Bẹ̀rẹ̀ L'ọ́tunÀpẹrẹ
Ìrírí Ní Òpópónà Damásíkù
Ìyípadà ọkàn Sọ́ọ̀lù lójú òpópónà tó lọ sí Damásíkù jẹ́ ìtàn tí a ti sọ ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà pàápàá gẹ́gẹ́bí àfiwé ìyípadà ọkàn ènìyàn – ìyẹn àwọn ènìyàn tó ní ìfọwọ́tọ́ ọrẹ-ọ̀fẹ́ ti Ẹ̀mí Mímọ́ tí wọ́n sì wá bẹ̀rẹ̀ ìgbé ayé ọ̀tún. A yí ìgbésí ayé Pọ́ọ̀lù padà nígbà tí ó fi ìgbàgbọ́ rẹ̀ sínú Jésù. Má gbàgbé wípé Sọ́ọ̀lù ni à ń pe Pọ́ọ̀lù tẹ́lẹ̀. Máṣe Jẹ́kí orúkọ méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ yí rú ọ lójú.
Nínú Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì 9:1-2 ni a ti pe àwọn ọmọ lẹ́yìn Kristi ní “Ọ̀nà naa” nítorí àwọn Kristẹni ń kéde rẹ̀ wípé ìgbàgbọ́ nínú Jésù ni “ọ̀nà kan ṣoṣo” sí ìgbàlà (Ka Jòhánù 14:6). Pọ́ọ̀lù jẹ́ adarí ẹ̀sìn Júù tí kò ṣe tán láti gbà wípé ẹ̀sìn rẹ̀ kò tọ̀nà.
Sọ́ọ̀lù gbéra láti lọ sí Damásíkù pẹ̀lú ète ikú l'ọ́kàn rẹ̀ – láti lọ pọ́n àwọn tí ń tẹ̀lé “Ona náà” lójú. Ní òpópónà Damásíkù yí, Sọ́ọ̀lù ní àbápàdé pẹ̀lú ìtànná ìmọ́lẹ̀ ńlá, èyí tó mọ́lẹ̀ jù oòrùn ọ̀sánkanrí. Nígbà náà ni ó wá gbọ́ ohùn kan tó fọ̀ síi wípé: “Sọ́ọ̀lù, Sọ́ọ̀lù, èéṣe tí ìwọ fi ńṣe inúnibíni sí mi?” (Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì 9:4). Nígbà tí Sọ́ọ̀lù bèrè ìdánimọ̀ ẹni tí ń báa sọ̀rọ̀, ohùn náà fèsì wípé, “Èmi ni Jésù, ẹni tí ìwọ ńṣe inúnibíni sí. Ní báyìí dìde kí o lọ sínú ìlú náà, a ó sì sọ ohun tí o gbọ́dọ̀ ṣe fún ọ.” (Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì 9:5-6)
Kò rọrùn fún Ananíà láti gbàgbọ́ wípé Sọ́ọ̀lù ti di àtúnbí nínú Jésù. Ní ẹsẹ̀ kọkànlá, Olúwa kọsí Ananíà wípé ẹ̀rí kan tí ó nílò ni láti mọ̀ wípé Sọ́ọ̀lù ti di àtúnbí ni láti ríi níbi tí ó ti ń gbàdúrà.
Sọ́ọ̀lù kò ríran ní àkókò yí! Ọlọ́run rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀ kí ó lè mọ bí ó ti nílò Jésù tó. Nígbà tí ìrètí ènìyàn bá ti pin, Jésù ma wá sí ìtòsí rẹ̀. Bí ó ti wà nínú Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì 9:19b-22 Sọ́ọ̀lù ní àyípadà ọkàn, èyí tó sọ ọ́ di ẹ̀dá titun.
Bí Pọ́ọ̀lù ti ṣe àlàyé ìrírí rẹ̀ nìyí — àti sí àwa tó gbàgbọ́ nínú Kristi – Ka Kọ́ríńtì Kejì 5:17. Kìíṣe gbogbo ènìyàn ló ní irúfẹ́ “ìrírí Òpópónà Damásíkù” tí Sọ́ọ̀lù ní, ṣùgbọ́n gbogbo wa ló yẹ kí á lè sọ wípé: “Ìgbésí ayé mi ti yí padà látìgbà tí mo bá Jésù Kristi pàdé.” Ǹjẹ́ o lè sọ èyí bí? Ǹjẹ́ o rántí ìgbà kan tí Ọlọ́run rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ láti lè fà ọ́ mọ́ra?
Ní àkókò ìfòyà, àbámọ̀ àti ìṣíni-níyè náà, Sọ́ọ̀lù padà ní òye wípé Jésù ni Olùgbàlà ní tòótọ́, àti wípé ó ti ṣe ìrànwọ́ fún àwọn tí a ṣe ikú pa àti àwọn aláìṣẹ̀ tí a fi sínú túbú. Sọ́ọ̀lù wá ríi wípé pẹ̀lú pẹ̀lú àwọn ǹkan tó gbàgbọ́ gẹ́gẹ́bí Farisí, ní báyìí ó mọ òtítọ́ nípa Ọlọ́run ó sì jẹ́ ojúṣe rẹ̀ láti gbọ́rọ̀ síi lẹ́nu.
Ní àkókò náà Sọ́ọ̀lù di ẹ̀dá titun, ní tòótọ́. A ti sọ ọ́ di àtúnbí. Ó sì wá sàmì sí ọjọ́ náà nípa yíyí orúkọ Hébérù rẹ̀ Sọ́ọ̀lù padà sí Pọ́ọ̀lù – láti lè bẹ̀rẹ̀ lójú ewé titun.

Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ọdún Tuntun. Ọjọ́ Tuntun. Ọlọ́run ṣ'ẹ̀dá gbogbo ìsípòpadà yìí láti rán wá l'étí pé Òun ni Ọlọ́run Ìbẹ̀rẹ̀ Ohun Tuntun. Bí ó bá jẹ́ pé Ọlọ́run fí ọ̀rọ̀ dá ayé, Ó lè s'ọ̀rọ̀ sí òkùnkùn ayé rẹ, kí Ó ṣ'ẹ̀dá ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tun fún ọ. Ṣé o kò sàì f'ẹ́ràn ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tun! Gẹ́gẹ́ bíi ìlànà ẹ̀kọ́ yìí! Máa bá wá kálọ!
More
A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Ògbéni Boris Joaquin, Ààrẹ àti Gíwá Àgbà fún Breakthrough Leadership Management Consultancy. Òun ni olùkọ́ àgbà àti olùdánilẹ́kọ̀ọ́ tó mú yányán jùlọ nínú ẹ̀kọ́ ìdarí àti àwọn ẹ̀kọ́ ìgbáyé-gbádùn ní ìlú Philippines. Òun pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀ Michelle Joaquin, ni wọ́n jọ ṣ'ètò ìlànà ẹ̀kọ́ yìí. Fún àlàyé kíkún, jọ̀wọ́ kàn sí http://www.theprojectpurpose.com/