Heb 4:14-16

Heb 4:14-16 YBCV

Njẹ bi a ti ni Olori Alufa nla kan, ti o ti la awọn ọ̀run kọja lọ, Jesu Ọmọ Ọlọrun, ẹ jẹ ki a di ijẹwọ wa mu ṣinṣin. Nitori a kò ni olori alufa ti kò le ṣai ba ni kẹdun ninu ailera wa, ẹniti a ti danwo li ọna gbogbo gẹgẹ bi awa, ṣugbọn lailẹ̀ṣẹ. Nitorina ẹ jẹ ki a wá si ibi itẹ ore-ọfẹ pẹlu igboiya, ki a le ri ãnu gbà, ki a si ri ore-ọfẹ lati mã rànnilọwọ ni akoko ti o wọ̀.

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Heb 4:14-16