Heb 4

4
1NITORINA, ẹ jẹ ki a bẹ̀ru, bi a ti fi ileri ati wọ̀ inu isimi rẹ̀ silẹ fun wa, ki ẹnikẹni ninu nyin ki o má bã dabi ẹnipe o ti kùna rẹ̀.
2Nitoripe a ti wasu ihinrere fun wa gẹgẹ bi fun awọn na, ṣugbọn ọ̀rọ ti nwọn gbọ́ kò ṣe wọn ni ire, nitoriti kò dàpọ mọ́ igbagbọ́ ninu awọn ti o gbọ́ ọ.
3Nitoripe awa ti o ti gbagbọ́ wọ̀ inu isimi gẹgẹ bi o ti wi, Bi mo ti bura ninu ibinu mi, nwọn ki yio wọ̀ inu isimi mi: bi o tilẹ ti ṣe pe a ti pari iṣẹ wọnni lati ipilẹ aiye.
4Nitori o ti sọ nibikan niti ọjọ keje bayi pe, Ọlọrun si simi ni ijọ keje kuro ninu iṣẹ rẹ̀ gbogbo.
5Ati nihinyi ẹ̀wẹ pe, Nwọn ki yio wọ̀ inu isimi mi.
6Nitorina bi o ti jẹ pe, o kù ki awọn kan wọ̀ inu rẹ̀, ati awọn ti a ti wasu ihinrere nã fun niṣãju kò wọ inu rẹ̀ nitori aigbọran:
7Ẹ̀wẹ, o yan ọjọ kan, o wi ninu Iwe Dafidi pe, Loni, lẹhin igba pipẹ bẹ̃; bi a ti wi niṣãju, Loni bi ẹnyin ba gbọ́ ohùn rẹ̀, ẹ máṣe sé ọkàn nyin le.
8Nitori ibaṣepe Joṣua ti fun wọn ni isimi, on kì ba ti sọrọ nipa ọjọ miran lẹhinna.
9Nitorina isimi kan kù fun awọn enia Ọlọrun.
10Nitoripe ẹniti o ba bọ́ sinu isimi rẹ̀, on pẹlu simi kuro ninu iṣẹ tirẹ̀, gẹgẹ bi Ọlọrun ti simi kuro ni tirẹ̀.
11Nitorina ẹ jẹ ki a mura giri lati wọ̀ inu isimi na, ki ẹnikẹni ki o má ba ṣubu nipa apẹrẹ aigbagbọ́ kanna.
12Nitori ọ̀rọ Ọlọrun yè, o si li agbara, o si mú jù idàkídà oloju meji lọ, o si ngúnni ani tìti de pipín ọkàn ati ẹmí niya, ati oríke ati ọrá inu egungun, on si ni olumọ̀ erò inu ati ète ọkàn.
13Kò si si ẹda kan ti kò farahan niwaju rẹ̀, ṣugbọn ohun gbogbo ni o wà nihoho ti a si ṣipaya fun oju rẹ̀ ẹniti awa ni iba lo.
Jesu Olórí Alufaa Ńlá
14Njẹ bi a ti ni Olori Alufa nla kan, ti o ti la awọn ọ̀run kọja lọ, Jesu Ọmọ Ọlọrun, ẹ jẹ ki a di ijẹwọ wa mu ṣinṣin.
15Nitori a kò ni olori alufa ti kò le ṣai ba ni kẹdun ninu ailera wa, ẹniti a ti danwo li ọna gbogbo gẹgẹ bi awa, ṣugbọn lailẹ̀ṣẹ.
16Nitorina ẹ jẹ ki a wá si ibi itẹ ore-ọfẹ pẹlu igboiya, ki a le ri ãnu gbà, ki a si ri ore-ọfẹ lati mã rànnilọwọ ni akoko ti o wọ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Heb 4: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa