JESU si lọ si ori òke Olifi.
O si tún pada wá si tẹmpili ni kutukutu owurọ̀, gbogbo enia si wá sọdọ rẹ̀; o si joko, o nkọ́ wọn.
Awọn akọwe ati awọn Farisi si mu obinrin kan wá sọdọ rẹ̀, ti a mu ninu panṣaga; nigbati nwọn si mu u duro larin,
Nwọn wi fun u pe, Olukọni, a mu obinrin yi ninu panṣaga, ninu ṣiṣe e pãpã.
Njẹ ninu ofin, Mose paṣẹ fun wa lati sọ iru awọn bẹ̃ li okuta pa: ṣugbọn iwọ ha ti wi?
Eyini nwọn wi, nwọn ndán a wò, ki nwọn ba le ri ohun lati fi i sùn. Ṣugbọn Jesu bẹrẹ silẹ, o si nfi ika rẹ̀ kọwe ni ilẹ.
Ṣugbọn nigbati nwọn mbi i lẽre sibẹsibẹ, o gbé ara rẹ̀ soke, o si wi fun wọn pe, Ẹniti o ba ṣe ailẹṣẹ ninu nyin, jẹ ki o kọ́ sọ okuta lù u.
O si tún bẹ̀rẹ̀ silẹ, o nkọwe ni ilẹ.
Nigbati nwọn gbọ eyi, nwọn si jade lọ lọkọ̃kan, bẹrẹ lati ọdọ awọn àgba titi de awọn ti o kẹhin; a si fi Jesu nikan silẹ, ati obinrin na lãrin, nibiti o ti wà.
Jesu si gbé ara rẹ̀ soke, o si wi fun u pe, Obinrin yi, awọn dà? Kò si ẹnikan ti o da ọ lẹbi?
O wipe, Kò si ẹnikan, Oluwa. Jesu si wi fun u pe, Bẹ̃li emi na kò da ọ lẹbi: mã lọ, lati igbayi lọ má dẹṣẹ̀ mọ́.