Òpin Ìgbéra-à-miga Látọwọ́ Kyle IdlemanÀpẹrẹ

The End Of Me By Kyle Idleman

Ọjọ́ 6 nínú 7

Di Àìkàyẹ Lati Di Àyànfẹ́

Njé̩ o rántí ìtan Pó̩ọ̀lù lójú ọ̀nà Damáskù? Ọló̩run mú Pọ́ọ̀lù, Ó sì tún un dá gẹ́gẹ́ bí aṣíwájú fún agbo Krìsté̩nì, ajíhìnrere àkó̩kó̩ tí kìí ṣe ẹlé̩sín Júù àti ẹni àkọ́kó̩ pàtàkì nínú ẹ̀kó̩ ìmọ̀ Krístì.

Tí ẹnikẹ́ni bá wà t'ó yẹ kí á f'agilé bí aṣíwájú, n jé̩ kìí ṣe ẹni tó pa àwọn onígbàgbọ́, t'ó sì sèètò láti máa fín àwọn ọmọ ìjọ jáde fún pípa?

Kìí ṣe pé Jésù nílò Pọ́ọ̀lù. Ìlànà tuntun yìí ti ń yí àwọn ènìyàn lọ́kàn padà ó sì ti ń sọ àwọn kan di adari. Pẹ̀lú irú ohun àìrò tẹ́lẹ̀ yìí, Ọ́lọrun fẹ́ ṣe nnkàn kan. A níláti gbà pé Ó n fi iṣẹ́ kan ránṣẹ́.

Kínni iṣé̩ náà dá lé - kí ló sì já sí fún ìwọ àti èmi?/p>

Ó túmọ̀ sí pé kò sí àìkàyẹ kankan fún wa. Ó ṣe ni láàánú tí a bá rí lára wa t'ó rò pé nnkàn tí O̩ló̩run rí nígbà t'O bá wò wá ni pé àsìkò wa ti fé̩ jù.

Ṣé o rò pé Pétérù kò ro irú èrò yí? Jésù ló fúnra Rẹ̀ yàn án, Ó sì lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ àkókò pẹ̀lú rẹ̀. Ó ní láti ní ìdí tí Jésù fi pè é ní Àpáta - tani kò ní fé̩ kí á sọ òun nì orúkọ yìí?

Ṣùgbó̩n lé̩hìn ìgbà t'o ṣe ohun gan an tí Jésù sọ pé yóó ṣe, wípé yóó sẹ́ Òūn ní àsìkò ìdààmú, Pétérù padà sí ẹsẹ̀ àárọ̀ rẹ̀ ní èrò pé òūn tí yọ kúrò l'ágbo. Jésù ri dájú pé Òūn sọ fún un pé yóò kùnà. Kí ló dé tí Ó fi ṣe èyí? Bóyá Pétérù rò pé ohun tí Jésù n sọ ni pé, "O kò ní lè kọjá ibí yìí. Ní wákàtí díẹ̀ sí ìsinyìí, o máa ṣe àṣìṣe".

Pétérù lọ p'ẹja, èyí tíí ṣe ọ̀nà tó kù t'ó mọ̀. Ó ti parí fún mi. Àsìkò mí dé, mo sì ṣìí lò.

Láàárọ̀ kùtùkùtù ọjó̩ yìí nínú o̩kò̩ ojú omi, ó ronú lórí bí gbogbo àlá o̩jó̩ ò̩la rẹ̀ ṣe dojú dé. Jésù ti ka òūn yẹ, èyí tó jẹ́ ìyanu. Ó ti f'agilé ara rẹ̀, àjálù sì ni èyí.

Ló bá gb'ójú s'ókè láti wo ẹni tí ó wà ní etí òkun. Láì ka nnkan kan sì, Jésù ni, Ó ń juwó̩ sí i, Ó ń sọ fún un pé iṣẹ́ pọ̀ láti ṣe, kín ló ń ṣe nínú ọkọ̀ ojú omi?

Mo yàn ọ́. síbẹ̀.

Kín ni àjàgà àtẹ̀hìnwá tí ò tún ń gbé kiri? Àgbèrè? Lọ bá Dáfídì sọ̀rọ̀. Iró̩? Ẹ̀tàn? Ábráhámù àti Ísákì mọ díẹ̀ nípa ìyẹn. Ọjó̩ àná t'ò kún fún èéérí? O̩ló̩run yan Ráhábù, asẹ́wó. Ìbínú àti ìrúnú? Jákọ́bù àti Jòhánù wọ inú ètò Ọló̩run síbẹ̀. Àwọn ìbánidó̩rẹ̀é̩ tí kò yọrí sí rere ń kó̩ọ̀? Obìnrin tí Jésù bá létí kànga ní ìrírì rẹ̀, O̩lọ́run sì rán Jésù sí i pẹ̀lú ọ̀rọ̀ pàtàkì.

Bóyá ìwọ ló kàn lónìí. Jésù ní ọ̀rọ̀ kan fún ọ. Kò ní ṣe pẹ̀lú àmúyẹ t'óo ní. Ó dá lórí pé kí o rí pé ipá rẹ ti pin, nítorí nígbà yìí ni Ọlọ́run yóò lè lò ọ́ ní ọ̀nà tó dára jù. Nípa oore ọ̀fé̩ Rẹ̀ ló fi yàn ọ́, kìí ṣe nípa nnkàn tí o lè mú wá.

Ọjọ́ 5Ọjọ́ 7

Nípa Ìpèsè yìí

The End Of Me By Kyle Idleman

A fa ètò yí yọ látinú iṣẹ́ àkànṣe tó tẹ̀lé ìwé Kyle Idle "Not A Fan," a pè ọ́ láti wá pa ìgbéraga tì, nítorí lẹ́yìn èyí ni o lè tẹ̀lé ìlànà àtinúdá ti Jésù.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Kyle Idleman àti David C Cook fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú sí, Jọ̀wọ́ lọ sí: www.dccpromo.com/the_end_of_me/

Awọn Ètò tó Jẹmọ́ọ