Bẹ̀rẹ̀ L'ọ́tunÀpẹrẹ
“Ipò-Ó-Dójú-Ẹ̀" Ìpadà Bọ̀ Ẹlẹ́ẹ̀kejì
Tí a bá wò yíká wa, tí a wo àwọn àjálù bíi ilẹ̀ mímì ati ìjì líle, ìṣèlú tí kò dúró déédé àti àìbalẹ̀ ọkàn, afi-àdó-olóró-para-ẹni-mó-ni, àkọlù lọ́wọ́ apániláyà, ó rọrùn láti lérò pé a wà nínú “ipò-ó-dójú-ẹ̀." Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àìdánilójú ló wà nínú ọjọ́ ọ̀la. Ṣùgbọ́n èyí dá wa lójú: Jésù ń padà bọ̀ àti pẹ̀lú pé a ó fi iná pa ayé rẹ́.
Bí a ti ṣe ń rí ọ̀pọ̀ orílẹ̀ èdè ti ṣe ń kígbe “ipò-ó-dójú-ẹ̀" láàrín oríṣiríṣi ìṣẹ̀lẹ̀, ẹ jẹ́ kí á wòye bóyá a nílò “ipò-ó-dójú-ẹ̀" nípa nǹkan ti ẹ̀mí bí a ti ṣe ń palẹ̀ mọ́
ìpadà bọ̀ ẹlẹ́kejì Jésù!
Nínú 2 Peter 3:1-13, Pétérù sọ fún wa pé ìlérí pé Jésù ń padà bọ̀ yóò sì wá sí ìmúṣẹ. Kíni Pétérù sọ pé yóò ṣẹlẹ̀ sí ayé ni ẹsẹ̀ 10? A ó fi iná pa ayé rẹ́. Ka ẹsẹ̀ 8 léèkan si. Kíni o rò pé eléyìí túmọ̀ sí?
Gẹ́gẹ́ bí ẹsẹ̀ 9 ṣe lọ, kí ni ìdí tí Ọlọ́run fi ń dúró láti mú ìlérí ìpadà bọ̀ Rẹ̀ ṣe àti ti pípa ayé rẹ́? Nítorí Kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni ṣègbé. Ìdí kan ṣoṣo tí Ọlọ́run fi lọ́ra àti ṣe oun tí ó gbẹ̀yìn àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìtàn ayé ni ìfẹ́ Rẹ̀ pé kí ẹnikẹ́ni má bàa ṣègbé, ṣùgbọ́n kí gbogbo ènìyàn lè wá sí ìrònúpìwàdà.
Ka ẹsẹ̀ 14. Ìdánilójú ìpadà bọ̀ Jésù ẹlẹ́kejì àti ìparun ayé pẹ̀lú iná tó ń bọ̀ yẹ kí ó nííṣe pẹ̀lú bí a ṣe ń gbé ayé wa ojojúmọ́. Kíni ẹsẹ̀ yí sọ pé ayé wa ṣé gbọ́dọ̀ rí?
A gbọ́dọ̀ wà láì ní àbàwọ́n, àìníẹ̀bi àti kí á wà ní àlàáfíà pẹ̀lú Rẹ̀. Èyí ni ìpè fún wa láti bẹ̀rẹ̀ ní lẹ́ẹ̀kan si. Láti bẹ̀rẹ̀ ní ọ̀tun.
Tí o bá mọ̀ dájú pé Ìpadà Bọ̀ Ẹlẹ́ẹ̀kejì yóò ṣẹlẹ̀ ní ìwọ̀n oṣù mẹ́ta sí òní, kíni o ó ṣe yàtọ̀? Ṣe àpẹẹrẹ àwọn oun tí oó kò sílẹ̀ ní ṣíṣe àti àwọn ohun tí oó bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe.
Ka ẹsẹ̀ 14 lẹ́ẹ̀kan si. Bí o ṣe ń ronú nípa bí ó ti ṣe ń gbé ìgbé ayé rẹ, kíni àwọn nkan tó o nílò láti ṣe kí o bàa "wà ní àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run”?
Pẹ̀lú gbogbo eléyìí lọ́kàn, ǹjẹ́ o ṣe tán láti pàdé Rẹ̀? Bíbẹ́ẹ̀kọ́, màá yá a palẹ̀mọ́! Nígbàtí a bá gbọ́ irú iṣẹ́ báyìí, ó yẹ kí ó mú àwọn aṣáko ronú ewu ìjàmbá burúkú tí wọn wà kí ó sì mú wọn sáré tọ Jésù ní ìrònúpìwàdà. Bí ẹsẹ̀ 10 ti rán wa létí, dídé Rẹ̀, yóò jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ òjijì!
Ní báyìí, ẹ jẹ́ kí á yẹ ọkàn wa wò bóyá àwọn oun kankan wà tí a nílò láti yanjú, ẹ jẹ́ ká mú wọn wá sọ́dọ̀ Jésù kí ó sì gbáradì fún ìgbà sókè. Nítorípé, Jésù ń bọ̀.
Àwọn ò títọ́ yìí yẹ kó rú ọkàn àwọn ènìyàn Ọlọ́run kó sì mú wa fẹ́ súnmọ Jésù pẹ́pẹ́ kí á bá lè lò wá láti fi ipa ṣílẹ̀ nínú ayé, ní ìwọ̀nba àkókò tí ó ku. Ogunlọ́gọ̀ ló yí wa ká tí wọn kò ì tí gba Jésù gẹ́gẹ́ bíi Olùgbàlà. O le è jẹ́ ẹni tí yoo ba wọn pàdé.
Bí o ṣe ń ro àwọn nǹkan wọ̀nyí, tani o ní ìgbàgbọ́ pé Ọlọ́run fẹ́ kí o bá sọ̀rọ̀ ní ọ̀sẹ̀ yí? Àwọn mọ̀lẹ́bí, ọ̀rẹ́, àti aládùúgbò wo ni o ní tí ó kù láti mọ Jésù ní ìbáṣepọ̀ tó jinlẹ̀? Ẹ jẹ́ ká fi oun gbogbo sílẹ̀ lákòókò yí kí á sì gba àdúrà jẹ́jẹ́ báyìí. Gbàdúrà pé wọn yóò wá sọ́dọ̀ Jésù ṣáájú Bíbọ̀ Ẹlẹ́ẹ̀kejì àti ìparun ayé pẹ̀lú iná.
Àkókò Àdúrà:
Gbàdúrà pé a óò ní ẹ̀mí ìṣe kíákíá (ipò-ó-dójú-ẹ̀) nípa òye pé à ń gbé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ṣáájú ìpadàbọ̀ Jésù èkejì àti òpin ayé.
Gbàdúrà pé kí Ọlọ́run darí wa sí àwọn tí Ó fẹ́ kí á bá pín Ìròhìn Ayọ̀ nípa Jésù lọ́ṣẹ̀ yí.

Nípa Ìpèsè yìí
Ọdún Tuntun. Ọjọ́ Tuntun. Ọlọ́run ṣ'ẹ̀dá gbogbo ìsípòpadà yìí láti rán wá l'étí pé Òun ni Ọlọ́run Ìbẹ̀rẹ̀ Ohun Tuntun. Bí ó bá jẹ́ pé Ọlọ́run fí ọ̀rọ̀ dá ayé, Ó lè s'ọ̀rọ̀ sí òkùnkùn ayé rẹ, kí Ó ṣ'ẹ̀dá ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tun fún ọ. Ṣé o kò sàì f'ẹ́ràn ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tun! Gẹ́gẹ́ bíi ìlànà ẹ̀kọ́ yìí! Máa bá wá kálọ!
More
A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Ògbéni Boris Joaquin, Ààrẹ àti Gíwá Àgbà fún Breakthrough Leadership Management Consultancy. Òun ni olùkọ́ àgbà àti olùdánilẹ́kọ̀ọ́ tó mú yányán jùlọ nínú ẹ̀kọ́ ìdarí àti àwọn ẹ̀kọ́ ìgbáyé-gbádùn ní ìlú Philippines. Òun pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀ Michelle Joaquin, ni wọ́n jọ ṣ'ètò ìlànà ẹ̀kọ́ yìí. Fún àlàyé kíkún, jọ̀wọ́ kàn sí http://www.theprojectpurpose.com/