Àwọn Ádùrá Tí Ó L'éwuÀpẹrẹ

Dangerous Prayers

Ọjọ́ 3 nínú 7

Wádìí mi

Ṣé o ní ìgboyà láti gb'àdúrà ní ọ̀nà tí o kò tíì gb'àdúrà rí?

Pẹ̀lú gbogbo ọkàn, èmí àti ìyè kíkún ìwàláàyè rẹ? Kíni yóò ṣẹlẹ̀ nínú ìgbésí ayé rẹ àti t'àwọn tí ó wà ní'tòsí rẹ tí o bá bẹ̀rẹ̀ síí gba àwọn ádùrá eléwu?

Ṣé o ní ìgboyà láti mọ̀?

Ọba Sọ́ọ̀lù f'ẹ̀sùn èké kan Dáfídì pé ó ṣọ̀tẹ̀ sí ìjọba, ó sì rán àwọn ọmọ ogun rẹ̀ léraléra tẹ̀lé Dáfídì láti pa á. Pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ̀, Dáfídì fẹ́ wu Ọlọ́run. Ó jà lòdì sí ìbínú rẹ̀ láti dáàbò bò àti láti fi ọlá hàn sí ọba. Ṣùgbón ó mọ̀ pé àwọn èrò rẹ̀ kò jẹ́ pípé nígbà gbogbo. Dáfídì fi ọkàn rẹ̀ s'ílẹ̀ níwájú Ọlọ́run, ó sí gba ọkàn nínú àwọn ádùrá tí ó ní ìpalára jùlọ, tí ó fi àìlera rẹ̀ hàn, tí ó sì l'éwu jùlọ tí ìwọ yóò gbọ́ l'áyé. Nítorí wípé ó fẹ́ b'ọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run ní gbogbo ọ̀nà ayé rẹ̀, Dáfídì gb'àdúrà pé, “Wádìí mi, Ọlọrun, kí o mọ ọkàn mi; yẹ̀ mí wò, kí o sì mọ èrò ọkàn mi. Wò ó bí ọ̀nà ibi kan bá wà tí mò ń tọ̀, kí o sì tọ́ mi sí ọ̀nà ayérayé” (Orin Dafidi 139:23–24).

Kìí ṣe wípé ádùrá yìí ṣòro láti gbà nìkan, ṣùgbọ́n ó ṣòro pàápàá láti fi sínú ìṣẹ àti láti gbé. Nítorí tí o bá ní ìgboyà láti gbà á, ìwọ yíò nílò ìgboyà láti gbé ìgbé ayé tí Ọlọ́run bá fi hàn ọ́ ní ìdáhùn. Nítorí náà, má ṣe gbà á tí o kò bá lè tẹ̀lé e.

Mọ̀ wípé ádùrá yíì ni agbára láti dá ọ l'ẹ́bi. Láti ṣe àtúnṣe sí ayé rẹ. Láti ṣe àtúnṣe sí ònà ayé rẹ. Láti yí ọ̀nà bí o se rí ara rẹ padà. Láti yí bí àwọn ẹlòmíràn ṣe rí ọ padà.

Bóyá o sí n rò pé òrò yìí kìí ṣe ǹkan bàbàrà. Bóyá ò n ronú ìdí tí ó yẹ kí o béèrè l'ọ́wọ Ọlọ́run láti wá ọkàn rẹ nígbà tí o ti mọ gbogbo nnkan tí ó wà nínu rẹ̀. Àmọ́ ìwọ tikalarẹ̀ mọ ohun tí ó wà níbẹ̀.

Ó mọ ohun tí ó wà níbẹ̀. Nítorí náà kí l'ó dé tí o se máa bèèrè fún ohun tí ó hàn gedegbe?

Èyí ni ibi tí ó ti jẹ́ ẹ̀tàn. Láì wò ó fínífíní, ó dàbí pé àwa yóò mọ àwọn ọkàn wa. Àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Mo mọ àwọn èrò mi. Mo mọ ohun tí ó ṣe pàtàkì jùlọ. Mo mọ ìdí tí mo fi n ṣe ohun tí mò n ṣe. Pàápàá, o lè sọ fún ara rẹ̀, mo ní ọkàn tí ó dára. Nko gbìyànjú láti ṣe ìpalára fún ẹnikẹ́ni. Mo fẹ́ ṣe ohun tí ó tọ́. Ọkàn mi dára. Mò n gb'àdúrà, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?

Ṣùgbọ́n Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi ìdàkejì rẹ̀ hàn. Ó lè jẹ́ ìyàlẹ́nu nígbà tí o bá gbọ́ ní ìgbà àkọ́kọ́, ṣùgbọ́n Jeremaya sọ òtítọ́ ibẹ̀ fún wa. Jeremaya jẹ́ ọmọ àlùfáà Lefi kan tí a bí ní àyíká 650 BC. L'àkókò ìjọba Ọba Josiah, Ọlọ́run gbé wòlíì ọ̀dọ́ yìí dìde láti mú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lọ sí Israẹli àti àwọn orílẹ̀-èdè. Jeremaya sọ ní kedere pé ìwọ - pẹ̀lú èmi àti gbogbo ènìyàn tó kù - kò ní ọkàn tí ó dára. Ní òtítọ́, kìí ṣe wípé ọkàn rẹ kò dára nìkan, ṣùgbón ọkàn rẹ burú, ó sì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ ní gbogbo àwọn ọ̀nà rẹ̀. Wòlíì náà sọ pé, “Ọkàn ènìyàn kún fún ẹ̀tàn ju ohun gbogbo lọ, ìwà ìbàjẹ́ sì kún inú rẹ̀; ta ni ó lè mọ èrò ọkàn eniyan?(JER. 17:9 BM).

Láì sí Kristi, ẹ̀tàn ni ọkàn rẹ́ jẹ́. Bí a bá ṣe súnmọ́ Jesu síi, ni a máa ní láti d'ojúkọ àwọn àìpé wa. Ìgbéraga. Ìmọ-t'ara-ẹni-nìkan. Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́. Àfẹ́sódì. Ẹ̀mí àríwísí. 

Gbígbàdúrà eléwu yìí lè ṣí ikanni ìbásọ̀rọ̀ sí Ọlọ́run. Dípò kí o bèèrè l'ọ́wọ́ Ọlọ́run láti ṣe ǹkan fún ọ, béèrè l'ọ́wọ́ rẹ̀ láti fi nnkan hàn nínú rẹ. Àkókò òtítọ́ yìí pẹ̀lú Ọlọ́run lè má yí ọ padà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ṣùgbọ́n yóò ràn ọ́ l'ọ́wọ́ láti dá àìní èmi rẹ mọ̀, àti láti yí ọ̀nà ayé rẹ padà.

Ìdí níyì tí ádùrá Dáfídì yìí ṣe jẹ́ ewu ní gbogbo ọ̀nà.

“Wádìí ọkàn mi, Olúwa.”

Ọjọ́ 2Ọjọ́ 4

Nípa Ìpèsè yìí

Dangerous Prayers

Ṣé lílo ìgbàgbọ́ òní jẹ̀nlẹ́ńkẹ́ ti sú ọ? Ǹjẹ́ o tilẹ̀ ṣetán láti dojúkọ àwọn ìbẹ̀rù rẹ, láti fún ìgbàgbọ́ rẹ lókun, àti láti tú agbára rẹ sílẹ̀? Ètò Bíbélì ọlọ́jọ́ méje yìí tí a mú jáde láti inú ìwe Alufa ilé ìjọ́siǹ Life.Church Craig Groeschel, Àwọn Àdúrà Tí Ó Léwu, pè ọ níjà láti gbàdúrà tó léwu—nítorí títẹ̀lé Jésù kò jámọ́ ìrìn-àjò aláìléwu.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Àlùfáà Craig Groeschel àti Life.Church fún ìpèsè ètò yìí. Fun àlàyé síwájú sí, jọ̀wọ́ lọ sí: https://www.craiggroeschel.com/