Òpin Ìgbéra-à-miga Látọwọ́ Kyle IdlemanÀpẹrẹ
Kí Aláìlera di Alágbára
Nínú ìwé Corrie ten Boom, Aree fún Olúwa, ó sọ nípa arábìnrin kan tí ó pàdé ní ìlú Russia ní àkókò Ogun ìdákẹ́-sí-ara-ẹni tí a sì ń pọ́n àwọn Kristẹni lójú.
Corrie kọ ọ́ wípé, obìnrin arúgbó nàá jókòó lórí àga ìrọ̀gbọ̀kú. Arun ẹ̀gbà ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọṣẹ́ sí ara arábìnrin yìí. Gbogbo ara rẹ̀ ni ó ti lọ́ káàkiri tó bẹ́ẹ̀ tó fi jẹ́ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ tìmù tìmù ni ó nílò láti fi rọra láti jókòó. Kò le dá ṣe oun koun mo, fún ìdí èyí gbogbo àkókò ọkọ rẹ̀ lórí ìtọ́jú rẹ̀ ni. Ìka àárín tó ga jùlọ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ nìkan ló kù tí ó lè darí. Kò sí oun koun mọ́ lẹ́yìn èyí.
Ṣùgbọ́n ṣá o, àrà tí ó fi ìka kan yìí dá. Ìka náà á máa sáré kiri. lórí ẹ̀rọ ìtẹ̀wé lati òwúrọ̀ títí di òru dudu bẹ́ẹ̀ ló ń tẹ, lati ọ̀rọ̀, gbólóhùn, ati àkójọpo gbólóhùn tí o ún fi ṣe ẹ̀dà Bíbélì àti àwọn ìwé Kristẹni míràn sí èdè Russia.
Ọkọ rẹ̀ a máa wòó, ó sì ṣe àkíyèsí pé ó gba ìka rẹ̀ tí ó ti wun jọ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àkókò kí ó tó tẹ ọ̀rọ̀ kan—ṣùgbọ́n kẹ̀rẹ̀ kẹ̀rẹ̀ ó ń sún lọ, ọ̀rọ̀ kan sí òmíràn, títí tí ó fi tẹ gbogbo ìwé Bíbélì já.
Ní àkókò yí ni Corrie ten Boom dé láti bẹ̀ wọ́n wò. Ó wòó níbi tí ó jókòó wọ́kọ wọ̀kọ, bíi egungun lórí àga, àánú rẹ̀ sì ṣeé. Ó wá gbàdúrà báyìí, “Olúwa, O sì wo arábìnrin yìí sàn?”
Ọkọ rẹ̀ rí ìkàánú àlejò wọn, ó wá sọ fún n pé, “Ọlọ́run ní ète láti ipasẹ̀ àìlera rẹ̀. Gbogbo àwọn Kristẹni tó kù nínú ìlú ni àwọn Ọlọpa ìkọ̀kọ̀ ńṣọ gbá gbá gbá. Ṣùgbọ́n nítorí àìsàn rẹ̀ yí tó ti pé, kò sí ẹni tí ó tún yẹ̀ ẹ wò mọ́. Wọn ti fi wá sílẹ, òun nìkan ni ẹni náà tí ó lè ṣe ẹ̀dà ìtumọ̀ èdè láì mú ìfura wá lọ́dọ̀ Ọlọpa.”
Láti sọ pé Ọlọ́run lòó láì bìkítà àìlera rẹ̀, kó iyán ọ̀rọ̀ náà kéré. Òtítọ́ ibẹ̀ ni pé, Ọlọ́run gba ògo láti ipasẹ̀ àìlera rẹ̀ ní ọ̀nà tí ó lágbára. Ìwọ náà yóò káàánú arábìnrin yìí, bí èmi náà ó ti ṣe. Ṣùgbọ́n oun kan tí yóò wù wá láti fi àdúrà lé jìnà, oun yẹn gan tí ó dájú pé ó ń ba ayé rẹ̀ jẹ́, ẹ̀gún ṣóńṣó tí ó n fa ìrora ni ó jẹ́ ibi mímọ́ tí ó fi ààyè fún obìnrin aláìlera yí láti dí òpómúléró ní ìjọba Ọlọ́run
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
A fa ètò yí yọ látinú iṣẹ́ àkànṣe tó tẹ̀lé ìwé Kyle Idle "Not A Fan," a pè ọ́ láti wá pa ìgbéraga tì, nítorí lẹ́yìn èyí ni o lè tẹ̀lé ìlànà àtinúdá ti Jésù.
More