Wá Àyè Fún Ohun tó Ṣe Kókó: Ìhùwàsí Ẹ̀mí Márùn-ún Fún Àkókò Lẹ́ńtìÀpẹrẹ
Àwọn Àṣà Ẹ̀mí: Àdúrà
Ǹjẹ́ ohun kan wà tí ó ńdí o lọ́wọ́ láti máa bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ nígbà gbogbo?
Àdúrà ní ṣókí túmọ̀ sí bíbá Ọlọ́run sọ̀rọ̀, àti títẹ́tísí ohùn Rẹ̀. Àti nítorípé Jésù sọ nígbà púpọ̀ wípé, "Nígbàtí ẹ bá ńgbàdúrà...," èyí jẹ́ kí á mọ̀ wípé ó ńretí kí á gbàdúrà, pẹ̀lú
Kí Àdúrà gbígbà tó lè mọ́ wa lára, oní láti ní ìwà àti máa gbàdúrà léra léra, sùgbọ́n èyí kò ní kí o má fi ìgboyà lépa ìbárẹ́ pẹ̀lú Rẹ̀.
Ọlọ́run ńdúró láti sún mọ́ ọ ní gbogbo ìgbà, kòsì sí ohun kan tí o lè sọ tí ó lè dá a dúró láti fẹ́ràn rẹ
Àsìkò lẹ́ǹtì jẹ́ àsìkò tí a le bẹ̀rẹ̀ sí ní mú Àdúrà gbígbà lójoojúmọ́ gẹ́gẹ́ bíi ìwà. Bí o bá ṣètò ayé rẹ yíká Ọlọ́run ṣùgbọ́n tí o kò ní àsìkò láti máa báa sọ̀rọ̀, yíò ṣòro kí o tó lè gbájúmọ́
Ó rọrùn láti dàgbà nínú ẹ̀mí nígbàtí o bá s'òtítọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run nípa ìdàgbàsókè rẹ. Àti nígbàtí o bá bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ nípa bí o se ńtẹ̀síwájú, yíò má rán ọ létí wípé Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ nítòótó, àti wípé ó jẹ́ ìdùnnú fún Ọlọ́run láti wà pẹ̀lú rẹ. Nítorínáà lónì, wá àkókò láti bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ nítòótó.
Gbé Ìgbésẹ̀Tí ohun tí o fẹ́ gbàdúrà lé lórí ò bá dá o lójú, gbìyànjú kí o lo Àdúrà Olúwa, kí o wá gbà fún ara rẹ.
Baba wa tí ńbẹ ní ọ̀run,
kí á bọ̀wọ̀ fún orúkọ mímọ́ Rẹ.
Kí ìjọba Rẹ dé láìpẹ́.
Ìfẹ́ tìrẹ ni kí á se ní ayé,
bí wọ́n tí ńṣe ní ọ̀run.
Fún wa ní oúnjẹ òòjọ́ wa lónìí,
kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jìn wá,
gẹ́gẹ́ bí àwa náà tí dárí ji àwọn
tí wọ́n sẹ̀ wá.
má fà wá sínú ìdánwò,
ṣùgbọ́ngbà wá lọ́wọ́èsù.
Matiu 6:9-13 BM
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Lẹ́ńtì: àkókò ìyẹaraẹniwò àti ìrònúpìwàdà fún ogójì ọjọ́ gbáko. Èròngbà tó dára ni, àmọ́ báwo ní àkókò Lẹ́ńtì ṣe ma ń rí lára? Ní ọjọ́ méje tó ḿbọ̀, ṣe àwárí àwọn ìhùwàsí márùn-ún ti ẹ̀mí tí o lè bẹ̀rẹ̀ ní àkókò àwẹ̀ yí láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ fún ìpèsè sílẹ̀ ọkàn rẹ fún ọjọ́ Àìkú ti Àjíǹde—àti lẹ́yìn rẹ̀.
More