Oore-ọ̀fẹ́ ati Ìm'oore: Máà gbé nínú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Oore-ọ̀fẹ́ Rẹ̀Àpẹrẹ
Àánú Tuntun Ní Ojoojúmọ́
Fi ojú inú wòó wípé o dùbúlẹ̀ ní orí ibùsùn rẹ ní alẹ́, o da aṣọ bo'ra, o sì ń ro gbogbo ohun tí o ti ṣe ní ọjọ́ náà – gbogbo ohun tí o fẹ́ kí o ti ṣe tàbí sọ ní ọ̀nà tí ó yàtọ̀. Tàbí kí ó jẹ́ pé ìṣòro ńlá kan ló ń kó ìbànújẹ́ bá ọ. Ó ti lẹ̀ lè máa ṣe ọ́ bíi pé kí o tún gbogbo rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀. Ó dára, o lè bẹ̀rẹ̀. Ní ojoojúmọ́, ìfẹ́ Ọlọ́run àti àánú Rẹ ń dúró dè ó láti gbà kí o sì bẹ̀rẹ̀ ní ọ̀tun. Àná àti ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ ti kọjá, àti wípé ìdúróṣinṣin àti ìfẹ́ Rẹ̀ ṣì ń jó lala ní ojoojúmọ́.
Ádúrà:
Baba, mo dúpẹ́, ọkàn mi sì balẹ̀ nítorí pé O fẹ́ràn mi gan-an, àánú Rẹ kún inú ìgbésí ayé mi ní ojoojúmọ́. Àmín.
Nípa Ìpèsè yìí
Ọlọ́run ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìlérí fún ọ, àti pé Ó pinnu láti pa gbogbo wọn mọ́. Ṣùgbọ́n ní ayé òde òní, ó rọrùn láti gbàgbé oore àti ore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run. Ètò Ìfọkànsìn ọlọ́jọ́ méje yìí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti rántí ọ̀pọ̀lọpọ̀ oore-ọ̀fẹ́ àti àwọn ìbùkún rẹ̀ nípasẹ̀ àkóónú tí ó wà nínú ètò ìfọkànsìn yìí, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti àrò jinlẹ̀ àdúrà ojoojúmọ́. Ìwádìí yìí wá láti inú ìwé akọọlẹ ìfọkànsìn ọlọ́jọ́ ọgọ́rùn-ún ti ore-ọ̀fẹ́ àti ìdúpẹ́ nípàṣẹ Shanna Noel ati Lisa Stilwell.
More