Bẹ̀rẹ̀ L'ọ́tunÀpẹrẹ

Begin Again

Ọjọ́ 2 nínú 7

Ọlọ́run ìbẹ̀rẹ̀ tuntun
Kò mọ irúfẹ́ ènìyàn tó máa pàdé lọ́jọ́ náà àti bí ẹni náà se máa yí ayé re padà. Ó ti se ìgbéyàwó lẹ́ẹ̀marù-ún, síbẹ̀, ọkọ ẹlòmíràn ló ń bá gbé báyìí. Bóyá bí àwọn ọ̀jògbọ́n Bíbélì kan se sọ, ó ń fa omi ní ọjọ́kanrí torí pé kò sí ẹlòmíràn tó máa fa omi ní àkókò yí. Bóyá ó jẹ́ ẹni tí àwùjọ kò gbà gẹ́gẹ́ bíi ara wọn. Bóyá torí àwọn ìwà rẹ̀, ó jẹ́ ẹni tí àwùjọ ti kọ̀. Gẹ́gẹ́ bíi ará Samáríà, kò rò wípé Jésù máa bá òun sọ̀rọ̀ lọ́jọ́ náà, tàbí pé ó tilẹ̀ máa bèèrè omi lọ́wọ́ òun. Ó fẹnu ara rẹ̀ sọ bẹ́ẹ̀: “Júù ni ìwọ, obìnrin ará Samáríà ni èmi. Èése tí ìwọ fi ń bi mí fún omi?” O mọ “ààyè rẹ.” Sùgbọ́n Jésù mọ oun tó ń se, ó jẹ́ oun ayọ̀ ńlá fún un, bíi óúnjẹ sí inú tí ebí ti pa. O mọ ẹni tí obìnrin náà jẹ́, bẹ́ẹ̀, ó sì mọ oun àti ẹni tí ó nílò Bẹ́ẹ̀ni, ó bèèrè omi lọ́wọ́ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bíi ènìyàn tí ó ti rẹ̀ torí ó ti rìn nínú òòrùn. Yes, Síbẹ̀, ó fi omi ìyè lọ̀ obìnrin náà kí ó má baà pòùngbẹ mọ́. Ayé ọmọbìnrin náà fihàn bí ó se nílò kí òùngbẹ rẹ̀ di pípa, kí ọkàn rẹ̀ balẹ̀. Olùgbàlà nìyí lọ́dọ̀ rẹ̀, ẹni tó le fi ọkàn rẹ̀ balẹ̀. Ó fi akèrèǹgbè omi rẹ̀ s'ílẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ odò, akèrèǹgbè tó fi ń pa òùngbẹ rẹ̀, ó sì sáré padà sí abà láti sọ fún àwọn ará abà nípa ọkùnrin tó sọ gbogbo oun tó ti se fún-un, tó sì bèèrè ìbéèrè tí yíò jẹ́ kí gbogbo ènìyàn ríi fúnra wọn. “Sé ó le jẹ́ Olùgbàlà bí?” (ẹsẹ̀ 29) Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ará Samáríà gbàgbọ́ nínú Jésù nítorí oun tí obìnrin náà sọ. (ẹsẹ̀ 39-42). Nígbà tí Jésù fi oun tó ti se hàn-án tí ó sì fi ayé tí kò ti ní pòùngbẹ mọ́ lọ̀ ọ́. Ó yí ayé rẹ̀ padà. A dárí ẹ̀sẹ̀ jìn-ín, o sì rí oore ọ̀fẹ́, ayé rẹ̀ sì gba ọ̀tun. Ó ń yọ̀ nínú ìròyìn ayọ̀ oore ọ̀fẹ́, o sì sáré tọ gbogbo ènìyàn tó mọ̀ lọ torí ìgbé ayé tuntun tó sẹ̀sẹ̀ gbà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì rí ìyè. Ìbẹ̀rẹ̀ tuntun rẹ̀ fún àwọn míràn ní ìbẹ̀rẹ̀ tuntun tiwọn. Èyí jẹ́ oun ayọ̀ fún Krístì Ìbéèrè láti rò: 1. Èèyàn le sọ pé akèrèǹgbè omi obìnrin náà jẹ́ ìgbìyànjú ẹ̀ láti kún ọkàn rẹ̀ pẹ̀lú ìfẹ́ àwọn ọkùnrin. Sùgbọ́n ìyẹn kò kún òùngbẹ ọkàn rẹ̀. Ìwọ ńkọ́? Kí lò ń fi kún akèrèǹgbè rẹ? Báwo loun yí se kún òùngbẹ ọkàn rẹ? 2. Jésù fún ọmọbìnrin ará Samáríà yí ní oun tó le pa òùngbẹ rẹ̀ ní òtítọ́: Jésù fúnra rẹ̀. Ó mọ ẹ̀sẹ̀ rẹ̀, ó sì fun ní ìyè. Jésù ń fi ìyè náà lọ ìwọ náà. Jésù mọ̀ ọ́ ó sì mọ oun tí kò lè tán òùngbẹ rẹ̀ẹ, ó sì fi ara rẹ̀ sílẹ̀ fún ọ- omi ìyè. Sé ìwọ ó gba èbùn omi ìyè yí kí o sì ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tun ní ayé rẹ

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 1Ọjọ́ 3

Nípa Ìpèsè yìí

Begin Again

Ọdún Tuntun. Ọjọ́ Tuntun. Ọlọ́run ṣ'ẹ̀dá gbogbo ìsípòpadà yìí láti rán wá l'étí pé Òun ni Ọlọ́run Ìbẹ̀rẹ̀ Ohun Tuntun. Bí ó bá jẹ́ pé Ọlọ́run fí ọ̀rọ̀ dá ayé, Ó lè s'ọ̀rọ̀ sí òkùnkùn ayé rẹ, kí Ó ṣ'ẹ̀dá ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tun fún ọ. Ṣé o kò sàì f'ẹ́ràn ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tun! Gẹ́gẹ́ bíi ìlànà ẹ̀kọ́ yìí! Máa bá wá kálọ!

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Ògbéni Boris Joaquin, Ààrẹ àti Gíwá Àgbà fún Breakthrough Leadership Management Consultancy. Òun ni olùkọ́ àgbà àti olùdánilẹ́kọ̀ọ́ tó mú yányán jùlọ nínú ẹ̀kọ́ ìdarí àti àwọn ẹ̀kọ́ ìgbáyé-gbádùn ní ìlú Philippines. Òun pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀ Michelle Joaquin, ni wọ́n jọ ṣ'ètò ìlànà ẹ̀kọ́ yìí. Fún àlàyé kíkún, jọ̀wọ́ kàn sí http://www.theprojectpurpose.com/