Ẹ̀mí Mímọ́: Ǹjẹ́ A Gba Iná Jẹ Àbí A Se Ìdáàbòbò Kí á má baà Gba Iná Jẹ?Àpẹrẹ
Gbogbo Èèyàn Ló Wà Fún
È̩mí mímọ́ kìí ṣe nnkan tí wọ́n ń pín bíi lọ́tìrì tí ó jẹ́ pé àwọn tí a ti yàn ni a ó fún. Kìí ṣe eré ànfààní. Kò sí olúborí tàbí olófò. Àwọn tí Ọlọ́run pè, Ó ń ró wọn ní agbára. Agbára pọ̀ tó láti kárí gbogbo ènìyàn. A ò yọ ẹnikẹ́ni kúrò, ẹnikẹ́ni kò sì gba àlòkù. Má fagi lé ara rẹ nígbà tí o ti rí ìtẹ́wọ́gbà.
Kò sí nnkan ti ó rújú tàbí tí kò yé ènìyàn nínú Ìwé Mímọ́. Ìrìbọmi È̩mí Mímọ́ kìí ṣe fún àwọn "àyànfẹ́ Ọlọ́run kan”. Rárá o, Ọlọ́run kò ní "ààyò.” Ní pàtó, gbogbo wa ni àyànfẹ́ Rẹ̀. Ní Ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́stì, ọgọ́fà ọkùnrin àti obìnrin wà ní Yàrá Òkè ní Jerúsálẹ́mù, a sì kà nínú Ìṣe Àwọn Àpọ́stélì 2:3 àti 4, “Wọ́n rí nnkan kan tí ó dàbí ahọ́n iná, tí ó pín ara rẹ̀, tí ó sì bà lé ẹnìkọ̀ọkan wọn. Gbogbo wọn sì kún fún È̩mí mímọ́...” Kò ṣèèṣì, bẹ́ẹ̀ni KÌÍ ṢE LỌ́TÌRÌ! “Ìkọ̀ọ̀kan” àwọn ọgọ́fà ni ó gbà á, tí a sì kún pẹ̀lu È̩mí Mímọ́. Pé wọ́n jẹ́ akọ tàbí abo, ọjọ́ orí tàbi ẹ̀yà àbí ipò wọn kò sì jámọ́ nnkan kan.
Ẹnìkan lọ́rùn níláti ti ka iye orí tó wà níbẹ̀, nítorí pe ahọ́n iná kan ló bà lé "ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn.” Tí o bá ní orí kan, Ọlọ́run ní iná kan fún ọ. Ní bàyí, o wà lára àwọn tí Ó ká. “È̩yin yóò sì gba agbára...” (Ìṣe Àwọn Àpọ́stélì1:8). Kàn wò ó báyìí pé orí rẹ di pápá fún È̩mí Mímọ́ láti bà sí. Yóò balẹ̀ yóò sì dúró - kò sì ní kúrò mọ́ láí.
Gbogbo ọgọ́fà àwọn ọmọ ẹ̀hìn tó wà nínú Yàrá Òkè lọ́jọ́ Pẹ́ńtíkọ̀stì ló gba ìrìbọmi È̩mí Mímọ́. Kò yọ ẹnikẹ́ni sílẹ̀. Kìí ṣe fún ọgọ́fà ọmọ ẹ̀hìn tí a mọ́ tàbí tí ó rìn tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jésù nìkan. Ọ̀pọ̀ tí a kó mọ orúkọ̀ wọn náà gba È̩mí Mímọ́. Wọ́n lè má jẹ́ olókìkí. ṣùgbọ́n wọ́n jẹ́ olódodo. Wọ́n lọ sí Yàrá Òkè wọ́n sì dúró de ìlérí náà. È̩mí Mímọ́ wá sí orí gbogbo wọn, ọwọ́ iná sì bà lé gbogbo wọn lórí - ọgọ́fà iná fún ogọ́fà àwọn olódodo.Tí o bá fara hàn, wàá ní iná agbára fún iṣẹ́ tí a yàn fún ọ.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Agbára àgbàyanu, tó ń jí òkú dìde ḿbẹ nínú rẹ. Ajíhìnrere Reinhard Bonnke ti ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ẹ̀kọ́ tó nípọn nípa Ẹ̀mí Mímọ́ fún ọ àti wípé ó kọ àwọn Kókó Àgbàyanu nípa Agbára Ẹ̀mí Mímọ́. Ẹ̀kọ́ Ọlọ́jọ́ Méje yìí ma mú ọ ronú nípa Ẹ̀mí Mímọ́ àti wípé ó máa ru ọ́ sókè láti ní ìgbàgbọ́ nínú agbára Ẹ̀mí náà tó ń gbé nínú rẹ.
More