẹ̀ yí láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ fún ìpèsè sílẹ̀ ọkàn rẹ fún ọjọ́ Àìkú ti Àjíǹde—àti lẹ́yìn rẹ̀.

More

YouVersion ló ṣe ìṣẹ̀dá àti ìpèsè ojúlówó ètò Bíbélì yí.