Àwọn Ádùrá Tí Ó L'éwuÀpẹrẹ

Dangerous Prayers

Ọjọ́ 1 nínú 7

Ìdí tí Àwọn Ádùrá Rẹ Fi Nílò Láti Méwu Dání 

Bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn tí ńṣe, mo tiraka láti gb'àdúrà n'ígbà gbogbo àti ní ọ̀nà tí ó múná dóko fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Pàápàá pẹ̀lú àwọn èrò t'ó dára, ọkàn mi á fà kúrò l'ọ́pọ̀ ìgbà tàbí kí ó sú mi n'ígbà tí mo bá n gb'àdúrà. N'ígbà tí mo jẹ́ ọ̀dọ́ olùṣọ́ àgùntàn, ọ̀rẹ́ mí kan ràn mí l'ọ́wọ́ láti ní ìdánilójú pé ó tó àkókò fún ìyípadà. Fún ìgbà pípẹ́, mo ti farada àwọn ádùrá tí kò ní ìgbàgbọ́ nínú, ṣùgbọ́n mo mọ̀ pé Ọlọ́run fẹ́ kí n tẹpá mọ́ṣẹ́ síi, àti wípé èmi gan fẹ́ mọ Ọ́ si, ní tímọ́tímọ́.

“Báwo ni, Craig, ǹjẹ́ o tilẹ̀ gbàgbọ́ wípé Ọlọ́run ṣì máa ńṣe iṣẹ́ ìyanu?”

Mo fèsì wípé “Bẹ́ẹ̀ni.”

“Ó dára bá yẹn—nítorí àwọn ádùrá rẹ ti tutù jù"

Mo gbìyànjú láti dà á s'áwàdà, àmọ́ àwàdà ọ̀rẹ́ mí yìí wọ̀mí ní akínyemí ara—pàápàá jùlọ nítorí òtítọ́ ni ǹkan tó sọ.

Láì lè fèsì, n kò ṣòpò gbìyànjú láti ṣe àwáwí bí mo ti ńṣe àgbéyẹ̀wò òtítọ́ inú àkíyèsí rẹ̀. N kò lè kọ̀ láti gbà wípé àṣírí tí mo ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ ṣùgbọ́n tí mo kọ̀ láti múlò ni ọ̀rẹ́ mi sọ: àwọn ádùrá mi jẹ́ èyí tó mú ìrẹ̀wẹ̀sì dání.

Ètò yìí wà fún ẹnikẹ́ni tí ó bá ní ìrora nínú ádùrá, gbígbàdúrà àtúnwí, èyí tí a mọ̀ tẹ́lẹ̀, àti àwọn ádùrá àìléwu.

À n sin Ọlọ́run kan tí ó lè ṣe ju ohun tí a lè béèrè tàbí rò lọ. Nítorí náà, ó tó àkókò láti dá'wó iṣẹ́ aláìléwu dúró. A kò ṣ'ẹ̀dá wa fún ìgbésí ayé ìtùnú. A jẹ́ ènìyàn onítara àti alágbára, tí a ró l'ágbára láti yí àgbáyé padà ní àwọn ọ̀nà ìpìlẹ̀! Mo gbàgbọ́ pé ètò yìí yíò gbà ọ́ níyànjú láti já àwọn ààlà, láti gb'àdúrà ewu àti láti gbé ní ìgboyà.

Bí mo ṣe n ka Bíbélì síi, ẹnú yà mí sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ádùrá tí àwọn ènìyàn Ọlọ́run sọ. Kìí ṣe àwọn ádùrá nípa àwọn ohun tí ó jẹ́ ti ara nìkan — láti bí ọmọ, fún àpẹẹrẹ (1 Sam. 1:27) - ṣùgbọ́n àwọn ádùrá wọn náà wúlò, fún óúnjẹ àti ìpèsè (Mat. 6:11) àti láti sa àsálà l'ọ́wọ àwọn ọ̀tá wọn (Orin Dáfídì 59: 1-2). N'ígbà míràn, ó dàbí wípé wọ́n rọra s'ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ sí Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ kan. Ìgbà míràn, wọ́n p'ariwo sí I nínú ìrora àti ìbànújẹ́.

Àwọn àdùrá wọn jẹ́ òtítọ́. Àìnírètí. Oníná. Òtítọ́. Níbẹ̀ ni mo wà tí mo tí n gb'àdúrà pé kí Ọlọ́run pa mí mọ́ kí ó sì bùkún bugan àti bọ̀ọ̀li mi.

Òtítọ́ ni ọ̀rẹ́ mí sọ.

Àwọn àdùrá mi jẹ́ aláìlágbára

Bóyá o lè ní ìbátan. Kìí ṣe pé o kò gbàgbọ́ nínú ádùrá. O gbàgbọ́. Ṣùgbọ́n o ti wà nínú ipò àìyípadà kan. Ò n gb'àdúrà nípa àwọn ìgbìyànjú àti ìbéèrè kannáà. Ní ọ̀nà kannáà. Ní àkókò kannáà. Ìyẹn tí o bá tilẹ̀ gb'ìyànjú láti gbàdúrà rárá. O lè mọ̀ pé ó yẹ kí o gb'àdúrà síi. Àti pẹ̀lú ìtara díẹ̀ síi. Ìgbàgbọ́ díẹ̀ síi. O fẹ́ bá Ọlọ́run s'ọ̀rọ̀, o sí fẹ́ gbọ́ tirẹ̀, láti pín ọ̀rọ̀ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Rẹ̀ bíi ìwọ yóò ṣe ṣe pẹ̀lú ìyàwó rẹ tàbí ọ̀rẹ́ t'ó dára jùlọ. O fẹ́ e gaan ṣùgbọ́n kò dá ọ l'ójú bí o ṣe lè ṣeé. Nítorí náà, àwọn ádùrá rẹ wà l'áìléwu.

Alapin. Ṣigọgọ. Aláìdùn.

Ọ̀rọ̀ ọ̀rẹ́ mí dá mi l'ójú pé ó tó àkókò fún ìyípadà nínú ayé ádùrá mi. Fún ìgbà pípẹ́, mo ti farada àwọn ádùrá àìlaadùn, àìnígbàgbọ́, àti jùlọ, ádùrá òfo. Mo mọ̀ wípé Ọlọ́run fẹ́ síi fún mi, àti pé mo fẹ́ mọ̀-On síi ní pẹ́kípẹ́kí, pẹ̀lú ìsiyèméjì mi nípa ohun tí yóò bèèrè l'ọ́wọ́ mi.

N'ígbà tí a bá n wá láti bá Ọlọ́run s'ọ̀rọ̀ nínú ádùrá tímọ́tímọ́, olótitọ́ àti aláìlágbára, kò ní pa wá mọ́ nínú ilé ààbò ẹ̀mí. Dípò bẹ́ẹ̀, yíò ju èrò ohun-ti-o-wà-nínú-è-fún-mi wa, yíò sì pè wá láti gbẹ́kẹ̀lé nígbà tí a kò mọ ohun tí yóò ṣe nígbà míràn. Àwọn ọjọ́ míràn, a máa gbàgbọ́ wípé ẹni ìbùkún ni wá. Àwọn ọjọ́ míràn, a d'ojú kọ àwọn italaya, àtakò àti inúnibíni. Ṣùgbọ́n gbogbo àkókò ádùrá tí ó l'éwu yóò kún fún wíwà láàyè Rẹ̀.

Ṣé o ṣe tán fún díẹ̀ síi? Ṣé ó sú ọ láti gbé ìgbé aiyé àìléwu? Ṣé o ṣe tán láti gba ádùrá ìgboyà, tí ó kún fún ìgbàgbọ́, ìbọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run, ìyípadà ayé, àti ìyípadà àgbáyé?

Ti o ba ṣetan, Eto Bibeli yii je tiẹ.

Ṣugbọn gbọ o. Àwọn idiwo yóò wa. Nigbati o ba bẹrẹ síí gba àwọn adura bii “wa mi, fọ mi, ran mi,” o le ni iriri awọn afonifoji. Awọn ikolu. Awọn idanwo. Irora. Iṣoro. Irẹwẹsi. Paapaa ibanujẹ. Ṣugbọn ayọ igbagbọ yoo tun wa, iwarìri awọn iṣẹ iyanu, itusilẹ ti ijowoaraeni, ati idunnu ti itẹlọrun Ọlọrun.

O to akoko lati da gbigbadura lailewu duro.

O to akoko lati bẹrẹ sii sọrọ, ọrọ gidi — ati gbigbọ gangan- si Ọlọrun.

O to akoko fun awọn adura ti o lewu.

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

Dangerous Prayers

Ṣé lílo ìgbàgbọ́ òní jẹ̀nlẹ́ńkẹ́ ti sú ọ? Ǹjẹ́ o tilẹ̀ ṣetán láti dojúkọ àwọn ìbẹ̀rù rẹ, láti fún ìgbàgbọ́ rẹ lókun, àti láti tú agbára rẹ sílẹ̀? Ètò Bíbélì ọlọ́jọ́ méje yìí tí a mú jáde láti inú ìwe Alufa ilé ìjọ́siǹ Life.Church Craig Groeschel, Àwọn Àdúrà Tí Ó Léwu, pè ọ níjà láti gbàdúrà tó léwu—nítorí títẹ̀lé Jésù kò jámọ́ ìrìn-àjò aláìléwu.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Àlùfáà Craig Groeschel àti Life.Church fún ìpèsè ètò yìí. Fun àlàyé síwájú sí, jọ̀wọ́ lọ sí: https://www.craiggroeschel.com/