Oore-ọ̀fẹ́ ati Ìm'oore: Máà gbé nínú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Oore-ọ̀fẹ́ Rẹ̀Àpẹrẹ
Gbé Ẹrù Rẹ Lé E
Kíni ohun tí ó wúwo tí ó wà ní ọkàn rẹ? Kíni àwọn nǹkan tí ń fa ẹ̀mí re sí ọ̀nà oríṣiríṣi tí ó sì jẹ́ kí ó rẹ̀ ọ? Olúfẹ́, Ọlọ́run mọ̀ nípa gbogbo wọn. Àti pé Ó ní òye pé o jẹ́ aláìlágbára àti pé o kò lè ṣe ohun púpọ̀ ní àsìkò kan náà. Nítorí ìdí èyí ni ó ṣe ṣe ìlérí láti ṣe ìrànlọ́wọ́ - Òun yóò gbé àwọn ẹrù rẹ. Kò sí àkókò tàbí gbèdéke lórí bí ẹrù ṣe wúwo sí láti jẹ́ kí Ó sọ pé, “O ti lo ìpín rẹ fún ọjọ́ òní.” Agbára Rẹ̀ kò ní ààlà, kò sì sí ìdààmú tí ó le jù fún Un. Ìdùnnú ńlá ni ó jé fún-un láti se ìrànlọ́wọ́ àti ṣe ìpèsè fún gbogbo àìní rẹ. Ṣùgbọ́n o ní láti kọ́kọ́ gbé gbogbo wọn sí ọwọ́ Rẹ̀, lẹ́yìn náà gbẹ́kẹ̀le, kí o sinmi nítorí pé o mọ̀ pé Òun ní ìṣàkóso lóri wọn.
Àdúrà
Olúwa, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Rẹ fún oore-ọ̀fẹ́ àti agbára Rẹ láti gbé mi la ojọ́ yìí kọjá. Mo gbé àwọn ẹrù mi fún Ọ nísinsìnyí mo sì ní ìsinmi ní ìgbà tí mo mọ̀ pé O ti gbé gbogbo rẹ̀, àti pé ìwọ wà pẹ̀lú mi. Àmín.
Nípa Ìpèsè yìí
Ọlọ́run ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìlérí fún ọ, àti pé Ó pinnu láti pa gbogbo wọn mọ́. Ṣùgbọ́n ní ayé òde òní, ó rọrùn láti gbàgbé oore àti ore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run. Ètò Ìfọkànsìn ọlọ́jọ́ méje yìí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti rántí ọ̀pọ̀lọpọ̀ oore-ọ̀fẹ́ àti àwọn ìbùkún rẹ̀ nípasẹ̀ àkóónú tí ó wà nínú ètò ìfọkànsìn yìí, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti àrò jinlẹ̀ àdúrà ojoojúmọ́. Ìwádìí yìí wá láti inú ìwé akọọlẹ ìfọkànsìn ọlọ́jọ́ ọgọ́rùn-ún ti ore-ọ̀fẹ́ àti ìdúpẹ́ nípàṣẹ Shanna Noel ati Lisa Stilwell.
More