Oore-ọ̀fẹ́ ati Ìm'oore: Máà gbé nínú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Oore-ọ̀fẹ́ Rẹ̀Àpẹrẹ
![Grace & Gratitude: Live Fully In His Grace](/_next/image?url=https%3A%2F%2Fimageproxy.youversionapi.com%2Fhttps%3A%2F%2Fs3.amazonaws.com%2Fyvplans%2F16227%2F1280x720.jpg&w=3840&q=75)
Rírìn Pẹ̀lú Ayọ̀
Ǹjẹ́ o tí rò ó rí pé, ní ìgbà tí Jésù wà ní ayé, ó rìn pẹ̀lú ayọ̀ Bàbá rẹ̀? Bẹ́ẹ̀ni, ní ìgbà tí ó ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, tí ó ń wo àwọn aláìsàn sàn, tí ó ń sì ń wàásù títí tí ó rẹ̀ ẹ́, Jésù ṣí kún fún ayọ̀. Àti pé kí ó tó kúrò ní ilẹ̀ ayé, ó sọ pé ní ìgbà tí ẹ bá dúró nínú rẹ̀ tí ẹ sì ń gbé ète rẹ̀ fún ìgbésí ayé yín, ẹ̀yin náà lè ní ayọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú. Ní òtítọ́, ayọ̀ rẹ̀ di pípé nínú yín. Èyí túmọ̀ sí pé iṣẹ́ yòówù tí ẹ bá ṣe tàbí ìṣòro yòówù tí ẹ bá ní, ẹ lè ṣe àṣeyọrí kí ẹ sì borí gbogbo wọn pẹ̀lú ayọ̀ rẹ̀ ní kíkún.
Àdúrà:
Baba, ẹ ṣeun fún àwọn ẹ̀bùn ìyanu àti ìdùnnú yín. Ẹ kún ọkàn àti èrò inú mi, ẹ dì mí mú, kì ẹ sí dá ààbò bò mí bí mo ti nrín ní kíkún ayọ̀ yín ní gbogbo ọjọ́ òní. Àmín.
Nípa Ìpèsè yìí
![Grace & Gratitude: Live Fully In His Grace](/_next/image?url=https%3A%2F%2Fimageproxy.youversionapi.com%2Fhttps%3A%2F%2Fs3.amazonaws.com%2Fyvplans%2F16227%2F1280x720.jpg&w=3840&q=75)
Ọlọ́run ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìlérí fún ọ, àti pé Ó pinnu láti pa gbogbo wọn mọ́. Ṣùgbọ́n ní ayé òde òní, ó rọrùn láti gbàgbé oore àti ore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run. Ètò Ìfọkànsìn ọlọ́jọ́ méje yìí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti rántí ọ̀pọ̀lọpọ̀ oore-ọ̀fẹ́ àti àwọn ìbùkún rẹ̀ nípasẹ̀ àkóónú tí ó wà nínú ètò ìfọkànsìn yìí, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti àrò jinlẹ̀ àdúrà ojoojúmọ́. Ìwádìí yìí wá láti inú ìwé akọọlẹ ìfọkànsìn ọlọ́jọ́ ọgọ́rùn-ún ti ore-ọ̀fẹ́ àti ìdúpẹ́ nípàṣẹ Shanna Noel ati Lisa Stilwell.
More