Àwọn Ádùrá Tí Ó L'éwuÀpẹrẹ

Fi Ìbẹ̀rù Mi Hàn
Kíni ó n mú ọ ṣ'àníyàn? Tí kò fi ọ́ l'ọ́kàn balẹ̀? Tí kò mú ọ f'ara balẹ̀? Tí n bá ọ́ l'ẹ́rù?
Mi ò s'ọ̀rọ̀ nípa àwọn ìbẹ̀rù déédé bíi ìbẹ̀rù ejò, alántakùn, tàbí ìbẹ̀rù irúfẹ́ èyí. Mò n so nípa ohun t'ó n gba orun l'ójú rẹ̀ ní alẹ́, àwọn nkan tí ó n pò ríru nínu ọkàn rẹ, tó kọ̀ láti dákẹ́. Àwọn nkan bíi iṣẹ́ rẹ tí ó ti bọ́. Àì rí ìgbéyàwó ṣe. Tàbí wíwà nínú ìgbéyàwó t'ó burú. Ìlera t'ó kùnà. Àì rí owó ná.
A kò mọ irú ìbẹ̀rù tí n da ọkàn Dafidi rú gangan, ṣùgbọ́n ó hàn gbangba pé ó ní wàhálà nípa ààbò rẹ̀ àti pàápàá ọjọ́ iwájú rẹ̀. Nítorí lẹ́hìn tí ó bèèrè l'ọ́wọ́ Ọlọ́run láti wá ọkàn rẹ̀, Dafidi gb'àdúrà, “mọ èrò ọkàn mi.” (Orin Dafidi 139: 23). Ó fẹ́ pín àwọn ìbẹ̀rù rẹ̀ tí ó ga jùlọ pẹ̀lú Ọlọ́run. Láti d'ojúkọ wọ́n kí ó sì fún wọn ní orúkọ. Láti gbàgbọ́ pé Ọlọ́run tóbi ju ìbẹ̀rù èyíkéyìí tí Dafidi lè ní.
Ṣé o ṣe tàn láti gba irú ádùrá bi èyí? “Olúwa, fi ohun tí n dá ọkàn mi dúró hàn. Fi ohun tí mo bẹ̀rù jùlọ hàn mí. Tẹ̀síwájú, ṣe ìrànlọ́wọ́ fún mi láti k'ojú ohun tí n s'ẹ̀rù bà mí.”
Ohun tí a bẹ̀rù ṣe kókó.
Àwọn ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, mo ní ìfihàn nípa kókó yìí tí ó kàn mí lára púpọ̀. Ọlọ́run fi hàn mí pé ohun tí mo bẹ̀rù jùlọ hàn ibi tí nkò tíì gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run jùlọ. Lẹ́hìn ibí ọmọbìnrin wa kẹta, Anna, Amy bẹ̀rẹ̀ síí ní àwọn ìnira ara. Ní ìbẹ̀rẹ̀, a rò pé rírẹ̀ ara nìkan ni, ṣùgbọ́n nígbà tí ìdajì ara rẹ̀ kọ̀, a gbàgbọ́ pé ó burú ju bẹ́ẹ̀ lọ. Dókítà lẹ́hìn dókítà ò lè pèsè ìdáhùn. Bí àwọn ààmì àìsàn rẹ̀ ti n burú síi, ìgbẹ́kẹ̀lé mi nínú Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ síí wá'lẹ̀.
Ìbẹ̀rù yìí yọrí sí àwọn míràn, bẹ́ẹ̀ sì ni, ní alẹ́, àwọn ìrònú mi di ohun tí nkò lè kápá. Tí nkan tí n ṣe Amy bá jẹ́ àìsàn nlá nkọ́? Tí mo bá pàdánù rẹ̀ nkọ́? Nkò ní lè dá tọ́ àwọn ọmọ wa. Nkò ní lè tẹ̀síwájú láti máa ṣ'àkóso ìjọ wa. Nkò ní fẹ́ gbé ayé mọ́.Nígbà náà ni ó yé mi. Àwọn ohun tí n gba orun l'ójú mi ní alẹ́ ni àwọn ohun tí nkò gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run láti se. Mo dì wọ́n mú, mò n rò wọ́n, mò n gbìyànjú láti wa ọ̀nà láti ṣ'àkóso lórí wọn, láti yanjú gbogbo àwọn ìṣòro mi, láti gbèrò fún gbogbo ohun àìròtẹ́lẹ̀. A dúpẹ́, nípasẹ̀ ore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, ìlera Amy bèrè síí padà s'ípò títí àgbàrá rẹ̀ di kíkún, ṣùgbọ́n àwọn ìdojújọ rẹ̀ ṣ'àfihàn ọkan nínu àwọn àìpé mí t'ó burú jùlọ. Ẹ̀rù ti b'orí mi.
Ìwọ nkọ́? Kíni àwọn àgbègbè tí o dì mú, bí ó ti lè jẹ́ wípé wọ́n n bà ọ́ l'ẹ́rù? Àwọn ìbẹ̀rù wo ni ò n fi pamó fún Ọlọ́run?
Ronú nípa rẹ̀. Tí o bá n bẹ̀rù nípa ọjọ́ iwájú ìgbéyàwó rẹ, èyí jẹ́ ìtọ́kasí pé o kò gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run pátápátá pẹ̀lú ìgbéyàwó rẹ. Tí àìbalẹ̀ ọkàn nípa bí ìwọ yóò ṣe san àwọn owó rẹ bá mú ọ, èyí fi hàn pé o lè má gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run tó láti jẹ́ olùpèsè rẹ. Tí àìbalẹ̀ ọkàn nípa ààbò àwọn ọmọ rẹ bá mú ọ, njẹ́ èyí n so pé ìwọ kò gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run láti pa wọ́n mọ́ l'áìléwu bí?
Bí Ọlọ́run ṣe n fi àwọn ìbẹ̀rù rẹ hàn, ni yóò tún kọ ìgbàgbọ́ rẹ. O nílò rẹ. O nílò wíwà rẹ. O nílò àgbàrá rẹ. O nílò Ẹ̀mí láti darí ọ. O nílò Ọ̀rọ̀ rẹ̀ láti fún ọ l'ókun.
Ohun tí o bẹ̀rù jùlọ n fi hàn ọ́ ibi tí o nílò láti d'àgbà pẹ̀lú Ọlọ́run. Kíni ò n bẹ̀rù? Kíni àwọn èrò àníyàn rẹ?
Kíni Ọlọ́run n fi hàn ọ́?
Níbo ni o ti nílò láti d'àgbà nínú ìgbàgbọ́?
Gbẹ́kẹ̀ rẹ lé e.
Nípa Ìpèsè yìí

Ṣé lílo ìgbàgbọ́ òní jẹ̀nlẹ́ńkẹ́ ti sú ọ? Ǹjẹ́ o tilẹ̀ ṣetán láti dojúkọ àwọn ìbẹ̀rù rẹ, láti fún ìgbàgbọ́ rẹ lókun, àti láti tú agbára rẹ sílẹ̀? Ètò Bíbélì ọlọ́jọ́ méje yìí tí a mú jáde láti inú ìwe Alufa ilé ìjọ́siǹ Life.Church Craig Groeschel, Àwọn Àdúrà Tí Ó Léwu, pè ọ níjà láti gbàdúrà tó léwu—nítorí títẹ̀lé Jésù kò jámọ́ ìrìn-àjò aláìléwu.
More