Wá Àyè Fún Ohun tó Ṣe Kókó: Ìhùwàsí Ẹ̀mí Márùn-ún Fún Àkókò Lẹ́ńtìÀpẹrẹ
Ìhùwàsí ti Ẹ̀mí: Ìdákẹ́rọ́rọ́
Fi ojú inú wo ara rẹ bí o ti dá wà lórí òkè kan. Odò kan sì ń ṣàn kọjá l'ẹ̀gbẹ́ rẹ bí àwọn ẹyẹ ti ń kọrin lápá kan. Òrùn ń ràn s'ójú rẹ bí atẹ́gùn náà ti ń fẹ́ sí ẹ fẹ́rẹ̀ẹ́. Ohun gbogbo wà ní Ìdákẹ́rọ́rọ́—àmọ́ àwọn ǹkan tí o fẹ́ ṣe ló gba ọkàn rẹ kan, pẹ̀lú àwọn ìṣòro tí o kò lè rán, àti àwọn ìpèníjà tí o kò lè yí padà. nííṣe tí o bá padà délé ló gba ọkàn rẹ kan. Lóòótọ́ lọ wà níbi tó dákẹ́ rọ́rọ́, àmọ́ ìró èrò ọkàn rẹ kò gbà ọ́ láàyè láti jẹ̀gbádùn ẹwà ìṣẹ̀dá tó yí ẹ ká ní àkókò náà.
Kíni ǹkan tó ma gbà ẹ́ láti t'ẹsẹ̀ dúró, mú ariwo náà dúró, kí o sì wà ní ìdákẹ́rọ́rọ́?
Nínú ìdákẹ́rọ́rọ́ yìí, ni a ti ní àǹfààní láti kọ́ bí a ti ń kọbiara sí àwọn ǹkan tí Ọlọ́run ń gb'éṣe ní ayé àti àyíká wa. Àmọ́ ìdákẹ́rọ́rọ́ a máa wà ní ibi ìpalọ́lọ́ àti ibi aápọn pẹ̀lú. Ó nííṣe pẹ̀lú bí a ti ń gba Ọlọ́run láàyè láti fi àfojúsùn àti etí ìgbọ́ wa s'ọ́dọ̀ Rẹ̀ bí a ti ń jọ̀wọ́ ariwo inú ọkàn wa fún un. Wàyì ó a nílò láti jọ̀wọ́ gbogbo ìpòrúru, ìfiyèsí, àti ìṣòro wa fún Ọlọ́run bí a ti ń Gbàá láàyè láti tún àfojúsùn waṣe.
Bí a ti ń fi ìhùwàsí ẹ̀mí yìí sí ojúṣe, a máa túbọ̀ wà nípò láti fi ògo f'Ọ́lọ́run fún agbára Rẹ̀ tó ń ṣú yọ láyé wa nítorí a máa bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe àkíyèsí àwọn ǹkan tí Ọlọ́run ńṣe nínú ayee wa.
Ìgbésẹ̀: Ya wákàtí kéréje nínú ọ̀sẹ̀ sọ́tọ̀ kí o sì fi àkókò náà kọ́ bí a ti ń jọ̀wọ́ gbogbo ìpòrúru ọkàn ẹni fún Ọlọ́run. Kò burú tí o bá nílò láti ṣe èyí léraléra fún ìgbà díẹ̀. Ṣáà lo àkókò yí láti pa gbogbo ariwo inú ọkàn rẹ lẹ́nu mọ́ àti láti ní ìhùwàsí wíwá àyè láti máa gbọ́ ohùn Ọlọ́run.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Lẹ́ńtì: àkókò ìyẹaraẹniwò àti ìrònúpìwàdà fún ogójì ọjọ́ gbáko. Èròngbà tó dára ni, àmọ́ báwo ní àkókò Lẹ́ńtì ṣe ma ń rí lára? Ní ọjọ́ méje tó ḿbọ̀, ṣe àwárí àwọn ìhùwàsí márùn-ún ti ẹ̀mí tí o lè bẹ̀rẹ̀ ní àkókò àwẹ̀ yí láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ fún ìpèsè sílẹ̀ ọkàn rẹ fún ọjọ́ Àìkú ti Àjíǹde—àti lẹ́yìn rẹ̀.
More