Òpin Ìgbéra-à-miga Látọwọ́ Kyle IdlemanÀpẹrẹ

The End Of Me By Kyle Idleman

Ọjọ́ 1 nínú 7

Èmi ọ̀wọ́n

Èmi ọ̀wọ́n,
Mo ti mọ̀ ọ́ ní ìwọ̀n ìgbà tí mo lè rántí. Mo ti gbọ rí pé “ọ̀rẹ́ wà tí ó sún mọ́ ni ju ọmọ ìyá lọ,” Mo ti súnmọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ èyàn, ṣùgbọ́n ìwọ àti èmi? Aní àsomọ́ tó yàtọ̀.

àti wípé, bẹ́ẹ̀ni, àwa nì yẹn, bíótilẹ̀jẹ́wípé mo ní iyèméjì pé ohun tí òwe yẹn ń sọ nìyẹn.

Wíwo àti ẹ̀yìn wá, ó tọ́ láti sọ pé mo ṣe ọ́ daada. Kí á sọ tòótọ́, ọ̀pọ̀ ìgbà ju tí mo lè kà, mo gbé ọ ṣá jú ohuńkóhun àti ohungbogbo. Ṣé o gbà?

Bí a tí ń dàgbà, Mo gbìyànjú láti ri wípé o wà ní ìpò àkọ́kọ́ ní orí ìlà. Mo rí si wípé o gba kúkì tí ó tóbi jùlọ nínú àwo, ibi ìwà ọkọ̀ sí tí ó dára jùlọ, ìjóko tí ó tura jùlọ nínú iyàrá tí a bá wọ̀.

Ní ilé ìwé, Mo ṣe àkíyèsi àwọn ohun kékèké tí o nífẹ sí, mo sì tẹ̀lé wọn. O fẹ́ràn àkíyèsi nígbàgbogbo, mo ṣe ohun gbogbo ní ìkáwọ́ mi láti ri wípé o ni. O sì tún fẹ́ àyànláyò, nítorínà mo lo ọgbọ́n láti fi ẹ́ sí ojú ẹ̀. Nísìnyín tí ati ní ayélujára, mo ní irin iṣẹ́ tó pọ̀ si. Mo gbé àwọn àwòrán èyí tí ó ṣe àfihàn rẹ ní dáada jùlọ nìkan jáde. Ẹnikẹ́ni ma rò wípé ò ń gbé ìgbé ayé àlá. Njẹ́ o ti rí àwọn àsọyé tí àwọn èyàn ńkọ nípa rẹ? Nígbà tí o bá ti gbìnyànjú tàbí tí o ní àkókò tí ó le, Mo ti ṣe gbogbo ipá mi láti tọ́jú àṣhírí kékeré wa. Mo gbìyànjú láti mú inú rẹ dùn.

Dájú, Ó rọrùn díẹ̀ láti mú inú ẹ dùn nígbà tí o jẹ́ ọmọ kékeré. Ìbínú fífaraya tí ó rọrùn ló ṣe iṣẹ́ náà. Lẹ́hìn náà, bí a ti ń dàgbà, Mo ní láti jẹ́ olóye díẹ̀ si. O fẹ́ láti ma borí àti láti ma rí ohun gbogbo tí o bá fẹ́—ní gbogbo ìgbà yí o jọ oníwà ìrẹ̀lẹ̀ àti aláìbíkítà. Ìyẹn amáa jẹ́ ẹ̀tàn! Láì sọ rírẹ̀ ẹni.

Kí a sọ tòótọ́, O kò tiẹ̀ bìkítà nipa àwọn ohun tí kò yánilára bí owó sísan àti àwọn àbájáde àti ohun tí yí ò ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ ọ̀la. Mo ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ líle tí kìí ṣe díẹ̀ sí àwọn èyàn kan fún ẹ, o kò ti lẹ̀ kìlọ̀fúnmi nípa ìdọ̀tí náà. O kò ti lẹ̀ sọ fún mi wípé mi ò ní lè kó àwọn ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ jẹ.

Mo ní ìfẹ́ rẹ, èmi. Ṣùgbọ́n mi ò lè ma gbé ìgbé ayé fún ẹ. Ní gbogbo ìgbà ni o ma ń tẹnumọ pé tí mo bálè ma mú ínú ẹ dùn, ìgbà náà ni inú mi yí ò dùn—bí ó ti lẹ̀ rọrùn tó. Ṣùgbọ́n ṣé o mọ ńkan? Kò rọrùn bẹ́. Kò ti rí bẹ́ẹ̀ rí.

Èmi, Mo ti jẹ́ kí o wà ní ìṣàkóso àti láti jòkó sí ìjòkó awakò, sùgbọ́n ó hàn gbangba pé o kò ṣeé gbẹ́kẹ̀lé. O ma ń tẹnumọ pé o mọ ọ̀nà tí ó yẹ kí a lọ, ṣùgbọ́n a máa já sí pàbó nígbàgbogbo. Mo ti wo àwọn àṣàyàn míràn, mo sì ti pinu láti bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò ní ọ̀nà tí ó yàtọ̀. Ó dí ó sì ṣòro àtiwípé kìíṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó n yàn, ṣùgbọ́n ó ńyọrí sí ìgbé aiyé ọ̀pọ̀lọpọ̀ tí ó jẹ́ gidi. Síbẹ̀síbẹ̀, àti pé kò sí ọ̀nà tí ó rọrùn láti sọ èyí, Èmi kò lè gba ọna yíi tí mo bá mú ọ mọ́ ra.

Nítorínà, Èmi, èyí ni òpin rẹ.

Tọkàntọkàn,
Èmi

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

The End Of Me By Kyle Idleman

A fa ètò yí yọ látinú iṣẹ́ àkànṣe tó tẹ̀lé ìwé Kyle Idle "Not A Fan," a pè ọ́ láti wá pa ìgbéraga tì, nítorí lẹ́yìn èyí ni o lè tẹ̀lé ìlànà àtinúdá ti Jésù.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Kyle Idleman àti David C Cook fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú sí, Jọ̀wọ́ lọ sí: www.dccpromo.com/the_end_of_me/

Awọn Ètò tó Jẹmọ́ọ