Wá Àyè Fún Ohun tó Ṣe Kókó: Ìhùwàsí Ẹ̀mí Márùn-ún Fún Àkókò Lẹ́ńtìÀpẹrẹ

Make Space for What Matters: 5 Spiritual Habits for Lent

Ọjọ́ 3 nínú 7

Àwọn Ìhùwàsí Ẹ̀mí: Àṣàrò

Iṣẹ́. Ẹ̀kọ́. Ìbáṣepọ̀. Ìléra. Ìnáwó. Àjàkálẹ̀-Àrùn. Pẹ̀lú onírúurú ǹkan tí à ń là kọjá lóde òní, ó rọrùn láti y'asẹ̀ àgẹ̀rẹ̀ kúrò nínú àwọn ǹkan tí a fẹ́ fún ara wa. 

Fún ìdí èyí t'ẹsẹ̀ dúró kí o sì fa èémí sí'mú. Bí o ti ń padà mí síta, fojú inú rí araà rẹ bí o ti ń gbé gbogbo àjàgà tó lè mú ẹ mẹ́hẹ kúrò. Ní báyìí, fi àwọn ọ̀rọ̀ yí ṣe àfojúsùn:  

Ẹ̀mí Ọlọ́run náà ni a fi dá mi, àti wípé èémí Ọ̀gá-Ògo ń fún mi ìyè. Jóòbù 33:4 ESV

Fi ìṣẹ́jú kan ronú nípa ẹsẹ̀ Bíbélì yẹn. Tún un kà lẹ́sẹẹsẹ kí o sì ṣe àkíyèsí ọ̀rọ̀ kààǹkan. 

Bí o ti ńṣe àṣàrò lórí ẹsẹ̀ Bíbélì yí, gba èyí rò: Ẹni tí ó fi èémí ṣe ìṣẹ̀dá rẹ ńṣe ìpamọ́ èémí rẹ. Lóòótọ́ ni ǹkan lè má rọgbọ ní ìgbà míràn, ṣùgbọ́n ìwọ kò jìnà sí Ọlọ́run tó dá ọ tí ó sì fún ọ lórúkọ. 

T'ẹsẹ̀ dúró lẹ́ẹ̀kan si. 

Ǹkan tí o kà tán yí jẹ́ àpẹrẹ àṣàrò nínú Ìwé Mímọ́. A sọ̀rọ̀ nípa àṣàrò nínú Bíbélì ní ìgbà mélòó kan láti ri dájú wípé àwọn ọmọ lẹ́yìn Ọlọ́run lè tún àfojúsùn wọn lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe. 

Àṣàrò kìíṣe ǹkan tí a lè fi ipá ara wa ṣe. Ó nííṣe pẹ̀lú fífà súnmọ́ Ọlọ́run àti bíbèrè fún Un láti fi àwọn èrò àti ọ̀nà rẹ̀ hàn sí wa. 

Ṣíṣe àṣàrò nínú Bíbélì ma ń ràn wá lọ́wọ́ láti rí àwọn ìlàkọjá wa pẹ̀lú ìhà mímọ́ nítorí à ń gba ǹkan mímọ́ láàyè láti yí ìrírí wa padà. Nígbà tí a bá wá àyè láti ṣe àṣàrò nínú Ìwé Mímọ́, à ń yàn láti yí àfojúsùn wa kúrò lọ́dọ̀ ara wa àti ayé, padà s'ọ́dọ̀ Ọlọ́run àti Ọ̀rọ̀ Rẹ̀. À ń gba Ọlọ́run láàyè láti yí èrò àti ìrísí wa padà. 

Bí o ti ń múra sílẹ̀ de ọ̀sẹ̀ tó ḿbọ̀, gbìyànjú láti mọ̀ọ́mọ̀ pa ọkàn rẹ pọ̀ lórí Ọlọ́run àti Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ lójojúmọ́. 

Gbé Ìgbésẹ̀: Gba Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láàyè láti ma gbé'nú rẹ ní àkókò Lẹ́ńtì nípasẹ̀ kíkọ́ àkọ́sórí gbogbo Ẹsẹ̀ Bíbélì t'Òní. Bí o ti ńṣe èyí, ṣe àkíyèsí àwọn ọ̀rọ̀ àti gbólóhùn tó tayọ, kí o sì bèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run láti fi ẹ̀kọ́ inú ẹsẹ̀ Bíbélì náà hàn sí ọ.

Day 2Day 4

Nípa Ìpèsè yìí

Make Space for What Matters: 5 Spiritual Habits for Lent

Lẹ́ńtì: àkókò ìyẹaraẹniwò àti ìrònúpìwàdà fún ogójì ọjọ́ gbáko. Èròngbà tó dára ni, àmọ́ báwo ní àkókò Lẹ́ńtì ṣe ma ń rí lára? Ní ọjọ́ méje tó ḿbọ̀, ṣe àwárí àwọn ìhùwàsí márùn-ún ti ẹ̀mí tí o lè bẹ̀rẹ̀ ní àkókò àwẹ̀ yí láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ fún ìpèsè sílẹ̀ ọkàn rẹ fún ọjọ́ Àìkú ti Àjíǹde—àti lẹ́yìn rẹ̀.

More

YouVersion ló ṣe ìṣẹ̀dá àti ìpèsè ojúlówó ètò Bíbélì yí.