Oore-ọ̀fẹ́ ati Ìm'oore: Máà gbé nínú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Oore-ọ̀fẹ́ Rẹ̀Àpẹrẹ

Grace & Gratitude: Live Fully In His Grace

Ọjọ́ 5 nínú 7

Ẹ Máa Yọ̀ Nínú Olúwa

Ó rọrùn láti máa yọ̀, kí a máa gba àdúrà, kí a sì máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run ní ìgbà tí nǹkan bá ń lọ dáadáa fún wa, àmọ́ tí ó bá wá jẹ́ pé ó ń ṣòro fún wa láti dìde lórí ibùsùn wa ńkọ́? Jésù mọ̀ pé ẹ̀yin yóò ní àkókò líle koko, òògùn ààbò fún ẹ̀mí tí ó ti di ahẹrẹpẹ ni ìyìn – kì í ṣe fún ìjàkadì náà, ṣùgbọ́n fún ìwàláàyè Rẹ̀ àti ìlérí ìyè ayérayé pẹ̀lú Rẹ̀. Ó ní ìfẹ̀ẹ́ rẹ. Ó kú nítorí rẹ. Àwọn ìdí wọ̀nyí ló sì yẹ kí a fi máa yọ̀ nínú rẹ̀, kí a sì máa yọ̀ láì ka ohunkóhun tí ó lè ṣẹlẹ̀ sí.

Àdúrà:

Jésù, mo yọ̀ nínú rẹ nísinsìn yí, mo sì dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ láti inú ọkàn mi fún ẹbọ tí o rú lórí àgbélébùú nítorí mi. Mo dúpẹ́ gan-an lọ́wọ́ rẹ. Àmín.

Ọjọ́ 4Ọjọ́ 6

Nípa Ìpèsè yìí

Grace & Gratitude: Live Fully In His Grace

Ọlọ́run ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìlérí fún ọ, àti pé Ó pinnu láti pa gbogbo wọn mọ́. Ṣùgbọ́n ní ayé òde òní, ó rọrùn láti gbàgbé oore àti ore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run. Ètò Ìfọkànsìn ọlọ́jọ́ méje yìí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti rántí ọ̀pọ̀lọpọ̀ oore-ọ̀fẹ́ àti àwọn ìbùkún rẹ̀ nípasẹ̀ àkóónú tí ó wà nínú ètò ìfọkànsìn yìí, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti àrò jinlẹ̀ àdúrà ojoojúmọ́. Ìwádìí yìí wá láti inú ìwé akọọlẹ ìfọkànsìn ọlọ́jọ́ ọgọ́rùn-ún ti ore-ọ̀fẹ́ àti ìdúpẹ́ nípàṣẹ Shanna Noel ati Lisa Stilwell.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ DaySpring fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ kàn sí: https://www.dayspring.com/