Ẹ̀mí Mímọ́: Ǹjẹ́ A Gba Iná Jẹ Àbí A Se Ìdáàbòbò Kí á má baà Gba Iná Jẹ?Àpẹrẹ

Holy Spirit: Are We Flammable Or Fireproof?

Ọjọ́ 3 nínú 7

Iná Ọlọ́run nínú Jésù

Fún àwọn kan, ibi ìjọsìn ni. Fún àwọn míràn, ibùjókòó káràkátà tí a ti ń wá oúnjẹ oòjọ́ lọ́nàkọnà. Àmọ́ fún Ọmọ, ilé Bàbá Rẹ̀ ni –ilẹ̀ ọ̀wọ̀ àti ibi àdúrà fún ìgbàlà, ìwòsàn àti ìtúsílẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè. Bẹ́ẹ̀ ló mú pàsán jáde sí àwọn onípàṣípààrọ̀ owó, àwọn olè àti alọ́nilọ́wọ́gbà, tó mú kí àwọn Farisí fárígá, Òun náà pẹ̀lú kò sì bìkítà fún ẹ̀mí ara Rẹ̀. Ṣùgbọ́n bí ọlá Bàbá Rẹ ṣe wà lójú ògbagadì àti bí ìtúsílẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè wà lẹ́sẹ̀ kan ayé ẹ̀sẹ́ kan ọ̀run, Ó fi ikú ṣe ẹlẹyà nítorí ó tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Bí àgbélèbú bá jẹ́ dandan, ó yá níbẹ̀. Ah, irú ìtara wo lèyìí!

Ní ìrírí ènìyàn, iná Ọlọ́run àti ìtara jásí ǹkankan náà—ìyen irú ìtara tí a rí nínú Jésù. Kìí tilẹ̀ ṣe nínú ọ̀rọ̀ Rẹ̀ nìkan ni Ó tí ní ìtara. Nígbàtí Jésù ńlọ sí Jerúsálẹ́mù fún ìgbà ìkẹyìn, a kàá pé Ó ń síwájú àwọn ọmọ-ẹ̀hìn Rẹ̀ lọ. Wọ́n ríi bí Ó ti ń rọ Ara Rẹ̀ láti tẹ̀síwájú (Máàkù 10:32). Kí nìdí? Lẹ́nu kan, iná tí ó wà nínú Ẹ̀mí Rẹ̀ hàn kedere nínú bí Ó ṣe ńlọ níwájú.

Nígbàtí wọ́n dé ọ̀hún, Jésù rí Ìdibàjẹ́ témpílì. Àwọn ọmọ-ẹ̀hìn wáá túnbọ̀ rí àrídàjú ìtara Rẹ̀ ní sàn-án sàn-án. Ohun tí Ó ṣe sọ Ọ́ di Ẹni ìkàyà. A rán àwọn ọmọ-ẹ̀hìn létí ọ̀rọ̀ Sáàmù 69:9: “Nítorí pé ìtara ilé rẹ ni ó jẹ mí lógún...” Àmọ́ ṣá, ìbínú tí o ti inú ìfẹ wá ní kìí ṣe láti inú ọkàn gbígbóná. Jésù kìí ṣe alákatátí-ẹ̀sìn. Ó fẹràn ilé Bàbá Rẹ̀ ni.. Ìpòngbẹ Rẹ̀ ni láti ríi pé àwọn ènìyàn nínú tẹ́ḿpìlì ńjọ́sìn pẹ̀lú òmìnira àti ayọ̀. Ṣùgbọ́n káràkátà inú tẹ́ḿpìlì ti ba èyí jẹ́. Ọkàn Rẹ̀ gbọgbẹ́ gidi bíi igi t'íná mú. Iná Ẹ̀mí-mímọ́ nínú Ẹ̀mí Rẹ̀ mú kí Ó fọ tẹ́ḿpìlì ní àfọ̀mọ́.

Àwọn ọmọdé, afọ́jú àti arọ dúró ní tiwọn, Ó sì mú wọn lára dá (Mátíù 21:14-16). Ohun àìgbodọ̀máṣe l'èyí jẹ́ fún Ùn, àti pé ìdí tí ìbínú Rẹ̀ fi ru gidigidi nìyìí. Ìbínú tó ṣe atọ́nà fún ayọ̀. Ó ṣe àṣeyọrí —àwọn ògowẹẹrẹ ńkorin, “Hosanna!”

day_3

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 2Ọjọ́ 4

Nípa Ìpèsè yìí

Holy Spirit: Are We Flammable Or Fireproof?

Agbára àgbàyanu, tó ń jí òkú dìde ḿbẹ nínú rẹ. Ajíhìnrere Reinhard Bonnke ti ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ẹ̀kọ́ tó nípọn nípa Ẹ̀mí Mímọ́ fún ọ àti wípé ó kọ àwọn Kókó Àgbàyanu nípa Agbára Ẹ̀mí Mímọ́. Ẹ̀kọ́ Ọlọ́jọ́ Méje yìí ma mú ọ ronú nípa Ẹ̀mí Mímọ́ àti wípé ó máa ru ọ́ sókè láti ní ìgbàgbọ́ nínú agbára Ẹ̀mí náà tó ń gbé nínú rẹ.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹgbẹ́ CfaN Kristi Fún Gbogbo Àgbáyé fún ìpèsè ètò yí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: https://shopus.cfan.org/collections/reinhard-bonnke/products/holy-spirit-are-we-flammable-or-fireproof-english