Ṣugbọn awa kò fẹ ki ẹnyin ki o jẹ òpe, ará, niti awọn ti o sùn, pe ki ẹ má binujẹ gẹgẹ bi awọn iyoku ti kò ni ireti. Nitori bi awa ba gbagbọ́ pe Jesu ti kú, o si ti jinde, gẹgẹ bẹ̃ni Ọlọrun yio mu awọn ti o sùn pẹlu ninu Jesu wá pẹlu ara rẹ̀. Nitori eyiyi li awa nwi fun nyin nipa ọ̀rọ Oluwa, pe awa ti o wà lãye, ti a si kù lẹhin de atiwá Oluwa, bi o ti wu ki o ri kì yio ṣaju awọn ti o sùn. Nitori Oluwa tikararẹ̀ yio sọkalẹ lati ọrun wá ti on ti ariwo, pẹlu ohùn olori awọn angẹli, ati pẹlu ipè Ọlọrun; awọn okú ninu Kristi ni yio si kọ́ jinde: Nigbana li a ó si gbà awa ti o wà lãye ti o si kù lẹhin soke pẹlu wọn sinu awọsanma, lati pade Oluwa li oju ọrun: bẹ̃li awa ó si ma wà titi lai lọdọ Oluwa. Nitorina, ẹ mã fi ọ̀rọ wọnyi tu ara nyin ninu.
Kà I. Tes 4
Feti si I. Tes 4
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: I. Tes 4:13-18
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò