Àwọn Ádùrá Tí Ó L'éwuÀpẹrẹ

Dangerous Prayers

Ọjọ́ 5 nínú 7

Fọ́ Mi

Ó dára láti gb'àdúrà fún ààbò àti ìbùkún, ṣùgbọ́n tí o bá fẹ́ díẹ̀ síi nkọ́? Tí o bá fẹ́ agbàrá láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́, agbàrá láti ọ̀run, ìgbàgbọ́ tí kò ṣeé mì, ìbáṣepọ̀ òtítọ́ pẹ̀lú Bàbá rẹ nkọ́? 

Dípò ìbéèrè l'ọ́wọ́ Ọlọ́run láti pa ọ́ mọ́ l'áìléwu, láti fún ọ síi, àti d'ààbò bo ayé rẹ nìkan, o lè ní láti bèèrè l'ọ́wọ́ Ọlọ́run wípé kí ó fọ́ ọ.

Nígbà tí mo ronú nípa gbígba ádùrá yìí, “Olúwa, fọ́ mi,” mo ronú nípa ìrírí kan tí èmi àti Amy ní nínú ẹgbẹ́ kékeré wa. Ní alẹ́ olòtútù kan ní alẹ́ Ọjọ́rú kan ní Oṣù Kínní, a jókòó ní ìgbádún ní yàrá t'ó gbóná kan pẹ́lú àwọn tọkọtaya méje tàbí mẹ́jọ míràn, a sì ní s'ọ̀rọ̀ nípa ádùrá eléwu yìí.

Gbogbo wá pinu wípé lóòtó ni a fẹ́ gb'àdúrà rẹ̀-a sì mọ̀ wípé a fẹ́ ṣe é lóòtọ́- ṣùgbọ́n a kò lè parọ́ wípé àbájáde rẹ̀ bà wá l'érù. Obìnrin àkọ́kọ́ tí ó s'ọ̀rọ̀ mú ìṣeéṣe náà ní pàtàkì ṣugbọn óo jẹ́wọ́ ìjàkadì inú rẹ̀. Ìyàwó ni, ó sì jẹ́ ìyá ọmọ mẹ́rin, ó ti tẹ̀lé Jésù pẹ̀lú ìṣòtítọ́ láti ọdún kejì ilé-ìwé gíga. Ó ṣiṣẹ́ ní iṣẹ́-ìránsẹ́bàwọn ọmọdé ní ilé ìjọsìn, ó san ìdámẹ́wá ní òtítọ́, ó ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn ọmọdé tí a gbà s'ílé, ó lọ sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ kan, ó sì yọ̀nda láti gb'àdúrà ní gbangba ní àwọn ẹgbẹ́ tí ó wà.

Ṣùgbọ́n nígbà tí ìyànjú láti béèrè l'ọ́wọ́ Ọlọ́run láti fọ́ ọ dé, ó kọ̀. “E má bínú, ṣùgbọ́n mo ní láti jẹ́ olóòótọ,” ó sọ. “Nkò fẹ́ béèrè l'ọ́wọ́ Ọlọ́run láti fọ́ mi. Mo bẹ̀rù ohun tí yóò ṣẹlẹ̀. Mo jẹ́ màmá àwọn ọmọ mẹ́rin. Mo nífẹ̀ẹ́ wọn púpọ. B'íbéèrè wípé kí Ọlọ́run fọ́ mi jẹ́ ǹkan ẹ̀rù nlá fún mi láti gbà. Tí mo bá ṣ'àìsàn tàbí ní ìrẹ̀wẹ̀eì ọkàn tàbí tí a bá fà mì kúrò l'ọ́dọ̀ ẹbí mi nkọ́?” 

Púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn míràn nínú ẹgbẹ́ kékeré náà gbọn orí ní àdéhùn.

Sùgbọ́n ìbéèrè mi l'ọ́jọ́ náà lóhùn jẹ́ ìkan náà fún gbogbo wa l'ónìí: kíni à n pàdánù nípasẹ̀ dídi ìtùnú wa mú?

Kíni à n pàdánù nítorí a ṣe ìpinnu láti yàgò fún ìrora àti ìnira?

Jésù sọ pé, “Nítorí ẹni tí ó bá fẹ́ gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là yóo pàdánù rẹ̀. Ṣugbọn ẹni tí ó bá pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nítorí mi, yóo rí i.” (Mat. 16:25). Jésù ò pè wá sí ìgbésí ayé ìtùnú àti ìrọ̀rùn, ṣùgbọ́n ti ọkàn ìtẹríba àti ìrubọ́. Ìfẹ́ wa tí ó ga jùlọ kò yẹ kí ó jẹ́ fún ìfẹ́ wa láti ṣeé ṣe, ṣùgbọ́n fún ìfẹ́ rẹ láti jẹ́ síṣe. Jésù sì n pè wá láti kú sí àwọn ìgbésí ayé ara wa, kí a baà lè gbé ní ìṣẹ́jú sí ìsẹ́jú, ọjọ́ sí ọjọ́ — fún òun. Láti fi àwọn yàrá ìgbádún wa àti àwọn ádùrá àìléwu s'ílẹ̀ kí a baà lè mọ ohun tí ó túmọ̀ ṣí pé a jẹ́ fífọ́ nítorí àwọn ẹlòmíràn.

Nípa ṣíṣe ohun gbogbo jẹ́jẹ́, a lè pàdánù ohun tí ó ṣe iyebíye ju ààbò àti ìtùnú wa lọ. A kò mọ irú àwọn ìbùkún tí ó lè wà ní apá kejì fífọ́ Ọlọ́run.

Ìwée Lúùkù ṣe àkọsílẹ̀ pé, “[Jésù] bá mú burẹdi, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun, ó bù ú, ó bá fún wọn. Ó ní, “Èyí ni ara mi tí a fun yín. [Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.’” (Luku 22:19). O fẹ́rẹ̀ jẹ́ gbogbo àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n Bíbélì ni ó gbà pé ìdarí Jésù láti “ṣe èyí” se ìpèsè ọ̀nà fún àwọn onìgbàgbọ́ láti rántí, bu ọlá, àti ṣe ayẹyẹ ikú àti àjínde rẹ̀. Ṣùgbọ́n díẹ nínú wọn gbàgbọ́ pé “ṣe èyí” Jésù tún tọ́ka sí bí a ṣe gbọ́dọ̀ gbé ìgbé ayé wa. Tí Jésù kó bà s'ọ̀rọ̀ nípa àṣà tí a máa máa ṣe lẹ́ẹ́kọ̀ọ̀kan ní ilé ìjọsìn nkọ́? Tí ó bá tún n pè wá láti jẹ́ fífọ́ àti kí a da ara wa jáde l'ójoojúmọ́ nkọ́? Tí a bá ní ìgboyà, àyà àti ìgbàgbọ́ láti gb'àdúrà, “Ọlọ́run, fọ́ mi” nkọ́?

A kò ṣe ìrántí Jésù nìkan l'àkókó Ìdàpọ̀ Mímọ́ ní ilé ìjọsìn. A rántí rẹ̀ nínú bí a ṣe n gbé ìgbésí ayé wa l'ójoojúmọ́. Nítorí a fọ́ ara Jésù, nítorí a ta ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ s'ílẹ̀ fún wa, àwa pẹ̀lú yẹ kí a gbé l'ójoojúmọ́ fún-un, ní fífọ́ àti ní dídà jáde. 

Èyí lè má dùn ní àkọ́kọ́. Tani ó fẹ́ jẹ́ “fífọ́” àti “dídà jáde”? Èyí jẹ́ mọ́ ìrora àti ìbànújẹ́. Ṣùgbọ́n nínú fífún ayé wa ni a ti rí ayọ̀ òtítọ́. Dípò kí a lépa ìfẹ́ wa, a ju'wọ́ s'ílẹ̀ fún tirẹ̀. Dípò gbígbìyànjú láti fi ohun tí a fẹ́ kún ayé wa, a sọ àwọn àyè wa di òfo láti ṣe ìyàtọ̀ nínú ayé àwọn elòmíràn.

Dídi fífọ́ níwájú Ọlọ́run kìí ṣe ìṣẹ̀lẹ̀ ìgbà kan; ìpinnu ójoojúmọ́ ni. Paulu sọ pé, “L'ójoojúmọ́ ni mò ń kú!” (1 Kọr. 15:31). Kíni ìyẹn túmọ̀ sí? Ní gbogbo ọjọ́, ó yàn láti kan àwọn ìfẹ́ tirẹ̀ mọ́ àgbélèbú kí ó baà lè gbé ní kíkún fún Ọlọ́run. Tí o bá ní ìgboyà láti gba ádùrá yìí, múra s'ílẹ̀. Múra s'ílẹ̀ látilati mọ Ọlọ́run, kí o jẹ́ kí Ọlọ́run mọ̀ ọ́, ní ọ̀nà tí ìwọ kò tíì ní ìrírí rẹ̀ tẹ́lè.

O lè mú ayé ní jẹ́ jẹ́. Ṣùgbọ́n mo gbàgbọ́ wípé ọ fẹ́ ju ìyẹn lọ. Mo yan èyí tí ó yàtọ̀. Èmí jẹ́ ẹni tí n wà ewu pẹ̀lú ìgbàgbọ́ kíkún. Nkò ní ti Ọlọ́run l'ójú pẹ̀lú ìrònú kékeré tàbí ìgbé ayé tí kò l'éwu. Tí àwọn ìbùkún ba wà ní apá kejì fífọ́, fọ́ mi.

Ọjọ́ 4Ọjọ́ 6

Nípa Ìpèsè yìí

Dangerous Prayers

Ṣé lílo ìgbàgbọ́ òní jẹ̀nlẹ́ńkẹ́ ti sú ọ? Ǹjẹ́ o tilẹ̀ ṣetán láti dojúkọ àwọn ìbẹ̀rù rẹ, láti fún ìgbàgbọ́ rẹ lókun, àti láti tú agbára rẹ sílẹ̀? Ètò Bíbélì ọlọ́jọ́ méje yìí tí a mú jáde láti inú ìwe Alufa ilé ìjọ́siǹ Life.Church Craig Groeschel, Àwọn Àdúrà Tí Ó Léwu, pè ọ níjà láti gbàdúrà tó léwu—nítorí títẹ̀lé Jésù kò jámọ́ ìrìn-àjò aláìléwu.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Àlùfáà Craig Groeschel àti Life.Church fún ìpèsè ètò yìí. Fun àlàyé síwájú sí, jọ̀wọ́ lọ sí: https://www.craiggroeschel.com/