Òpin Ìgbéra-à-miga Látọwọ́ Kyle IdlemanÀpẹrẹ
A Fọ́ Ọ Kí Ó Lè Di Odidi
Ó ti lé ní mílíọ̀nù àwọn ènìyàn tí ó ti wo ọ̀rọ̀ tí onímọ̀ nípa àwùjọ Brene Brown sọ nínú ìjíròrò TED Talk rè̩ nípa àìlágbára. Nnkan gbòógì tí ó fi l'ókìkí ni òótó̩ tí ó sọ wípé bí ó ti wù kí á má fé̩ gbà tó, a ń fẹ́ òmìnira láti lè gbà pé a ti bàjé̩. A ò lóye pé o nílò kí á ṣe é. Òtítọ́ ni fún gbogbo wa, ó tilẹ̀ ṣe tòótó̩ jù fún àwọn tí kò tilẹ̀ mọ̀.
Brown ń ràn wá ló̩wó̩ láti rí í pé kìí ṣe àwa nìkan. Nnkan tí ó sọ ni pé:: "Àwa ni 'àwọn ènìyàn yẹn'. Òtítọ́ ni pé...àwa ni "àwọn yẹn". Ọ̀pọ̀ wa ni ó jẹ́ pe owó oṣù kan, ìkọ̀sílẹ̀ kan, ọmọ kan t'ó ti gírànán nínú lílo òògùn olóró, ìròyìn àìlera ọpọlọ kan, àìsàn tó le kan, ìfipá bá ni lò kan, yíyó̩ ọtí mu lẹ́ẹ̀kan, alẹ́ ìbálòpọ̀ kan láì lo ìdáàbòbò tàbí yíyan ọ̀ré̩ abánidẹ́ṣẹ̀ kan ló mú wa yàtọ̀ sí 'àwọn yẹn' - àwọn tí a kò ní ìgbẹ́kè̩lé nínú, àwọn tí à ń káànúú, àwọn tí a kìí jẹ́ kí àwọn ọmọ wa bá ṣeré, àwọn tí nnkan burúkú ń ṣẹlẹ̀ sí, àwọn tí a kò fẹ́ ki wọ́n gbé nílé kejì sí wa.”
Ọ̀pọ̀lo̩pọ̀ ohùn ni ó ń ṣọ fun wa pé kí á kàn f'ara hàn, nítorí láì ṣe bẹ́ẹ̀, ayé wa yó dojú dé.
Ọ̀pọ̀lọpọ ohùn ló ń.sọ fún wa pé kí á dára yá, tí a kò bá sì ro èrò tí kò dára, ohun tí kò dára yó ṣàn lọ díẹ̀díẹ̀.
Ìdí nìyí tí àwọn ènìyàn ìwòyí ṣe gbilẹ̀ nínú ìrújú, ọ̀gá nínú fífi ìrora pamọ́, àwọn tí wọ́n ń fi àṣìlò òògùn ba ara wọn jẹ́, ẹrú owó yíyá, atẹ̀lé ohun tí kò nítumọ̀ ati alábàpín ìdánìkànwà. Nítorí pé kò yé wa pé ọ̀nà àbáyọ kanṣoṣo fún bíbàjẹ́ ni...ìbanújé̩.
Ìròyìn ayọ̀ ni pé Ọló̩run sọ ohun tí ó bàjẹ́ di odidi. Á mú ohun tí a fojú fò, ohun tí a kò kà sí, ohun tí a kọ̀ tì, tí a ti pa tì, ohun tí a ti run, tí a ti bàjé̩, Á wá ṣe ohun tí Òun nìkan lè ṣe.
Ọlọ́run fẹ́ràn láti sọ ohun tó bàjẹ́ di ẹlẹ́wà.
Iwe Jeremaya 18:4-6 jẹ́ àwòrán tó re̩wà nípa bí Ọlọ́run ṣe jókòó gẹ́gẹ́ bí amọ̀kòkò tó ń wo ìkòkò pẹ̀lù àlébù rẹ̀, ó sì kọ̀ láti sọ ọ́ nù. Amọ̀kòkò mọ idẹ mìràn "bí ó ṣe dára lójú Rẹ̀." Amọ̀ àti àlébù kan náà ṣùgbó̩n a sọ gbogbo rẹ̀ dọ̀tun. Kò ní àkìtàn. Iṣẹ́ ọnà mímọ ìkòkò leè lo amọ̀ kan ní àìmoye ò̩nà.
Àdúrà mi ni, “Ọlọ́run, mú àwọn àfó̩kù mi kí o sì tùn un mọ sí ohun tí ó bá tọ́ lójú Rẹ.”
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
A fa ètò yí yọ látinú iṣẹ́ àkànṣe tó tẹ̀lé ìwé Kyle Idle "Not A Fan," a pè ọ́ láti wá pa ìgbéraga tì, nítorí lẹ́yìn èyí ni o lè tẹ̀lé ìlànà àtinúdá ti Jésù.
More