Bẹ̀rẹ̀ L'ọ́tunÀpẹrẹ

Begin Again

Ọjọ́ 4 nínú 7

Oore Ọ̀fé̩ Ọló̩run: Ọwó̩ tí Ó Nà Jáde

Mo máa ń ronú ipò tí obìnrin yẹn wà: ìtìjú àti ẹ̀sín, bóyá ó tilẹ̀ tún dàpọ̀ mó̩ ìbínú, ìjákulẹ̀, ìdálẹ́bi - àti èrò pé ikú ti dé.
Bóyá obìnrin tí wọ́n mú pé ó ń ṣe àgbèrè ìbá tilẹ̀ yàn láti kú ju ẹ̀sín tó fé̩ d'ojú kọ ló̩dọ̀ àwọn ará ìlú.

Kò dàbí ẹni pé ẹniké̩ni leè ràn àn lọ́wó̩.

Ṣùgbó̩n bí ó ti ń fi ìbẹ̀rùbojo retí kí wó̩n máa sọ òun lókò, òkò kankan kò wá. Ó dá a lójú pé àwọn olórí ẹ̀sìn ṣetàn láti sọ òun l'ókò pa.

“...ẹ jé̩ kí ẹnikẹ́ni tí kò bá d'é̩ṣẹ̀ rí kí ó ju òkò àkó̩kọ́!" (ẹsẹ 7) Jésu ti pe àwọn t'ó fé̩ fún obìnrin yìí ní ìdájó̩ ẹ̀ṣè̩ rẹ̀ n'íjà, ìpèníjà náà sì pè fún àròjinlẹ̀ - fún gbogbo ẹlẹ́ṣẹ̀.

Bí ó tilẹ̀ jé̩ pé ara ń yá àwọn èrò láti pa obìnrin yìí, Jésù kò tíì ta á dànù bí ẹ̀ṣẹ̀ẹ rẹ̀ ṣe wúwo tó. Dípò bẹ́ẹ̀, Jésù fé̩ fún un ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tun. "Máa lọ, kí o sì má d'é̩ṣẹ̀ mó̩." (e̩sẹ 11)

N jé̩ o ti rò nígbà kankan rí pé ayé ti sú ọ tàbí pé ọ̀rọ̀ rẹ ti sú ayé? Lé̩hìn gbogbo àṣìṣe, ìgbésẹ̀ òpè tó lùmọ́ è̩ṣè̩ tó fẹ́rẹ̀ gba ọjọ́ ọ̀la rẹ tàbí è̩mí rẹ, Ọlọ́run kò tíì y'o̩wó̩ ló̩rò̩ rẹ. Rárá o, dípò bẹ́ẹ̀ Ó fẹ́ fún ọ ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tun ni.

Ọlọ́run rí ọ Ó sì mọ ọkàn rẹ. Ó fẹ́ràn rẹ tó bé̩ẹ̀ gẹ́. Tọ Jésù wá bí o ṣe wà yí. Oore ọ̀fé̩ Rẹ̀ ni ọwó̩ gbọọrọ t'Ó nà sí ọ kí o lè bẹ̀rẹ̀ ayé ló̩nà ọ̀tun - pẹ̀lú Rẹ̀ wá ni, báyìí.


Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 3Ọjọ́ 5

Nípa Ìpèsè yìí

Begin Again

Ọdún Tuntun. Ọjọ́ Tuntun. Ọlọ́run ṣ'ẹ̀dá gbogbo ìsípòpadà yìí láti rán wá l'étí pé Òun ni Ọlọ́run Ìbẹ̀rẹ̀ Ohun Tuntun. Bí ó bá jẹ́ pé Ọlọ́run fí ọ̀rọ̀ dá ayé, Ó lè s'ọ̀rọ̀ sí òkùnkùn ayé rẹ, kí Ó ṣ'ẹ̀dá ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tun fún ọ. Ṣé o kò sàì f'ẹ́ràn ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tun! Gẹ́gẹ́ bíi ìlànà ẹ̀kọ́ yìí! Máa bá wá kálọ!

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Ògbéni Boris Joaquin, Ààrẹ àti Gíwá Àgbà fún Breakthrough Leadership Management Consultancy. Òun ni olùkọ́ àgbà àti olùdánilẹ́kọ̀ọ́ tó mú yányán jùlọ nínú ẹ̀kọ́ ìdarí àti àwọn ẹ̀kọ́ ìgbáyé-gbádùn ní ìlú Philippines. Òun pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀ Michelle Joaquin, ni wọ́n jọ ṣ'ètò ìlànà ẹ̀kọ́ yìí. Fún àlàyé kíkún, jọ̀wọ́ kàn sí http://www.theprojectpurpose.com/