Oore-ọ̀fẹ́ ati Ìm'oore: Máà gbé nínú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Oore-ọ̀fẹ́ Rẹ̀Àpẹrẹ
Ète Ọlọ́run fún Ọ
Mímí èémí gígùn wọlé lẹ́yìn òjò ìgbà ìrúwé, tí àwọn ẹyẹ òwúrọ̀ ń kọrin ìyìn, dídákẹ́ jẹ́ẹ́, tí mo sì ń gbádùn àkókò tí mo fi dákẹ́ jẹ́ẹ́ pẹ̀lú Ọlọ́run – gbogbo ìrírí wọ̀nyí mú àwọn àkókò inú dídùn wá nínú Olúwa. Àti pé bí o ṣe ń lo àkókò púpọ̀ síi nínú àwọn ẹ̀dá Rẹ, nínú Ọ̀rọ̀ Rẹ, nínú àdúrà, Ó gbin àwọn irúgbìn ìfẹ́ fún àwọn ète Rẹ̀ fún ọ. Bí o ṣe ń fún-un ní ọkàn rẹ, Ó ń kọrin padà sí tìrẹ, Ó ń pè ọ́ láti ṣe ohun tí ó dá ọ fún. Yíó sì pọ̀ ju òye rẹ – à n sọ ọ́ di iṣẹ́ àrà.
Àdúrà:
Baba, mo ní ìfẹ̀ẹ́ wíwà ní iwájú Rẹ àti wíwà nínú àláfíà àti ìfẹ́ tí O ní fún mi. Mo fẹ́ ohun tí O fẹ́ fún mi nítorí mo mọ̀ pé òhun ní ó dára jùl ọ. Àmín.
Bí o bá gbádùn ìfọkànsìn yìí, tí o sì fẹ́ láti máa kọ́ bí o ṣe lè ní ìrírí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, lọ sí dayspring.comláti gba ẹ̀dà ìwé 100 Days of Grace & Gratitude tí Shanna Noel kọ.
Nípa Ìpèsè yìí
Ọlọ́run ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìlérí fún ọ, àti pé Ó pinnu láti pa gbogbo wọn mọ́. Ṣùgbọ́n ní ayé òde òní, ó rọrùn láti gbàgbé oore àti ore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run. Ètò Ìfọkànsìn ọlọ́jọ́ méje yìí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti rántí ọ̀pọ̀lọpọ̀ oore-ọ̀fẹ́ àti àwọn ìbùkún rẹ̀ nípasẹ̀ àkóónú tí ó wà nínú ètò ìfọkànsìn yìí, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti àrò jinlẹ̀ àdúrà ojoojúmọ́. Ìwádìí yìí wá láti inú ìwé akọọlẹ ìfọkànsìn ọlọ́jọ́ ọgọ́rùn-ún ti ore-ọ̀fẹ́ àti ìdúpẹ́ nípàṣẹ Shanna Noel ati Lisa Stilwell.
More