Oore-ọ̀fẹ́ ati Ìm'oore: Máà gbé nínú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Oore-ọ̀fẹ́ Rẹ̀Àpẹrẹ
Oore-Ọ̀fẹ́ Ni A Fi Gbà Wá Là
Láti ìgbà tí wọ́n ti bí wa, ohun tí ó fà á àti ohun tí ó máa ti ẹ̀yìn rẹ̀ yọ ni ó ń darí wa. Tí a bá ṣe ohun tí ó dára, àwọn èníyàn á kíyè sí i, wọ́n á sì yìn wá. Bí a bá ṣe àṣìṣe, a máa ń dá wa ní ẹjọ́, a sì máa ń jíhìn títí dì ìgbà tí a ó fi ṣe àtúnṣe. A máa ń jẹ́ kí ìwà wa mú èrè, ìtẹ́wọ́gbà, àti ìmúpadàbọ̀sípò wá. Ìdí nìyí tí ó fi ṣòro fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn láti ní òye èròǹgbà oore-ọ̀fẹ́. Nínú àánú Rẹ̀, Kristi kú fún wa kí Ó lè mú àwọn ipò tí ènìyàn dá kúrò kí a lè máa gbé ní òmìnira ní abẹ́ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run. Ohun tí ó fa ikú Jésù ló ṣe pàtàkì jù lọ, ó mú kí a ní òmìnira àti oore-ọ̀fẹ́ nínú ìgbésí ayé wa. A kò ní láti "ṣe" ohunkóhun mọ́ bí kò ṣe láti gbà á gbọ́ kí a sì gbà á. Ṣé o ti ṣe bẹ́ẹ̀ rí?
Àdúrà:
Baba, mo dúpẹ́ fún ẹbọ Ọmọ Rẹ kí n lè máa gbé ní ìbámu pẹ̀lú oore-ọ̀fẹ́ Rẹ. Wàyí o, ràn mí lọ́wọ́ láti tẹ́wọ́ gbà á pátápátá kí n sì máa rìn nínú òmìnira tí mo ní nísinsìnyí. Àmín.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ọlọ́run ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìlérí fún ọ, àti pé Ó pinnu láti pa gbogbo wọn mọ́. Ṣùgbọ́n ní ayé òde òní, ó rọrùn láti gbàgbé oore àti ore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run. Ètò Ìfọkànsìn ọlọ́jọ́ méje yìí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti rántí ọ̀pọ̀lọpọ̀ oore-ọ̀fẹ́ àti àwọn ìbùkún rẹ̀ nípasẹ̀ àkóónú tí ó wà nínú ètò ìfọkànsìn yìí, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti àrò jinlẹ̀ àdúrà ojoojúmọ́. Ìwádìí yìí wá láti inú ìwé akọọlẹ ìfọkànsìn ọlọ́jọ́ ọgọ́rùn-ún ti ore-ọ̀fẹ́ àti ìdúpẹ́ nípàṣẹ Shanna Noel ati Lisa Stilwell.
More