Wá Àyè Fún Ohun tó Ṣe Kókó: Ìhùwàsí Ẹ̀mí Márùn-ún Fún Àkókò Lẹ́ńtìÀpẹrẹ
Kínni Èrèdí Lé̩ntì
Dára ró díẹ̀ kí o sì b'ojú wo ìta. Kí lo rí? Kí ló mú ọ rẹ́rìnín músé̩?
Ohunkóhun tí o ṣàpèjúwe yii - ó ti ti wà níbẹ̀ tipé̩ - ò kàn n dúró de ìgbà tí ìwọ yóò ṣe àkíyèsí rẹ̀ ni.
Èyí gan an ni èrèdí Lé̩ntì: láti fi ààyè sílẹ̀ láàrin àwọn ojúṣe ojojúmó̩ láti mọ rírì àwọn nnkan tí a kò fiyè sí té̩lẹ̀ - ìwàláàyè Ọló̩run.
Lé̩ntì jé̩ ogójì ọjó̩ tó ṣíwájú ọjó̩ ìsinni Àjínde. Gé̩gé̩ bí Jésù ṣe lo ogójì ọjó̩ nínú aginjù, Lé̩ntì jẹ̄ ohun èlò tí ó le mú kí o mò̩ nípa ohùn Ọló̩run àti ìrúbọ ìfẹ́ Rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jé̩ pé kò sí Lé̩ntì gẹ́gé̩ bí ò̩rọ̀ tààrà nínú Bíbélì, Ìgbìmò̩ Nísíà jíròrò lórí rè̩ ní ọdún 325 AD pé ó pèsè àsìkò àròjinlẹ̀ àti ìrònúpìwàdà fùn àwọn Krìsté̩nì lóòrè kóòrè bí àwọn òdòdó ṣe ń tají lẹ́hìn àsìkò òtútù - àsìkò tí a máa ń rí bíi ìbè̩rẹ̀ ìgbà ọ̀tun.
Èrèdí Lé̩ntì kìi ṣe láti "mú kí ayé rẹ dára" bí kò ṣe láti jé̩ kí o gbé ayé rẹ lórí ohun tó ṣe pàtàkì jù: Ẹni tí ó dá ọ tí ó sì kú fún ọ. Ọ̀kan nínú àwọn ò̩nà tí o fi lè ṣe èyí ni nípa àwọn ìṣesì ẹ̀mí
Nítorí náà, bí o ṣe n palẹ̀mọ́ fún O̩jọ́ Ìsinmi Àjínde, jẹ́ kí á sàwárí àwọn ìṣesí ẹ̀mí tí o lè máa ṣe lásìkò yẹn, tí o sì lè sọ di ìṣe ojojúmọ́a
Jé̩ kí á jù mọ̀ wá ààyè fùn ohun tí ó ṣe pàtàkì.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Lẹ́ńtì: àkókò ìyẹaraẹniwò àti ìrònúpìwàdà fún ogójì ọjọ́ gbáko. Èròngbà tó dára ni, àmọ́ báwo ní àkókò Lẹ́ńtì ṣe ma ń rí lára? Ní ọjọ́ méje tó ḿbọ̀, ṣe àwárí àwọn ìhùwàsí márùn-ún ti ẹ̀mí tí o lè bẹ̀rẹ̀ ní àkókò àwẹ̀ yí láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ fún ìpèsè sílẹ̀ ọkàn rẹ fún ọjọ́ Àìkú ti Àjíǹde—àti lẹ́yìn rẹ̀.
More