Ẹ̀mí Mímọ́: Ǹjẹ́ A Gba Iná Jẹ Àbí A Se Ìdáàbòbò Kí á má baà Gba Iná Jẹ?Àpẹrẹ
Iná àtòrunwá tí ó wà láti ïbatísí tí Èmí Mímó ní ó yí ní nípò padà láti yepere sí àgbàyanu. A ó dí ipò àse tí a gbé léwa l'ówómú láti rí wípé àwa kò gbé aiyé fun ara wa mo, a ó sí jòwó èrù àti ìlàkàkà okàn wa, béèni á o sé àmúlò isé tí á gbé léwa lówó láti òdò eléda. A ó sí di ohun èlò lówó eléda wa.
Mósè tí rí orísirísi ìgbé lójojúmó fun ogoji odún. Kò lo Kiri láti wo ìgbé tàbí láti k'èkó nípa won. Igbó aginjù kò fanimóra, a kò gbín wón béè wón kò l'éwà ní wíwò. Nwon kò dára ní wíwò.Sùgbón Olórun yan nínú wón, tí kò já mó nkankan, ó sí so won dí àgbàyanu. Iná búyo lórí rè- sùgbón kò jóná(Ekisodu 3:2). Olórun sòrò láti inú rè. Ó fohùn jade láti inú ìgbé tí njóná. L'ónà kan Mósè dàbí ìgbé yí- ènìà lásánlàsàn, tí kò já mó nkankan . O jé ìtì igi-ápànìà tí ó ñsá fún ìdájó tí ó sí so ìrètí ojó òla rè nù. Ólùsó-àgùtàn lásán ní íse, gbogbo àwon ólùsó-àgùtàn ní ó jé ìrírá sí àwon ará Egipiti(Genesis 46:24)
Mósè rí ìgbé náà tí ó njóná l'áìyípadà dí eérú. Kò sí mò wípé eléyi lé mú ïyípadà bá ìgbé aiyé on. Ó wõo fín, ó sí yí sí apákan láti rí àrídájú àti fífanímóra rè. Ní àkókò yí iná àtòrunwá yí kúrò ní orí ìgbé yí o sí wo inú èmí rè. Mósè eléran ara yí padà dí Mósè tí ó ní iná nínú. "Ó sí so àwon ïránsé rè dí òwó iná".(Heberu 1:7 NIV). Ní ojó tí ó bá yí sí ègbé kan láti wó ìgbé tí njóná, ìwo kó ní jé eni-yepere mó.
"Ìjíhìnrere tí ó l'agbára jé kèké esin oníná pèlú ìránsé tí ó ní agbára Èmí-Mímó, tí ó sí nwaásu ìhìnréré tí ó gbóná lórí kèké iná! Gbá Èmí-Mímó láyè láti mú kí ìgbésí aiyé rè dí kèké iná"Reinhard Bonnke
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Agbára àgbàyanu, tó ń jí òkú dìde ḿbẹ nínú rẹ. Ajíhìnrere Reinhard Bonnke ti ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ẹ̀kọ́ tó nípọn nípa Ẹ̀mí Mímọ́ fún ọ àti wípé ó kọ àwọn Kókó Àgbàyanu nípa Agbára Ẹ̀mí Mímọ́. Ẹ̀kọ́ Ọlọ́jọ́ Méje yìí ma mú ọ ronú nípa Ẹ̀mí Mímọ́ àti wípé ó máa ru ọ́ sókè láti ní ìgbàgbọ́ nínú agbára Ẹ̀mí náà tó ń gbé nínú rẹ.
More