Ẹ̀mí Mímọ́: Ǹjẹ́ A Gba Iná Jẹ Àbí A Se Ìdáàbòbò Kí á má baà Gba Iná Jẹ?Àpẹrẹ

A kò lè dá ara wa tọ́
A dá wa lọ́nà tó fi nílò fún wa láti gbára lé ọrẹ ọ̀fẹ́ àti agbára Ọlọ́run. Yàtọ̀ sí ìrónilágbára Rẹ̀, a kò lè dá ṣe ohun kan (Jòhánù 15:5). Ó jẹ́ pípé wa (Kọ́ríńtì kejì 3:5). Ọlọ́run fi Ẹ̀mí Rẹ̀ sínú wa, nítorí a nílò ìtùnú Rẹ̀, láti darí àti tọ́ wa sọ́nà. A máa mú àwọn ẹ̀bùn àti agbára Rẹ̀ ṣiṣẹ́ nínú wa nítorí a nílò rẹ̀ fún iṣẹ́ ìránṣẹ́ tó gbé lé wa lọ́wọ́–ohun èlò ẹ̀mí fún iṣẹ́ ẹ̀mí.
A kò dá wa l'ókòwò pẹ̀lú àwọn ìṣúra tí ẹ̀mí àti èròjà agbára láti máa dá'ṣẹ́ ṣe. A kìíṣe “kristi” kékeré tó lè dára rẹ̀ tọ́. Lóòrè kóòrè ni à ń rí ọ̀pọ̀ yanturu gbà, “látinú” ọ̀pọ̀ ti Kristi, bíi ẹ̀ka igi àjàrà ti ń rí oje gbà. A kìíṣe àjàrà tó dá wà, tó ní ìṣẹ̀dá tó yàtọ̀, ṣùgbọ́n a jẹ́ pípé nínú Rẹ̀ (Kólósè 2:10).
Kìíṣe pẹ̀lú agbára kéréje tí a ti tùjọ ni à ń pè wá láti jáde lọ sínú ayé, bẹ́ẹ̀ni kìíṣe fún àwọn ènìyàn láti máa rò ó wípé: háà, agbára rèé. Ó ṣeé ṣe fún wa láti dábírà fún wákàtí kan tàbí méjì pẹ̀lú àwọn àmúyẹ àrà-ọ̀tọ̀ tí a ní; àmọ́ ní kòpẹ́ kò jìnà ni èpò agbára yìí yóò gbẹ. A kìíṣe ẹ̀rọ amúnáwá; àmọ́ irin tí iná ń gbà inú rẹ̀ kọjá ni a jẹ́. Éfésù 1:22 àti ẹsẹ̀ 23 ṣe àkàwé “...ìjọ náà, èyí tí ńṣe ara Rẹ̀, gẹ́gẹ́bí ọ̀pọ̀ Ẹni tó jẹ́ ohun gbogbo nínú ohun gbogbo. Òhun ni yóò kún inú wa tí yó sì la ayé wa kọjá. Ọ̀pá omi lásán ni a jẹ́ a kìíṣe orísun. Jésù sọ wípé, “Gẹgẹ bi ẹka kò ti le so eso fun ara rẹ̀, bikoṣepe o ba ngbé inu àjara, bẹ̃li ẹnyin, bikoṣepe ẹ ba ngbé inu mi.” (Jòhánù 15:4).
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Agbára àgbàyanu, tó ń jí òkú dìde ḿbẹ nínú rẹ. Ajíhìnrere Reinhard Bonnke ti ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ẹ̀kọ́ tó nípọn nípa Ẹ̀mí Mímọ́ fún ọ àti wípé ó kọ àwọn Kókó Àgbàyanu nípa Agbára Ẹ̀mí Mímọ́. Ẹ̀kọ́ Ọlọ́jọ́ Méje yìí ma mú ọ ronú nípa Ẹ̀mí Mímọ́ àti wípé ó máa ru ọ́ sókè láti ní ìgbàgbọ́ nínú agbára Ẹ̀mí náà tó ń gbé nínú rẹ.
More