Àwọn Ádùrá Tí Ó L'éwuÀpẹrẹ
Kí Ìfẹ́ Rẹ Wá Sí Ìmúṣẹ
Dípò àwọn ádùrá gígùn àti t'aláriwo, àwọn ádùrá t'ó n kan Ọlọ́run jẹ́ àwọn ádùrá tí ó rọrùn, ádùrá òótọ́, ádùrá tọkàntọkàn. Ṣùgbọ́n wípé ó rọrùn kìí ṣe ìkannáà bíi àìléwu. Ìdí níyì tí mo ṣe kọ èyí. Àṣìṣe tí ó tóbi jùlọ tí mo ṣe ní ayé ádùrá mi, ìdí tí àwọn ádùrá mi fi jẹ́ aláìlágbára, nítorí pé mo gb'àdúrà àìléwu. Mo wà ní agbègbè ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú Ọlọ́run. N kò gbóná, n kò tutù. Ádùrá mi gbó. Ṣùgbọ́n àwọn ádùrá tí kò gbóná kò fà wá súnmọ́ Ọlọ́run, wọn kò sì ṣe ìrànlọ́wọ́ fún wa láti fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn sí ayé yìí.
Ádùrá jẹ́ ewu. Ìmọ̀ràn yìí nípa ádùrá kọ́kọ́ yé mi nígbà tí mo kà nípa bí Jésù ṣe s'ọ̀rọ̀ pẹ̀lú Baba rẹ̀ nínú ọgbà Gẹtisémánì, ní ìgbà díẹ̀ ṣáájú kí ó tó fi ẹ̀mí rẹ̀ lé lẹ̀ l'órí àgbélèbú. Mímọ ohun tí ó wà n'íwájú rẹ̀, Jésù bèèrè l'ọ́wọ́ Ọlọ́run bóyá ọ̀nà míràn wà. Lẹ́hìn naa, Jésù, tí kìí ṣe ọmọ-ẹ̀hìn kan tàbí ènìyàn kan lásán nínú Bíbélì, ṣùgbọ́n J-E-S-U, Ọmọ Ọlọ́run, gb'àdúrà ìpalára àti ewu ti ìrẹ̀lẹ̀: “Ṣugbọn ìfẹ́ tèmi kọ́, ìfẹ́ tìrẹ ni kí ó ṣẹ.” (Luku 22:42).
Jésù ò béèrè l'ọ́wọ́ wa ńkan tí òun kò ní ṣe fúnra rẹ̀. Ó pè wá sí ìgbésí ayé ìgbàgbọ́, kìí ṣe ìgbésí ayé ìtùnú. Dípò wípé kí a wá sí ọ̀dọ rẹ̀ fún ìgbésí ayé tí ó ní ààbò, ìrọ̀rùn àti èyí tí kò ní wàhálà, Ọmọ Ọlọ́run pè wá níjà láti ní ewu ìfẹ́ àwọn ẹlòmíràn ju ara wa lọ. Dípò ṣíṣe àwọn ìfẹ́ wa l'ọ́joojúmọ́, ó pè wá láti sẹ́ wọn fún ohun ayérayé. Dípò gbígbé bí a se fẹ́, ó sọ fún wa láti gbé àwọn àgbélèbú wa l'ọ́joojúmọ́, kí a sì tẹ̀lé apẹyẹrẹ rẹ̀.
Mo ṣ'àníyàn pé fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, ádùrá dàbíi ríra tikẹti lotiri kan, ayé sí ìgbésí ayé ní ilẹ̀-ayé yìí tí kò ní ìṣòro, wàhálà tàbí ìrora. Fún àwọn ẹlòmíràn, ádùrá jẹ́ iṣẹ́ iṣeun-ọkan lásán, bíi kíka àwọn orin àyànfẹ́ tàbí orin ọmọdé tí o fẹ́ràn láti ìgbà èwe. Síbẹsíbẹ, àwọn míràn gb'àdúrà nìkan nítorí èrí ọkàn á jẹ́ wọn tí wọn kò bá ṣe é.
Ṣùgbọ́n kò sí ọ̀kan nínú àwọn ádùrá wọ̀nyí tí ó ṣe àfihàn ìgbésí ayé tí Jésù wá láti fún wa.
Dípò, ó pè wá láti fi ohun gbogbo s'ílẹ̀ láti tẹ̀lé e.
Jésù kò kàn pe àwọn ẹlòmíràn níjà láti fi àwọn ìfẹ́ tiwọn s'ílẹ̀. Òun pàápàá gbé ìgbésí ayé ewu. Ó fi ọwọ́ kan àwọn adẹ́tẹ̀. Ó fi ore,-ọ̀fẹ́ hàn sí àwọn panṣaga. Bẹ́ẹ̀ sì ni, ó dúró ní ìgboyà ní ojú ewu. Lẹ́hìn náà ni ó sọ fún wa pé a lè ṣe ohun tí ó ṣe - àti jù bẹ́ẹ̀ lo.
Ìdí níyì tí a kò fi lè dá dúró l'óríi wípé kí Ọlọ́run bùkún oúnjẹ wa tàbí “wà pẹ̀lú wa l'ónìí."
A sọ fún wa nínú Bíbélì pé a lè “fi ìgboyà súnmọ́ ìtẹ́ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun wa” (Heb. 4: 16a BM). A kò ní láti súnmọ́ ní ìtìjú tàbí ìlara ìbànújẹ́ - a lè wa s'íwájú rẹ̀ pẹ̀lú ìdánilójú àti ìgboyà. Nígbà tí a bá gb'àdúrà ní ọ̀nà yìí, nígbà náà ni a yóò "rí àánú gbà, ati nípa oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, kí á lè rí ìrànlọ́wọ́ ní àkókò tí ó wọ̀” (Heb. 4: 16b BM).
Àwọn àdùrá rẹ̀ ṣe pàtàkì.
Bí o ṣe gb'àdúrà ṣe pàtàkì.
Ohun tí o gbà ní ádùrá ṣe pàtàkì.
Ádùrá. Rẹ̀. Kan. Ọlọ́run.
Nípa Ìpèsè yìí
Ṣé lílo ìgbàgbọ́ òní jẹ̀nlẹ́ńkẹ́ ti sú ọ? Ǹjẹ́ o tilẹ̀ ṣetán láti dojúkọ àwọn ìbẹ̀rù rẹ, láti fún ìgbàgbọ́ rẹ lókun, àti láti tú agbára rẹ sílẹ̀? Ètò Bíbélì ọlọ́jọ́ méje yìí tí a mú jáde láti inú ìwe Alufa ilé ìjọ́siǹ Life.Church Craig Groeschel, Àwọn Àdúrà Tí Ó Léwu, pè ọ níjà láti gbàdúrà tó léwu—nítorí títẹ̀lé Jésù kò jámọ́ ìrìn-àjò aláìléwu.
More