Àwọn Ádùrá Tí Ó L'éwuÀpẹrẹ

Dangerous Prayers

Ọjọ́ 7 nínú 7

Dà Mí Láàmú

Ohun tí a gb'àdúrà nípa ṣe pàtàkì. Ṣùgbọ́n kò ṣe pàtàkì nìkan, ó tún n ṣ'àfihàn àwọn ohun òmíràn. 

Àkóónú àwọn ádùrá wa sọ fún wa nípa àwa àti ìbátan wa pẹ̀lú Ọlọ́run ju ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn l'érò lọ. Ohun tí a gb'àdúrà lé lórí ṣe àfihàn àwọn ohun tí a gbàgbọ́ nípa Ọlọ́run. Tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ádùrá wa bá wà fún “ara wa” tàbí “ohun tí ó ṣe pàtàkì sí wa,” nígbà náà ni àkóónú àwọn ádùrá wa n sọ pé a gbàgbọ́ pé Ọlọ́run wà fún wa nìkan.

Nítorí náà, gba àkókò díẹ̀ láti ṣe àyẹ̀wò ádùrá kan. Ronú nípa ohun gbogbo tí o ti gb'adura fún láìpẹ́- kìí ṣe gbogbo ìgbésí ayé rẹ, fún àwọn ọjọ́ méje tí ó ti kọjá yìí nìkan ni. Ronú nípa ṣíṣe tàbí títẹ àkọsílẹ̀ kan lórí ẹ̀rọ àgbéká rẹ kí o sì kọ gbogbo àwọn ohun oríṣiríṣi tí o bẹ̀bẹ̀ l'ọ́wọ́ Ọlọ́run láti ṣe ní ọ̀sẹ̀ tí ó kọjá yìí. Ronú síi fún ìgbà díẹ. Njẹ́ o rántí? Àwọn ohun wo ni o gb'àdúrà nípa? Kíni o bèèrè wípé kí Ọlọ́run ṣe fún ọ? 

Dáhùn ní òtítọ́ nísinsìnyí. Tí Ọlọ́run bá sọ bẹ́ẹ̀ni sí gbogbo ádùrá tí o ti gbà ní àwọn ọjọ́ méje tí o ti kọjá wọ̀nyí, báwo ni àgbáyé ìbá ṣe yàtọ̀? 

Tí àwọn ádùrá rẹ bá jẹ́ déédé, àwọn tí ó ní ààbò, bóyá o yóò ti ní ọjọ́ tí ó dára nígbà náà, o yóò dé l'áìléwu, tàbí gbádùn Ìbùkún oúnjẹ àti ohun mímu aládùn oríṣiríṣi.

Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, tí mo bá ti ṣ'àyẹ̀wò àwọn ádùrá mi, àwọn àbájáde rẹ̀ ìbá ti burú. Tí Ọlọ́run bá ti ṣe ohun gbogbo ní àkókò ọ̀sẹ̀ kan tí mo béèrè l'ọ́wọ́ rẹ̀ láti ṣe, àgbáyé kò bá tíì yàtọ̀ púpọ rárá. Ní òtítọ́, ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn ọ̀sẹ̀, n kò ní gb'àdúrà fún ohunkóhun. Àwọn ọ̀sẹ̀ míràn, mo lè gb'àdúrà, ṣùgbọ́n àwọn ádùrá náà jẹ́ nípa mi nìkan, èyí kò yí ohun púpọ padà nínú ètò nlá nkan.

Àwọn àdùrá mi jẹ́ àìléwu púpọ.

Mo r'áyè sí Ẹlẹ́dàá àti Atáyéro àgbáyé. Èmi Ni. Alpha àti Omega. Ìbẹ̀rẹ̀ àti Òpin. Ọlọ́run tí ó ní gbogbo agbára, tí ó wà ní ìgbàgbogbo, tí ó mọ ohun gbogbo, tí ó lè ràn iná láti ọ̀run wá, tí ó pa ẹnu àwọn kìnìún tí ebi npa dúró, tàbí kí ó mú kí ìjì líle ríru dákẹ́. Ohun gbogbo tí mo sì béèrè l'ọ́wọ́ rẹ̀ láti ṣe ni kí ó pa mí mọ́, kí ó sì ràn mí l'ọ́wọ́ láti ní ọjọ́ tí ó dára.

Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, n kò fẹ́ kí a dà mí láàmú. Ṣùgbọ́n lẹ́hìn tí mo gba àwọn ádùrá tí ó l'éwu díẹ síi, mo ṣe àwárí pé àwọn ìdarí onírẹ̀lẹ̀ Ọlọ́run yóò ma da àwọn èrò ti ara-ẹni mi dúró nígbà míràn àti pé yóò tọ́ mi sí ìfẹ́ ayérayé rẹ̀.

Ìgbàgbọ́ mi l'ágbára síi.

Ìgbésí ayé mi ní ọrọ̀ síi.

Ọkàn mi kún síi.

Ronú nípa ohun tí ó lè yàtọ̀ tí o bá gb'àdúrà pẹ̀lú òtítọ́ díẹ síi. Tí o bá fi ewu díẹ síi. Tí o bá fi ara rẹ̀ sílẹ díẹ síi sí ohun tí Ọlọ́run lè ṣe nínú rẹ dípò kí ó kàn n'írètí pé òun yóò ṣe nkan fún ọ. Tí o bá gba àwọn ádùrá ìgboyà nkó? Tí o lá àlá tí ó tóbi? Tí o tẹ̀lé Jésù láì bìkítà, pẹ̀lú ìgboyà àti ìgbàgbọ́?

Ó tó àkókò láti yí ọ̀nà tí ò ni gbà gb'àdúrà padà. Ó' tó àkókò láti fi àwọn ádùrá ààbò, ìtùnú, àsọtẹ́lẹ̀ àti ìrọ̀rùn sílẹ̀. Ó tó àkókò láti gb'àdúrà pẹ̀lú ìgboyà àti ewu, láti ṣí ara rẹ sí ọ̀nà tí ó yàtọ̀ sí ibi-àjò tí ó dára ju ti tẹ́lẹ̀. Ó tó àkókò láti bẹ̀rẹ̀ síí gba àwọn ádùrá tí ó l'éwu. Ó tó àkókò láti da ara rẹ láàmú.

Tí o bá fẹ́ ṣe ohun tí ó yàtọ̀ lórí ilẹ̀ lóòtó, ìwọ yíò nílò agbára láti ọ̀run. Tí o bá fẹ́ kí ìgbésí ayé rẹ ṣe pàtàkì, ó tó àkókò láti gba àwọn ádùrá onígboyà nlá. 

Wá Ọlọ́run kí o sì lá àlá nlá. Kọ̀ láti bẹ̀rù ìkùnà. Ó tó àkókò láti jáde. Láti gbẹ́kẹ̀lé. Láti gbìyànjú. Láti gbàgbọ́. Ìgbésí ayé rẹ ò ní ní ààbò nígbà gbogbo. Àti pé yóò gba ìgbàgbọ́. Ṣùgbọ́n láì sí ìgbàgbọ́, kò ṣeé ṣe láti wu Ọlọ́run.

Kíni ò n dúró dè?

Kọ́ ẹ̀kọ́ díẹ síi nípa ìwé tuntun Craig Groeschel, Àwọn Ádùrá Tí Ó L'éwu. 

Day 6

Nípa Ìpèsè yìí

Dangerous Prayers

Ṣé lílo ìgbàgbọ́ òní jẹ̀nlẹ́ńkẹ́ ti sú ọ? Ǹjẹ́ o tilẹ̀ ṣetán láti dojúkọ àwọn ìbẹ̀rù rẹ, láti fún ìgbàgbọ́ rẹ lókun, àti láti tú agbára rẹ sílẹ̀? Ètò Bíbélì ọlọ́jọ́ méje yìí tí a mú jáde láti inú ìwe Alufa ilé ìjọ́siǹ Life.Church Craig Groeschel, Àwọn Àdúrà Tí Ó Léwu, pè ọ níjà láti gbàdúrà tó léwu—nítorí títẹ̀lé Jésù kò jámọ́ ìrìn-àjò aláìléwu.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Àlùfáà Craig Groeschel àti Life.Church fún ìpèsè ètò yìí. Fun àlàyé síwájú sí, jọ̀wọ́ lọ sí: https://www.craiggroeschel.com/