Bẹ̀rẹ̀ L'ọ́tunÀpẹrẹ

Begin Again

Ọjọ́ 1 nínú 7

Ìbẹ̀rẹ̀ Ọ̀tun
Mo fẹ́ràn láti s'ípò padà w'ọnú ọdún tuntun. Gẹ́gẹ́ bí mo ti fẹràn láti rí ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ tuntun. Mo gbàgbọ́ pé Ọlọ́run ṣ'ẹ̀dá àwọn ìgbà ìṣípòpadà yìí láti rán wa l'étí pé Òun ni Ọlọ́run Ìbẹ̀rẹ̀ Ọ̀tun.

Ọlọ́run lè ṣ'ẹ̀dà nǹkan jáde láti inu òfìfo. Bíi ìkòkò amọ̀, Ó lè mọ nǹkan jáde láti inú àkójọpọ̀ ñkan rúdurùdu. Ó lè mú ọkàn rẹ tó ti dàrú, dọ̀tí, àti tó tí díbàjẹ́, kí Ó sì sọ ọ́ di ọkàn tó mọ́, tó ní pinnu - Á á sọ di pípé padà!

Bí ó ti rí ní Gẹ́nẹ́sìsì níbití Ọlọ́run tí ṣ'òrọ sínú òfìfo àti òkùnkùn láti ṣe ẹ̀dá àgbáláayé, àwọn ìràwọ̀ àti ayé wa yìí. Ọlọ́run fí ọ̀rọ̀ ṣ'èdá ayé. Ọlọ́run lè s'ọ̀rọ̀ sínú òkùnkùn ayé rẹ pẹ̀lú, kí Ó sì ṣ'èdá ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tun fún ọ.

Fún bíi ọjọ́ mélòó kan, jẹ́ kí n ṣe atọ́nà rẹ nínú ẹ̀kọ́ nípa àwọn tí wọ́n ti jọ̀wọ̀ rúdurúdu ayé wọn fún Ọlọ́run. Ìṣẹ̀lẹ̀ àyíká, àyídáyidà, àti ohun tí wọn ń là kọjá kò darí ayé wọn mọ́. Ṣùgbọ́n wọ́n gbà pé àwọn lè rí ojútùú tó tọ́, ìgbé ayé gidi, ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tun nípasẹ̀ Ọmọ Ọlọ́run, Jésù Krístì ( Ka 1 Kọ́ríntì 1:30).

Kódà ní báyìí, Ó lè s'ọ̀rọ̀ sínú rúdudùru ayé rẹ kí O sì fún ọ ní ìrètí ọ̀tun, àti agbára ọ̀tun.

Ka Sáámù Psalm 51:10. Ọlọ́run fẹ́ láti rí ọ ní mímọ́, nítorí náà O fẹ́ k'ópa gidi ní ṣíṣ'ẹ̀dá ọkàn tuntun fún ọ kí Ó sì mú ètò wá sínú rúdurùdu ayé rẹ. Ohun tí o ní láti ṣe ni pé kí o rẹ ara rẹ sílẹ̀ níwájú Rẹ̀, kí o sì tẹríba fún ìṣèjọba Rẹ̀.

Sọ wípé, “Dá àyà tuntun sínú mi, Ọlọ́run, kí O sì tún ọkàn ìdúróṣinṣin ṣe nínú mi.” Gbàdúrà pé, “Ọlọ́run, bẹ̀rẹ̀ ìgbà ọ̀tun láyé mi, yàtọ̀ sí gbogbo rúdudùru, jẹ́ kí n bẹ̀rẹ̀ l'ọ́tun.”

Mo fẹràn ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tun! Gẹ́gẹ́ bíi ìlànà ẹ̀kọ́ yìí. Máa bá wa kálọ!
Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

Begin Again

Ọdún Tuntun. Ọjọ́ Tuntun. Ọlọ́run ṣ'ẹ̀dá gbogbo ìsípòpadà yìí láti rán wá l'étí pé Òun ni Ọlọ́run Ìbẹ̀rẹ̀ Ohun Tuntun. Bí ó bá jẹ́ pé Ọlọ́run fí ọ̀rọ̀ dá ayé, Ó lè s'ọ̀rọ̀ sí òkùnkùn ayé rẹ, kí Ó ṣ'ẹ̀dá ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tun fún ọ. Ṣé o kò sàì f'ẹ́ràn ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tun! Gẹ́gẹ́ bíi ìlànà ẹ̀kọ́ yìí! Máa bá wá kálọ!

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Ògbéni Boris Joaquin, Ààrẹ àti Gíwá Àgbà fún Breakthrough Leadership Management Consultancy. Òun ni olùkọ́ àgbà àti olùdánilẹ́kọ̀ọ́ tó mú yányán jùlọ nínú ẹ̀kọ́ ìdarí àti àwọn ẹ̀kọ́ ìgbáyé-gbádùn ní ìlú Philippines. Òun pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀ Michelle Joaquin, ni wọ́n jọ ṣ'ètò ìlànà ẹ̀kọ́ yìí. Fún àlàyé kíkún, jọ̀wọ́ kàn sí http://www.theprojectpurpose.com/