Ẹ̀mí Mímọ́: Ǹjẹ́ A Gba Iná Jẹ Àbí A Se Ìdáàbòbò Kí á má baà Gba Iná Jẹ?Àpẹrẹ

Holy Spirit: Are We Flammable Or Fireproof?

Ọjọ́ 2 nínú 7

A Baptísì Jésù nínú Ẹ̀mí Mímọ́

Láì fi ti pé a ti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ lóyún Rẹ̀, Jésù ní lò ìtẹ̀bọmi ti Ẹ̀mí bí Ó ṣe ń bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìránṣẹ́ Rẹ̀. Bí Jòhánù Onítẹ̀bọmi ṣe ri Jésù bọ omi tán nínú Odò Jọ́dánì, Ìtẹ̀bọmi ìkejì ṣẹlẹ̀. Ẹ̀mí Ọlọ́run bà lé E, bí àdàbà, kìí ṣe bíi ẹ̀là iná, nítorípé kò sí ohùn tí iná yóò jó nínú Jésù.

Àpẹẹrẹ tó ga jù lọ fún àwọn Kristẹni ni Jesu, Ó sì gba Ìtẹ̀bọmi ti Ẹ̀mí Mímọ́. Ìwé Ìhìn Rere ti Mátíù, Máàkù àti Lúùkù, mẹ́tèèta ló kọ àkọsílẹ̀ yí kan náà. Ìwé Ìhìn Rere kẹrin, Jòhánù, ṣe àlàyé síwájú sí. Jòhánù Onítẹ̀bọmi, akígbe-ṣáájú fún Jesu, kéde, “Mo rí bí Èmi ṣe ń sọkalẹ láti ọ̀run bí àdàbà, Ó sì bà lé E lórí” (John 1:32). Jésù fún ra ra Ẹ ṣe àlàyé, “Ẹ̀mí Olúwa ń bẹ lára Mi, nítorí Ó ti fi àmì òróró yàn mí láti wàásù ìhìn rere...” (Luke 4:18). Pétérù, nínú Ìṣe àwọn Àpọ́sítélì 10:38, sọpé, “Ọlọ́run sì fi àmì òróró yan Jésù ti Násárétì pẹ̀lú Èmi Mímọ́ àti agbára.” Jòhánù Onítẹ̀bọmi sọ oun ìtani kán ún kan. “Ẹni tí Ó rán mi láti ṣe ìtẹ̀bọmi pẹ̀lú omi sọ fún mi pé, ‘Ní orí Ẹnití Ẹ̀mí bá sọkalẹ tí Ó sì bà lé, Òun ni Ẹni náà tí yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ bamitíìsì’” (John 1:33).

Kristì ni ìrírí bí ènìyàn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run kí Ó ba lè fi àpẹẹrẹ ìrírí ènìyàn tó pé hàn. Òun ni àkọ́kọ́ láàrin ogunlọ́gọ̀. Òun ni irúfé àkọ́kọ́ ẹ̀dá ènìyàn tí a fi Ẹ̀mí Mímọ́ bamitíìsì láyé. Jòhánù 3:34 sọpé, “Ọlọ́run fi Ẹ̀mí fún Un láì sí òdiwọ̀n.” John 1:16 kéde, “Nínú ẹ̀kún rẹ́rẹ́ Rẹ̀ ni gbogbo wa ti gbà...” Èyí ni ìyanu òtítọ́—oun tí Ó gbà jẹ́ fún wa. Ó gba ìfikún nítorí ti wa, nínú ẹ̀kún rẹ́rẹ́ àìlópin Rẹ̀ ni a fi kún wa.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 1Ọjọ́ 3

Nípa Ìpèsè yìí

Holy Spirit: Are We Flammable Or Fireproof?

Agbára àgbàyanu, tó ń jí òkú dìde ḿbẹ nínú rẹ. Ajíhìnrere Reinhard Bonnke ti ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ẹ̀kọ́ tó nípọn nípa Ẹ̀mí Mímọ́ fún ọ àti wípé ó kọ àwọn Kókó Àgbàyanu nípa Agbára Ẹ̀mí Mímọ́. Ẹ̀kọ́ Ọlọ́jọ́ Méje yìí ma mú ọ ronú nípa Ẹ̀mí Mímọ́ àti wípé ó máa ru ọ́ sókè láti ní ìgbàgbọ́ nínú agbára Ẹ̀mí náà tó ń gbé nínú rẹ.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹgbẹ́ CfaN Kristi Fún Gbogbo Àgbáyé fún ìpèsè ètò yí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: https://shopus.cfan.org/collections/reinhard-bonnke/products/holy-spirit-are-we-flammable-or-fireproof-english