Oore-ọ̀fẹ́ ati Ìm'oore: Máà gbé nínú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Oore-ọ̀fẹ́ Rẹ̀Àpẹrẹ

Grace & Gratitude: Live Fully In His Grace

Ọjọ́ 2 nínú 7

oore- ọ̀fẹ́ Rẹ̀ ní ẹkún réré

Nígbàtí o bá la ìṣòro kọjá- bóyá ìṣẹ̀lẹ̀ àjálù ńlá, àìsàn, ìjákulè, tàbí ìpọ́njú - ìwà àwọn ènìyàn ni láti wo ìṣòro náà kí wọ́n ṣe ohun ti ó yẹ kán ṣe: àìní ìfọkàn balẹ̀, ìbánújẹ́ tàbí kí ó ju bẹ́ẹ̀lọ. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run fún wa ní ọ̀nà mìíràn: gbẹ́kẹ̀le. Nígbàtí o bá ṣe èyí, ìwọ yóò ní àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ - Àlàáfíà Rẹ̀ tí ó péye fún àkókò tí o wà nínu rẹ̀. Ó mọ gbogbo ohun tí ò ń dojú kọ, àti, pàápàá pẹ̀lú rúdurùdu tí ó wà ní àyíká, o le rìn nínú oore-ọ̀fẹ́ Rẹ ní ẹ̀kún réré àti àlàáfíà tí ó wà nínú rẹ. Kíni ìwọ yóò fi ìgbẹ́kẹ̀lé Rẹ lé lóni?

Àdúrà  

Olúwa, mo dúpé lọ́wọ́ Rẹ fún ìlérí Rẹ láti bùkún fún mi pẹ̀lú àlàáfíà òtítọ́ àti àìnípẹ̀kun Rẹ, láì bìkítà ohun tí mò ń dojúkọ. Àmín.

Ọjọ́ 1Ọjọ́ 3

Nípa Ìpèsè yìí

Grace & Gratitude: Live Fully In His Grace

Ọlọ́run ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìlérí fún ọ, àti pé Ó pinnu láti pa gbogbo wọn mọ́. Ṣùgbọ́n ní ayé òde òní, ó rọrùn láti gbàgbé oore àti ore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run. Ètò Ìfọkànsìn ọlọ́jọ́ méje yìí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti rántí ọ̀pọ̀lọpọ̀ oore-ọ̀fẹ́ àti àwọn ìbùkún rẹ̀ nípasẹ̀ àkóónú tí ó wà nínú ètò ìfọkànsìn yìí, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti àrò jinlẹ̀ àdúrà ojoojúmọ́. Ìwádìí yìí wá láti inú ìwé akọọlẹ ìfọkànsìn ọlọ́jọ́ ọgọ́rùn-ún ti ore-ọ̀fẹ́ àti ìdúpẹ́ nípàṣẹ Shanna Noel ati Lisa Stilwell.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ DaySpring fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ kàn sí: https://www.dayspring.com/