Òpin Ìgbéra-à-miga Látọwọ́ Kyle IdlemanÀpẹrẹ

The End Of Me By Kyle Idleman

Ọjọ́ 4 nínú 7

Ìrẹ̀sílẹ̀ fún Ìṣelógo

Ó ní àwọn ǹkan tí ènìyàn lè kọ́ nínú iṣẹ́-ìráńṣẹ. Ọ̀kan ni wípé àwọn ènìyàn ma ń wá ojútùú sí ìṣòro wọn nínú ìjọ. Ìṣòro ti mú ayé wọn dojú rú, wọ́n sì ń wòye bóyá ìdáhùn tó kọjá òye ènìyàn lè yọjú. Gbèsè, àfẹ́sódì, ìgbéyàwó tó dẹnukọlẹ̀—ohunkóhun tí kò bá jẹ́, àṣẹ̀yìnwá àṣẹ̀yìnbọ̀ rẹ̀ ni wípé wọ́n máa bèrè fún ìtọ́ni. Atọ́ka àwọn kókó, tí o lè tẹ̀lé, láti fi òpin sí ìṣòro rẹ. “Kíni ǹkan tí mo lè ṣe?” A ma ń rò wípé ìdáhùn náà wà nínú ọ̀rọ̀ náà “ṣe.”

Ní àwọn ìgbà míràn tí a bá ní ṣíṣe láti ṣe, òtítọ́ ibẹ̀ ni wípé kò sí ǹkan tí a lè fi rọ́pò rírẹ ara wa sílẹ̀. Ní ipele yìí a lè rí ẹnìkan tó sọ wípé, “Ní báyìí, ó ti yé'mi. Ní ìrẹ̀lẹ̀ síi. Àmọ́ ó yẹ kó ní ǹkan tí mo lè ṣe. Yàtọ̀ sí níní ìrẹ̀lẹ̀ síi.”

Ó rọrùn láti ṣe ju láti dà. Ṣíṣe nííṣe pẹ̀lú ìgbésẹ̀. Àti dà nííṣe pẹ̀lú ìyípadà pọ́nbélé.

Ṣé o fẹ́ mọ ǹkan tó tọ́ láti ṣe? Ó dáa, a lè ṣeé bá yẹn.
-Dúró sókè réré.
-Fọwọ́ sọ àyà rẹ.
-Gba àdúrà yí: “Ọlọ́run, ṣàánú fún mi.”
-Sọ ọ́ láti oókan àyà rẹ.

Mo fẹ́ kó yé ọ wípé èyí tó kẹ́yìn yẹn ni kọ́kọ́rọ́. Ìgbà tí o bá ní ìrẹ̀lẹ̀ ni èyí máa wáyé.

Ǹjẹ́ o ní ìfẹ́ sí àwọn ohùn tó ń ní ko má ṣeé?
-Máṣe fi ẹ̀dùn rẹ hàn.
-Máṣe fi ìwé ẹ̀rí rẹ hàn.
-Máṣe bèrè fún ìbùkún nípasẹ̀ fífi ara rẹ wé ẹlòmíràn.
-Máṣe sọfún Ọlọ́run nípa àwọn ìdí tí o nílò láti di alábùkún fún.
-Máṣe kí Ọlọ́run kú oríire wípé ó ní ọ gẹ́gẹ́bí ọmọ.
-Máṣe dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún iṣẹ́ àṣekára tí o ti ṣe.

Kòsí ohun tó lè dà bíi ìrera-ẹni-sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run. Ọkàn tó ní ìrẹ̀lẹ̀ ló wu Ọlọ́run. Igbe àwọn onírẹ̀lẹ̀ a máa mú Ọlọ́run fi agbára Rẹ̀ hàn.

A ma ń rí ìrẹnisílẹ̀ gẹ́gẹ́bí ǹkan tí máa ń kọ́ngun sí ènìyàn—èyí tó túmọ̀ sí wípé, ẹnìkan tàbí ǹkan kan ló máa rẹ̀wá sílẹ̀. Àìnísẹ́lọ́wọ́ a máa rẹ̀wá sílẹ̀, ìbáṣepọ̀ tó mẹ́hẹ, tàbí àfojúsùn tó f'orí ṣọ́pọ́n. Àmọ́ Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa ìrẹ̀sílẹ̀ tó jẹ́ àtinúdá—àwa fúnra wa là ń ṣeé. Èyí kìíṣe ǹkan tí à ń dúró fún láti ṣẹ́yọ fúnra rẹ̀. “Rẹ ara rẹ sílẹ̀.” Ó fẹ́ lọ́ létí, àbí bẹ́ẹ̀kọ́? Àfi bíi ti alára-mámọ̀yà. Ó ti mọ́ra fún wa láti máa lépa àti borí ní gbogbo ìgbà, dípò rírẹ ara wa sílẹ̀.

Iṣẹ́ àṣepé ìrẹ̀sílẹ̀ nìyí—ǹkan tí Kristi ṣe. Kò ka ara Rẹ̀ kún ǹkan kan. Ó rẹ ara Rẹ̀ sílẹ̀. Èyí ni ẹni tó jẹ́ Ọlọ́run—nípa ìṣẹ̀dá—àmọ́ kò fi ipò yí ruga sókè, àmọ́ kò ka ara Rẹ̀ kún ǹkan kan.

Báwo ni a ti ń rẹ ara wa sílẹ̀? Àwọn ọ̀nà kan tó ti ràn mí lọ́wọ́ láti mú ìgbéraga wá sópin nínú ayé mi ni:
-Láti rẹ ara mi sílẹ̀, mo ma ń mọ̀ọ́mọ̀ jẹ́wọ́ ìkùnà mi.
-Láti rẹ ara mi sílẹ̀, mo ma ń ta ọrẹ láì gbé aago.
-Láti rẹ ara mi sílẹ̀, mo ma ńṣe àwọn ẹlòmíràn dáradára ju ara mi lọ.
-Láti rẹ ara mi sílẹ̀, mo ma ń bèrè fún ìrànlọ́wọ́.

Ọjọ́ 3Ọjọ́ 5

Nípa Ìpèsè yìí

The End Of Me By Kyle Idleman

A fa ètò yí yọ látinú iṣẹ́ àkànṣe tó tẹ̀lé ìwé Kyle Idle "Not A Fan," a pè ọ́ láti wá pa ìgbéraga tì, nítorí lẹ́yìn èyí ni o lè tẹ̀lé ìlànà àtinúdá ti Jésù.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Kyle Idleman àti David C Cook fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú sí, Jọ̀wọ́ lọ sí: www.dccpromo.com/the_end_of_me/

Awọn Ètò tó Jẹmọ́ọ