Òpin Ìgbéra-à-miga Látọwọ́ Kyle IdlemanÀpẹrẹ
Ojúlówó Àti Gbàni Mọ́ra
Àwa gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn ń tiraka pẹ̀lú òtítọ́ nítorí a bẹ̀rù ìkọ̀sílẹ̀. A fẹ́ kí aráyé rí wa lọ́nà tó dára jù lọ nítorí pé nígbà náà, ó ṣeé ṣe káwọn èèyàn tẹ́wọ́ gbà wá, ó sì ṣeé ṣe kí wọ́n gbóríyìn fún wa.
Boya a kò nílo lati gbìyànjú líle tó bẹ́ẹ tàbí láti fi èyíkéyìí awọn àbàwọn wa pamọ́. Boya awọn ènìyàn yóò fẹ́ràn wa gẹ́gẹ́ bi a ṣe jẹ. Ó tilẹ̀ ṣeé ṣe kí wọ́n túbọ̀ fà mọ́ wa bí wọ́n bá mọ díẹ̀ lára àwọn ìkùnà wa àti àwọn ìjàkadì wa. Wọ́n lè sọ pé, “Èmi náà rí bẹ́ẹ̀. Mo ni awọn ọ̀ràn kanna. Inú mi dùn láti mọ pé a pé meji."
Ṣugbọn ewú kàn wà tí a kò ní gba. Ẹ̀rù jẹ ọtá sí atinuriwa. A ko fẹràn àwọn abawọ́n wa, ati pe a ko níreti kí ẹnikẹni fẹ́ ẹ gẹ́gẹ́. Nitorinaa a ṣiṣẹ́ takúntakún láti fihàn pé a wuyi julọ.
“Mimọ ni Ọkàn”… Ìyẹn jẹ́ nkán kàn láti gbé ro, àbí? Ó túmọ si wípé ò ń gbé ìgbésí ayé tí o ni ìbùkún nígbàtí o ba yé d'ọ́kàn rú nípa àwọn àmi àti ìpolongo rẹpẹtẹ àti gbogbo igbiyanju láti parọ́wa fún àwọn ènìyàn pé o jẹ́ ohún ti o yatọ sí bí o ti ṣe wa. Nígbàtí inú àti ìta bá báramu, iwọ jẹ́ mímọ ní ọkàn àti pé o wà níbití Ó fẹ́ kí o wà.
Dídé òpin ará mi túmọ si wípé nkò ní àníyàn púpọ mọ̀ làti máà pidán fún àwọn mìíràn mọ. Dídé òpin ará mi túmọ si wípé ǹ kò nífẹ láti gbé ìgbé ayé irọ́ mọ́, nítorí o yé mi wípé aiṣẹ̀tàn mí ni Ọlọ́run n wa.
Nígbàtí a bá tẹríba láti dúpẹ ní ilé oúnjẹ, báwo ní ọkàn wà ṣe wà laiṣẹ̀tan tí kò dàrú? Ṣé Ọlọ́run àti ìpèsè oúnjẹ rẹ̀ lo kún ọkàn wa, àbí apá kan lára wa ń ronú nípa bí a ṣe fara hàn sáwọn èèyàn?
Nígbàtí a bá na ọwọ́ wa sókè láti yọọda fún iṣẹ́ àkànṣe ní ilé ìjọsìn, mélo nínú ọkàn ni a yà sọ́tọ láti ṣe ìfẹ Ọlọ́run, ati mélo ni ó kọbiara si ẹni tí ó nwo àti bí orí wọn ṣe wú sí?
Ǹjẹ́ a máa ń ro wípé tani o ṣọ́ àwo ìrúbọ náà bí o ṣe ń kọjá lọ?
Nígbà tí a bá dúró láti gbàdúrà ní gbangba, njẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ yēn wà fún etí Ọlọ́run tàbí tí àwọn tí ń gbọ́ bí?
Dídé òpin ará mi túmọ si wípe mo tí parí pẹlú àti máà wá iyìn tàbí àkíyèsí ènìyàn àti ofó tí o mú jáde. Kàkà bẹ́ẹ̀, mo wá láti tẹ́ Ọlọ́run nìkan lọ́rùn- èrè mi lọ́wọ́ rẹ̀ ni mo ń wá dípò láti ọwọ́ àwọn ènìyàn. Nígbàtí a bá ti ilé-iṣeré ti gbogbo ènìyàn, fa aṣọ-ikele silẹ̀, pa àwọn iná, tí a si ṣeré si olùworán kan, lái bikita nípa àtúnyẹwò àwọn aláriwisi tabi ẹlòmíràn, nígbà yẹn ni a de òpin tí ará wá tí a si ní ìrírí Ìbùkún Ọlọ́run.
Nípa Ìpèsè yìí
A fa ètò yí yọ látinú iṣẹ́ àkànṣe tó tẹ̀lé ìwé Kyle Idle "Not A Fan," a pè ọ́ láti wá pa ìgbéraga tì, nítorí lẹ́yìn èyí ni o lè tẹ̀lé ìlànà àtinúdá ti Jésù.
More